Àdó olóró tí wọ́n fi ń pa iná àdó olóró míì ló gbiná l'Ekiti - Ọlọ́pàá Ekiti

Ibi ti ibugbamu ti ṣẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Olasunkanmi Ogunmokun

Ado oloro ti wọn fi n pa ina ado oloro ti bu gbamu ni olu ilu ipinlẹ Ekiti, Ado Ekiti ni owurọ yii.

Kọmiṣana Ọlọpaa ipinlẹ naa, Ọgbẹni Asuquo Amba sọ fun BBC Yoruba pe lootọ ni ibugbamu kan waye ṣugbọn awọn ko le sọ pato ohun ti o jẹ.

Ṣugbọn Ikechukwu sọ wi pe awọn ni awọn ado oloro kan ti wọn fi n pa ina ibugbamu ado oloro ninu ile ti wọn n ko nkan pamọ si.

Oríṣun àwòrán, Olasunkanmi Ogunmuko

Iṣẹlẹ naa waye ni adugbo kan to wa ni agbegbe ile ijọba atij ti ipinlẹ Ekiti ni olu ilu ipinlẹ naa, Ado Ekiti.

Ṣe ni wọn gbọ gbamu lowurọ oni ṣugbọn ko si ẹni kankan to fara pa tabi ba iṣẹlẹ naa rin bi o til jẹ wi pe o pa ile ti wọn n ko nkan pamọ si lara.

Ọgbẹni Ikechukwu ni ikọ awọn ti n ṣiṣẹ pọ lọwọ lọwọ pẹlu kọmisana lati mọ ohun to ṣẹlẹ gangan ati lati mu u rọlẹ.

Kọmiṣana Ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ni orukọ ti awọn pe nkan ibugbamu yii ni ede to lee ye ara ilu ni awọn pe e yẹn ṣugbọn awọn akọṣẹmọṣẹ ti n ṣe iṣẹ wọn tori naa ki awọn ara ilu ma bẹru.

A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa wa fun un yin bo ba ṣe n lọ.

Àkọlé fídíò,

'Àṣà wa l'Ekiti ló dára jú lórílẹ̀èdè Nàìjíríà'