Period-shaming: Iléèwé pàṣẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tú síhòhò torí ǹkan oṣù

Fifi awọn obinrin ṣe ẹlẹya nitori nkan oṣu ni India Image copyright AFP

Awọn ọmọ Ile iwe girama kan ni Gurajat ti n fẹsun kan pe ileewe wọn mu awọn ni dandan lati bọ ara si ihoho ki wọn si fi awọtẹlẹ wọn han awọn olukọ obinrin lati fi aridaju han pe awọn o ṣe nkan oṣu.

Lọjọ ọjọ kan ni wọn ko awọn akẹkọbinrin mejidinlaadọrin sita ninu kilaasi, ti wọn si ko wọn lọ si ile igbọnsẹ pe ki wọn maa bọ ṣokoto penpe wọn ni kọọkan.

Iṣẹlẹ yii waye ni ilu Bhuj, ipinlẹ Gurajat lorilẹede India lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kọja.

Awọn akẹkọ naa n kẹkọọ ni ile ẹkọ Shree Sahajanand Girls (SSGI) ti ẹgbẹ awọn ẹlẹsin Hindu kan n ṣe adari fun.

Iroyin sọ pe alamojuto ileegbe awọn akẹkọọ mu ọrọ naa lọ oludari ileewe wọn ni ọjọ Aje pe awọn akẹkọọ kan n ru ofin to yẹ kawọn obinrin to n ṣe nkan oṣu maa tẹle.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIntersextuality: Dokita ni ká mu èyì tó wù wá nínú jíjẹ́ akọ tàbí abo

Ninu ofin ti wọn ṣe yii, awọn obinrin ko gbọdọ wọ inu ibi ijọsin ati ile idana, bẹẹ si ni wọn ko faaye gba wọn lati fọwọ kan awọn akẹkọọ miran lasiko ti wọn ba n ṣe nkan oṣu.

Koda bi wọn ba n jẹun, wọn gbudọ ta kete ki wọn da joko jina si awọn to ku. Wọn gbudọ fọ abọ tiwọn lọtọ, bẹẹ si ni bi wọn ba wa ni kilaasi, ori aga to wa lẹyin ni wọn yoo joko si.

Image copyright BBC GUJARATI

Ọkan lara awọn akẹkọọ naa sọ fun akọroyin BBC ti ilu Gujarati, Prashant Gupta pe ileegbe awọn akẹkọọ ni iwe akọsilẹ kan ti wọn gbudọ maa kọ orukọ wọn si bi wọn ba ti ri nkan oṣu wọn eyi si lo maa n ran awọn alaṣẹ ileewe lọwọ lati da wọn mọ.

Ṣugbọn fun odidi oṣu meji bayii, ko tii si akẹkọọ kankan to fi orukọ rẹ silẹ sinu iwe naa.

Nitori naa lọjọ Aje alamojuto wọn lọ sọ fun ọga agba ileewe pe awọn to n ṣe nkan oṣu n wọ ile idana, wọn n sunmọ ile ijọsin wọn si n ba awọn akẹkọọ wọn to ku ṣere pọ.

Awọn akẹkọ wa fẹsun kan pe lọjọ keji, alamojuto ileegbe awọn fiya jẹ awọn ki wọn to tun wa mu awọn ni dandan pe ki wọn bọra sihoho.

Wọn ṣapejuwe ohun to ṣẹlẹ si wọn gẹgẹ bi iriri to dun wọn gan to si ti da apa si ọkan awọn eyi to ja mọ ifiyajẹni ninu ọpọlọ.

Baba akẹkọọ kan tilẹ sọ pe igba ti awọn de ile iwosan, ọmọ ohun atawọn akẹkọọ miiran wa ba oun ti wọn si bẹrẹ si ni sọkun.

Nigba to di Ọjọbọ ọsẹ, awọn akẹkọọ kan korajọ, wọn si ṣe iwọde ninu ọgba ileewe lati ja fun ki wọn gbe igbesẹ lori alamojuto to fi awọn ṣe ẹlẹya yii.

Ẹwẹ, agbẹnusọ fun ileewe naa, Pravin Pindoria ni iṣẹlẹ naa ṣe ni laanu jọjọ to si ni awọn ti bẹrẹ iwadii. Ati pe awọn yoo si gbe igbesẹ lori ẹnikẹni ti panpẹ ofin ba mu.

Ṣugbọn ni ti adari agba Fasiti ti ile iwe girama naa so pọ mọ, Darshana da ẹbi le awọn akẹkọọ lori.

Arabinrin naa ni wọn ti ru ofin o si fi kun un pe awọn kan lara wọn ti tọrọ aforiji.

Image copyright AFP

Ẹwẹ, lara awọn akẹkọọ sọ fun BBC pe ileewe ti n finna mọ awọn lati juwọ ariwo ọrọ yii silẹ ki wọn si ma sọ ohun ti wọn la kọja.

Kii ṣe igba akọkọ niyi ti wọn yoo yẹyẹ awọn akẹkọbinrin nitori asiko nkan oṣu.

Aadọrin akẹkọọ ni wọn bọ si ihoho ni ọdun mẹta sẹyin nileewe kan ni ẹkun ariwa India nigba ti oluṣọ ileegbe kan ri ẹjẹ lara ilẹkun ile iwẹ.

Ṣiṣe ẹlẹyamẹya si awọn obinrin nitori nkan oṣu wọpọ lorilẹede India nibi ti ṣiṣe nkan oṣu ti jẹ nkan eewọ tipẹ, ti wọn si maa n ri awọn obinrin to n ṣe nkan oṣu gẹgẹ bi ẹni ti ko mọ.

Wọn saba maa n ya wọn sọtọ lagbo, ninu eto ẹsin ti wọn ko ni jẹ ki wọn wọ inu ile ijọsin tabi ojubọ bẹẹ si ni wọn o ki n wọ ile idana.