Ààrẹ Buhari: Èrò burúkú ni pé owó osù Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Naijiria pọ̀jù

Ile igbimo Asofin Naijiria lọdun 2018

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede Naijiria ti sọ wi pe, ohun ti ko dara ni ki awọn ọmọ Naijiria ma a ro o ni ọkan wọn pe, awọn aṣofin Naijiria n gbowo ju bi o ti yẹ lọ.

Buhari ni aini igbagbọ ninu awọn aṣofin naa, ni ko jẹ kawọn ọmọ Naijiria ri iṣẹ ribiribi ti wọn n ṣe.

Lai Mohammed, to n ṣoju aarẹ Buhari lo sọ ọrọ yii ni ibi ifilọlẹ iwe iroyin nile igbimọ Asofin, eleyii ti wọn pe ni The Green Chamber Magazine.

O ni wi pe ko si otitọ kankan ninu ọrọ ti awọn eniyan n sọ wi pe, wọn n pin owo ni ile igbimọ aṣofin lai ṣe iṣẹ to yẹ.

Aarẹ Buhari ni aimọ iru iṣẹ kabiti ti wọn n ṣe lo fa aibikita fun awọn asofin naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Buhari ni iwe iroyin ti wọn ti wọn fẹ ṣe ifilọlẹ rẹ naa, yoo jẹ ki gbogbo aye mọ iru iṣẹ ribiribi ti wọn n ṣe.

Ati wi pe, awọn aṣofin naa yoo le sọ iroyin ara wọn lai si magomago lati ọdọ awọn akoroyin, bi o ba ṣe ri, ni wọn a ṣe gbe e si ta.

Amọ, alejo pataki nibi ifilọlẹ naa lati orilẹede Kenya, Ọjọgbọn Plo Lumumba beere lọwọ awọn aṣofin naa pe, ṣe wọn n jẹ aṣoju rere fun awọn ọmọ Naijiria abi ti ara wọn ni wọn n ṣe ni ile igbimọ Asofin Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Naijiria ní ó gbàgbọ́ pé àwọn aṣòfin Naijiria ń gba owó gọbọi ju iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe lọ.

Ọjọgbọn Plo Lumumba wa rọ wọn ki wọn wo awokọṣe awọn baba nla Naijiria, ti wọn ja fun ominira Naijiria, ki awọn naa sa ipa wọn lati mu idagbasoke ati ilọsiwaju ba orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Female Driver: Sokunbi ni obìnrin àwakọ̀ Dáńfó l‘Eko, tó ń lọ̀ láti ìpínlẹ̀ kan sí òmíì

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Naijiria ní ó gbàgbọ́ pé àwọn aṣòfin Naijiria ń gba owó gọbọi ju iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe lọ.