Daniel Arap Moi: Ẹ wo àwòrán ìgbé àyé ààrẹ ilẹ̀ Kenya tẹ́lẹ̀rí tó papòpà

Aarẹ orilẹede Kenya tẹlẹri , Daniel arap Moi ti ku ní ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rún un.

Ọdun mẹrindinlogun lo fi jẹ aarẹ orilẹede Kenya. Awọn eniyan kọkọ ṣe atilẹyin fun ijọba rẹ ko to di wi pe wọn fi ẹsun jẹgudujẹra ati ifaṣẹyin to ba ọrọ aje.

Oríṣun àwòrán, Google

Àkọlé àwòrán,

Ni ọdun 1962 ni ilu London ni Daniel arap Moi ati Michael Blundell lọ ṣe ipade ni ilu London ati le sọrọ lori bi ilẹ Kenya yoo ṣe gba ominira lọwọ Ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Jomo Kenyatta lo fi jẹ igbakeji aarẹ ni ọdun 1967

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin iku Jomo Kenyatta ni ọdun 1978 ni wọn fi jẹ aarẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Moi ṣe ipade pẹlu olootu ilẹ India, Indira Gandhi ni Kenya ni Osu Kẹwa,ọdun 1981.

Oríṣun àwòrán, PA Media

Àkọlé àwòrán,

Ọbabinrin Elizabeth II nibi ti aarẹ Moi ti gbalejo rẹ ni Kenya, ni ọdun 1983.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Iwọ erin ti iye owo rẹ le ni miliọnu mẹta owo ilẹ okeere 3m (£2.3m) ni aarẹ Moi sọ ina si lati polongo igbogunti bi wọn ṣe n pa erin ni 1989.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ọdun 1991 ni o sọ fun ẹgbẹ oṣelu African National Union (Kanu) ti tan ni Kenya. Ọdun to tẹle lo jẹ aarẹ orilẹede naa pẹlu ẹsun ọpọlọpọ magomago.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ibi ayẹyẹ ni olu ilu Kenya, Nairobi ni ọdun 1992.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Moi ki awọn latilẹyin rẹ lẹyin to pari saa rẹ ni ọdun 1998.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Daniel arap Moi ati aarẹ ilẹ Amẹrika tẹlẹri, Bill Clinton nibi ipade ijiroro pẹlu ilẹ Amẹrika ni Washington Convention Centre ni Washington, DC ,lọdun 2000.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Daniel arap Moi jọkọ ṣe ikeji si aarẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Mwai Kibaki nibi iburawọle ni Osu Kejila, ọdun 2002, lẹyin opin si saa rẹ ọlọdun mẹrinlelogun.

Gbogbo awọn ti a kọ pe wọn ni aworan naa lo ni i.