Sex for Grade: Ọwọ́ àwọn aṣòfin yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní tẹ àwọn olùkọ́ fásitì olójúkòmúòlọ

Obinrin Image copyright Gettty

Ile igbimọ aṣofin orilede Naijiria yoo ṣe ipade lori abadofin kan ti wọn gbero lati fi ṣe ofin ti yoo lodi si ilọkulọ ibalopọ lawọn ile iwe giga fasiti Naijiria.

Abadofin naa yananana ẹwọn ọdun marun gbako fun olukọ ti wọ ofin ba tẹ pe o n fi ilọkulọ ibalopọ lọ akẹkọbinrin tabi ọkunrin.

Wọn ṣe agbekalẹ abadofin yii lẹyin ti ẹka ileeṣ BBC to n tu aṣiri awọn ohun ti ko dara lawujọ, BBC Africa Eye lori fifi ilọkulọ ibalopọ lọ akẹkọọ ki wọn ba le fun wọn ni maaki eyi to maa n wa latọdọ awọn olukọ fasiti.

Eyi ni igbesẹ ti ile igbimọ aṣofin agba gbe bayii gẹgẹ bi ọna ati mu awọn to ba ru ofin to ni ṣe pẹlu ibalopọ lawọn fasiti orilẹede Naijiria.

Yatọ fun fifi ẹwọn jura, abadofin naa tun sọrọọ lile tabi aṣẹ lọ rọọkun nile fun awọn akẹkọọ to ba ti ile ẹjọ ba ri i pe irọ ni ẹsun ti wọn n fi lọ pe olukọ fẹ fipa ba awọn lo pọ.

Ẹwẹ, ile igbimọ aṣofin agba ti fi abadofin naa ṣọwọ si igbimọ to tun duro ire lori ọrọ idajọ, ẹtọ ọmọniyan ati ọrọ ofin.

Bi abadofin naa ba di gbigba wọle nile igbimọ aṣofin agba ti wọn si fi ṣọwọ si ile igbimọ aṣojuṣofin, ti awọn mejeji ati aarẹ si fọwọ si i ko fi di ofin.

Oṣu kẹwa ọdun to kọja ni akanṣe iroyin BBC kan jade to tu aṣiri awọn aṣemaṣe ibalopọ to n wa latọwọ awọn olukọ fasiti ni ile iwe giga fasiti meji pataki kan nilẹ Afirika.

Aṣiri to tu yii ti mu ki awọn alaṣẹ fasiti mejeji ni ki awọn olukọ naa lọ rọọkun nile.