Ogun Police: Bàbá fìdí ọmọ ọdún márùn ún jó sítóòfù gbígbònà, ó di aláàbọ̀ara torí ó jí ẹja

omode

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán,

Ajàfẹ́tọ̀ ọmọdé, Oluwatoyin Ojo ti ni obi to ba ti fun ọmọ lẹgba ju meji lọ ni ọwọ ti ṣẹ si ofin Naijiria.

Ọpọlọpọ awọn obi ni ilẹ adulawọ ni ko loye nipa iru nkan ti eniyan le ṣe lati ba ọmọ wi lai fi iya jẹ ọmọde naa.

Eyi ko ṣẹyin Baba kan ni ipinlẹ Ogun to fi idi ọmọ rẹ jona lọna ati ba ọmọ naa wi nitori pe o ji ẹja.

Alagbawi ati ajafẹtọ fun awọn ọmọde, Oluwatoyin Ojo ti bu ẹnu atẹ lu iwa aitọ ti baba naa hu si ọmọ rẹ.

Ojo ni ohun to ṣe ni laanu ni pe ọpọlọpọ ninu awọn obi naa ko mọ wi pe ohun ti wọn ṣe ko dara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Bàbá ọmọ náà ní ó jí ẹja ní òun ṣe fi ọmọ naa jókòó ní orí sítóòfù ẹ̀lẹ́tíríkì, tí ìdí àti apá ọmọ náà sì bó fálafàlá.

Arabinrin naa wi pe ti obi ba ti na ọmọ ti ara rẹ si bẹ ẹjẹ lọna ati ba a wi, o ti da ẹṣẹ ifiyajẹni to lodi si ofin.

Wo awọn ọna ti obi fi n ṣe si ofin nipa ifiyajẹ ọmọde

 • Ti obi ba fi ami si ara ọmọde lọna ati ba a wi, o ti ṣẹ si ofin ati ọmọ naa
 • Ti o ba fi ẹgba na ọmọ ju ẹẹmeji lọ ni ọwọ rẹ, o ti da ifiyajẹni
 • Obi to ba fi ara ọmọ rẹ jona lọna ati ba a wi, ti ṣẹ si ofin to lodi si ifiyajẹni
 • Ẹni to ba lo abẹ lati kọla si ara ọmọ lọna ati ba a wi, ti fi iya jẹ ọmọ naa
 • Obi ti o ba n sọrọ kobakungbe si ọmọ rẹ nipa ṣiṣẹ epe fun un, ti o le mu ibanujẹ ọkan abi iporuru kan ba ọmọ naa ti fi iya jẹ ẹ
 • Ibalopọ pẹlu ọmọde ti ko i tii pe ọmọ ọdun mejidinlogun ja si ifiyajẹni ati ifipabanilopọ, eleyii ti ofin Naijiria ati ti agbaye koro oju si
 • O lodi si ofin ki ọmọde ma a kiri laarin igboro, nigba ti o yẹ ki o wa ni ile ẹkọ rẹ bi awọn ọmọde bii ti rẹ
 • Fifi ọmọde fun ọkọ lai tii pe ọmọ ọdun mejidinlogun ja si ifiyajẹni labẹ ofin
 • Bakan naa ni o lodi si ofin lati fi ọmọde ṣ'ẹru, tabi fi san gbese bi awọn kan ṣe n se ni awọn agbegbe kọọkan ni orilẹede Naijiria
 • O lodi si ofin naa lati da ọmọbinrin labẹ nitori ko si anfaani kankan ti o n ṣe fun obinrin ti o ba ti dagba, o ma n fa kikorira ibalopọ ati aisan oju ara si wọn ni ara
 • Obi ti o ba kọ ọmọ rẹ silẹ ṣẹ si ofin nitori wi pe awọn ọmọ to yẹ ki obi ṣi maa tọju a wa di alarinkiri ni igboro

Ijiya wo lo wa fun obi to ba fi iya jẹ ọmọ rẹ?

Labẹ ofin Naijiria, Ajafẹtọ ọmọde, Oluwatoyin Ojo sọ wi pe o ṣeeṣẹ ki obi ri ẹwọn ọdun meji si meje he ti wọn ba fi ija jẹ ọmọ wọn.

Ijọba naa si ni aṣẹ lati gba ọmọ lọwọ obi rẹ, ti wọn ba fi iya jẹ ẹ ni ọna aitọ.

Ajafẹtọ ọmọde naa wa rọ ijọba lati ri i wi pe wọn la awọn obi loyẹ nigba ijiya to wa ninu ifiyajẹ ọmọ wọn, ati wi pe ki wọn pese nọmba ti kọ gunju ti awọn ọmọ naa le pe, ti wọn ba n la ifiyajẹni kọja.

O fi kun un wi pe ki ijọba tun pese ile igbe fun awọn ọmọde ti ko ri ile gbe abi ti awọn obi ti kọ silẹ, ki iru ifiyajẹ ọmọde le dinku ni awujọ.

Bẹẹ ni o rọ awọn obi lati ri i wi pe wọn toju wọn, ki wọn si mọ wi pe awọn ọmọ yii ni aṣẹ labẹ ofin lati ri i wi pe awọn obi wọn ko fi iya jẹ wọn.

Bàbá fìdí ọmọ ọdún márùn ún jó sítóòfù gbígbònà, ó di aláàbọ̀ara nítorí ó jí ẹja

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ogun ti fi panpẹ ọba mu arakunrin kan, Idowu Sikiru fun ẹsun pe o fi iya jẹ ọmọ rẹ, ọdun marun un, Segun Sikiru.

Ẹni ti wọn fi ẹsun kan naa, to n gbe agbegbe Itowo ni Oke Sopen ni Ijebu Igbo, ni o fi idi ọmọ rẹ jọ sitoofu ẹlẹtiriki nitori o ji ẹja jẹ.

Awọn ọlọpaa ri ọkunrin naa mu lẹyin ti awọn ara adugbo ta wọn lolobo pe ọkunrin kan ti fẹ pa ọmọ rẹ kekere.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbola Oyeyẹmi sọ wi pe bi awọn ṣẹ gbọ iroyin naa ni awọn ṣe kiakia lọ si bẹ, ti wọn si fi panpẹ ọlọpaa mu ọkunrin ọhun.

Oyeyemi ni Baba ọmọ yii fi tipatipa fi idi ọmọ rẹ jo ina ẹlẹtiriki lẹyin ti o ni ọmọ naa mu ẹja ti wọn ti se, eleyii ti o jẹ ki idi ọmọ naa o bo falafala.

Bakan naa ni baba ọmọ yii fi ina jo ọwọ pẹlu ẹnu ọmọ naa, ti awọn ọlọpaa si ti gbe ọmọ ọhun lọ si ile iwosan fun itọju to peye.

Oyeyemi fi kun un pe kọmisọnna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ ki wọn gbe baba ọmọ naa lọ si ẹka to n risi ifinisowo ẹru ati ilokulo ọmọde fun iwadii to peye ati ijiya to tọ si iru iwa bẹẹ.