EFCC: Ibrahim Magu ní ìwá ìbàjẹ́ ló fa Coronavirus

Ibrahim Magu, alaga EFCC

Oríṣun àwòrán, Efcc/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Àrùn Coronavirus bẹ́ sílẹ̀ lórílẹ̀èdè China níbi tí ó ti pa ènìyàn tó lé ní 2,000 ní ilẹ̀ náà.

Adele alaga fun ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, Ibrahim Magu ti ni oun gbagbọ pe iwa jẹgudujẹra lo fa arun Coronavirus to n ja rain lorilẹede China.

Arun coronavirus naa to bẹrẹ ni Osu Kejila, ọdun 2019 ni orilẹede China ti pa eniyan to le ni ẹgbẹrun meji, ti o si ti ran ẹgbẹgbẹrun eniyan lorilẹede China ati awọn orilẹede mẹẹdọgbọn miran kaakiri agbaye. lọ sọrun.

Amọ arun coronavirus to n ja rain naa ko i tii de orilẹede Naijiria, nitori naa ni awọn eniyan ṣe n woye lori ọrọ ti Magu sọ.

Ibrahim Magu sọ wi pe iwa jẹgudujẹra lo fa Coronavirus lasiko ti awọn ọmọogun ajọ EFCC n ṣe ayẹyẹ ikẹkọjade ni ileewe ọmọogun Naijiria to wa ni ipinlẹ Kaduna.

Magu n sọrọ nipa ijamba ati ewu ti o wa ninu iwa jẹgudujẹra, lo fi sọ wi pe ohun naa lo fa ajakalẹ arun ọhun.

Ọga Agba ajọ EFCC naa fi kun un wi pe awọn ko ni gba iwa ibajẹ laaye nigba kankan nitori awọn yoo tẹsiwaju lati maa gbogun ti iwa ibajẹ.

Ibrahim Magu ni lati ọdun 2015 ni awọn ti bẹrẹ igbogunti naa ni ọkunkundun, ti awọn si ti fi panpẹ ọba mu eniyan mẹtalelọgọrun ni 2015, marundin-nigba ni ọdun 2016 ati ọọrundunrun le mẹrinla ni ọdun 2018, nigba ti awọn si mu eniyan to le ni ẹgbẹrun lọdun 2019 nikan.