Coronavirus: Ǹjẹ́ adìyẹ Broiler ni ǹkan tó ń tan àìsàn COVID-19 kálẹ̀?

Adiye Broiler

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìròyìn tó n tàn kan lórí ayélujara ní pe ara adiye Broiler ni àwọn ènìyàn ti n ko àìsàn Coronavirus (COVID19) kalẹ̀, ni NCDC ti sàlàye pé ìròyìn ẹléjé ni .

NCDC ni àìsàn náà ko niṣe pẹlú adiyẹ broiler ti àwọn onímọ sayẹnsi si ti ṣiṣẹ́ takuntakun láti mọ ẹrànko to n pín àìsàn náà to ti pa ènìyàn ẹgbẹ̀sàn to si ti ran ẹgbẹ̀run lọ́na ààdọrin ni àgbàyé.

O jẹ́ ǹkan to ya ni lẹ́nu lati maa gbọ ìròyìn òfége pe adiyẹ broiler lo n fa COVID19, oṣiṣẹ kan ni NCDC, Chukwuemka Oguanuo lo sọ fún BBC.

"Se ẹ mọ pe oniruuru àhesọ lo ti wáye lati igba ti ọ̀rọ̀ coronavirus ti de, awọn kan ni inú ẹrànkò kan ti wan n pe ni Pangolin, sùgbọ́n ọ̀rọ̀ ti oni broiler yii tu ya mi lẹ́nu."

" Lasiko yìí, ǹkan ti a mọ ni pe ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn to ni ààrun náà ni la'ti ara ènìyàn si eniyan"

Nkan ti a mọ nipa Coronavirus

Aisan, ti wọ́n n pe ni 2019-nCov, ni iru àisan coronavirus to tun n wa lode nisinyi jẹ èyi ti ko si lára ènìyàn tẹ́lẹ̀

Coronavirus jẹ aisan aifojuri mẹfa iru rẹ̀ lo si wà, sùgbọ́n eleyii ni ẹlẹkeje iru rẹ̀, ohun si ni àwọn onimọ sọ pe o n tà ka

Ajọ WHO ti gba àwọn ènìyàn niyanju láti ma ni ibaṣepọ pẹlu ẹranko abẹmi, ki wọ́n si se ẹran ati éyin wọ́n daradara.

O san láti ma ni ǹkan ṣe pẹlu ẹnikẹni to ba ni ọ̀fìnkìn tàbi to ni ikọ́, eyi ni ọ̀na láti daabo bo ara ẹni lọ́wọ́ COVID19

Ati àwọn onimọ sayensi ni Naijiria ati gbogbo àgbáye ni wan ti jọ n gbimọ pọ lati mọ idi aisan náà ati lati wa ọ̀na abayọ

Oríṣun àwòrán, Kevin Frayer

Àkọlé àwòrán,

Awon alase ni aisan na le ran lati ara eniyan si eniyan miran

Kini awon apẹrẹ aisan Coronavirus

Awọn apẹrẹ gbòògi ni:

  • Imi to nira tabi ki èèmi ma ja geere
  • Iba
  • Ikọ ati Kata
  • Awon ẹya ara le da iṣẹ silẹ
  • Otutu aya
  • Ati iku