Femi Adesina: Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà bá f'ara balẹ̀ wọ́n ó rí iṣẹ́ ribiribi tí Buhari ti ṣè

Aarẹ Buhari nipinlẹ Plateau

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Olubadamọran pataki si aarẹ Buhari lori ọrọ ibanisọrọ ati ipolongo, Femi Adesina ti ni ki awọn ọmọ Naijiria farabalẹ lati le ri iṣẹ daada ti aarẹ Buhari ti gbe ṣe.

Ninu apilẹkọ kan to fi si oju opo rẹ, Adesina ni ọpọ iṣẹ ni aarẹ ti ṣe ṣugbọn aifarabalẹ awọn eeyan Naijiria kan ko jẹ ki wọn mọ pe o ti ṣiṣẹ.

Lẹnu ọjọ mẹta yi, Adesina ti n tako ọrọ si awọn to n bẹnu atẹ lu iṣejọba aarẹ Buhari to fi mọ awọn to ṣe iwọde RevolutionNow to ṣe apejuwe wọn gẹgẹ bi awọn ọmọdekunrin ati obinrin ati pe eremọde lasan lasan ni iwọde wọn jẹ.

Adesina tunbọ mu akawe ọrọ ọmọde kan ti fọnran fidio rẹ gbode kan nibi to ti n sọ fun iya rẹ to fẹ na wi pe ko ''calm down''

O ni gẹgẹ bi ọmọ naa ti ṣe sọ, awọn ọmọ Naijiria ni lati farabalẹ.

Àkọlé fídíò,

Mummy calm down: Ìyá Ore sọ pé gbogbo ìgbà tí óun bá n bá a wí ló ma n ṣe àwàdà

Aworan Femi Adesina

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi-Adesina

''Igbonara wa ti pọju, ikunsinu pọ fun wa, a fẹran ka maa sọ ijọba lorukọ buruku, awọn to ba n gbiyanju ati tun ilu ṣe orukọ ti ko da laa n sọ wọn''

Bi ẹ ba gbọ bi awọn eeyan kan ti ṣe n sọrọ, awọn ọdọ tara wọn n gbona, awọn olori ẹlẹsin,awọn onwoye agbo oṣelu to fi mọ awọn ti wọn pe ara wọn lajafẹtọmọniyan, wan kii ri nkan daada kan ninu ijọba yi''

Adesina wa ṣe akawe awọn iṣẹ ti ijọba ti sẹ to fi mọ ipese awọn ohun amayederun fara ilu lẹka orisirisi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lakotan ọrọ rẹ, o ni ti awọn eeyan ba farablẹ, wọn yoo ri awọn nkan to ra mọ alaafia orileede Naijiria ati pe abnfaani to kẹyin re lati mu atunṣe ba Naijiria.

Ki lawọn ọmọ Naijiria sọ

Awọn ọmọ Naijiria ko jẹ ki ọrọ Adesina balẹ ki wọn to bẹrẹ si ni fun lesi pada loju opo Twitter.

Bi awọn kan ti ṣe ni lootọ lawọn ri awọn nkan to ka silẹ gẹgẹ bi aṣeyọri ijọba lawan mii ni awọn ko ri ohun to n pe ni aṣeyọri

Àkọlé fídíò,

Ìdílé tí ọkọ da ọmọ síta tóríi ojú Búlùú tí wọ́n ní bá BBC sọ̀rọ̀

Ìgbìmọ̀ ọ̀tẹ̀ ní ọ̀rọ̀ àwọn àgbààgbà ẹkùn àríwá pé ìjọba Buhari ti kùnà- Femi Adesina

Oludamọran pataki fun aarẹ Muhammadu Buhari, Femi Adesina ti bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti àjọ ìgbìmọ̀ àwọn àgbààgbà ẹkùn àríwá Naijiria, NEF sọ lori iṣejọba Naijiria labẹ iṣakoso aarẹ Buhari.

Àjọ ìgbìmọ̀ àwọn àgbààgbà ẹkùn àríwá Naijiria, NEF fi àtẹ̀jáde síta pé ààrẹ Buhari tí kùnà nínú ìṣèjọba Naijiria.

Ninu ọrọ ti wọn sọ fun awọn oniroyin ni ajọ naa ti sọrọ lori bi orilẹede Naijiria ṣe ri lọwọlọwọ, ati ọna abayọ si ohun to dẹnukọlẹ ni Naijiria.

Ajọ naa ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun awọn pẹlu bi aarẹ Buhari ko ṣe naani awọn araalu lori eto aabo.

Bakan naa ni wọn si pe fun ki aarẹ Buahari kọwe lo gbelerẹ fun awọn olori eto aabo ni orilẹede Naijiria.

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ninu idahun rẹ, Femi Adesina ninu atẹjade sọ wi pe isọkusọ gba ni ọrọ ti awọn igbimọ ti Ango Abdullahi ṣe adari fun un sọ.

O ni ẹtanu ati ibanilorukọjẹ ni ajọ naa n ba kaakiri, ti ko si si otitọ kankan ninu gbogbo ẹsun ti wọn fi kan Aarẹ Muhammadu Buhari lori iṣejọba rẹ.

Oludamọran pataki fun aarẹ Muhammadu Buhari naa wa fikun pe ijọba aarẹ Buhari n lọ ni irọwọrọsẹ, ati wi pe oun sa ipa rẹ lati mu gbogbo ohun to ti bajẹ pada si ipo ni saa yii.