#JusticeFor Chima: Àgbáríjọ àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́ pè fún ìdádujro Kọmisọna ọlọpàá

Muhammed Adamu
Àkọlé àwòrán,

Iku Mọkaliki: Agbarijọ awọn aja fẹtọ pe fún ìdádujro Kọmisọna ọlọpàá

Agbárijọ ẹgbẹ́ awọn ajafẹtọ ọmọniyan ti ke si ọgà àgbà ajọ ọlọpàá, Muhammed Adamu láti dá kọmisọna ọlọpàá nipinlẹ Rivers, Mustapha Dandaura nítori ikú mọkaliiki, Ikwunado Chima to kú si atimọle ọlọpàá lẹ́yin ti wọ́n mu òun ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́rin.

Ẹgbẹ́ ọhún tún rọ ilé iṣẹ́ ọlọpàá lati le ọgá náà lẹ́nu iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bii àra àwọn Eagle Crack to jẹ́ awọn to fi iya jẹ Chima titi di ojú ikú àti àwọn ọ̀rẹ rẹ Ifeanyi Onyekwere, Victor Ogbonna, Osaze Friday àti Ifeanyi Osuji.

Iroyin sọ pe wọ́n mu Chima àti awọn ọ̀rẹ rẹ mẹ́rin ni inú oṣu kejila, ọdun 2019 lẹ́yyin ti wọ́n fẹ̀sun kan wọ́n pe adigunjale ni wọ́n àti pe wọ́n n ṣe ẹgbẹ òkùnkun.

Chima si ku lasiko ti awon ẹka Eagle Crack fi iya jẹ.

Awọn agbarijọ aja fẹtọ náà tun ní ki wọ́n pa ẹka Eagle Squad naa rẹ patpata.

Asoju ẹgbẹ́ náà to ba akoroyin sọ̀rọ̀ ni Port Harcourt, Ogbeni Enafaa Georgewill ni ki ile iṣẹ́ ọlọpaa san owo ilé iwosan awọn to kù.