Okada ban: Láìpẹ́, ìjọba ìpínlẹ̀ Eko yóò fi ǹkan tó dára míì rọ́pò Kẹ̀kẹ́ àti ọ̀kadà

Moto

Oríṣun àwòrán, Twitter

Àkọlé àwòrán,

Laipe, ijoba ipinlẹ Eko yóò fi ǹkan to dara míí ropò Kẹkẹ àti ọkada

Laipẹ yìí ni òkìkí kan lori ayélujara twitter pe ìjọba ti n pínu lati ko àwọn mọto korope jade lati fi rọ́pò kẹ́kẹ́ maruwa àti awọn ọkada ti ìjọba kásẹ̀ rẹ̀ kúrò nilẹ̀ nibẹ̀rẹ̀ oṣu yìí.

Níní ọ̀rọ̀ ti Kọmisọna fun ọ̀rọ̀ tó n lọ ní ípinlẹ Eko Gbenga Omotosho lásìkò to n ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ lo ti sàlàye pé, kìí ṣe ìjọba ìpínlẹ̀ Eko lo ko kẹ́kẹ́ máruwa si ìpínlẹ̀ Eko tẹ́lẹ̀ nítori náà kìí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko lo ko kẹ́kẹ́ kúrò nilẹ̀

Lóri àwọn fóto mọtọ to gba ori twitter kan, Komisọna ni ìjọba ko ti pínu láti ko mọtọ kankan jáde, sùgbọ́n o lè jẹ́ àwọn onísòwò to kan fẹ́ tajà lo ń ṣe irú ǹkan bẹẹ

Ọ̀gbẹ́ni Ọmọtọshọ ni bótilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ń seto lọ́wọ́ ti wọ́n si ń ba àwọn oniṣòwò ṣe ìpàde pọ̀ láti mọ ǹkan tó yẹ ti o si dara fún ara ilú.

Ọmọtoshọ ni kìí ṣe pe ìjọba fẹ fi ìyà jẹ ara ilú, sùgbọ́n ètò ààbo ilú jẹ́ ìjọba lógun ti wọ́n fi gbe ìgbésẹ náà, sùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn ara ilú kò mọ ǹkan ti ìjọba mọ ti wọ́n fi n ṣe ǹkan ti wọ́n ń ṣe.

Kọmisọna fun ọ̀rs to n lọ wá sàlàye pé ìjọba ti n ṣiṣẹ́ takuntakun lati ri dáju pé ǹkan ti o dara ju Kẹ́kẹ́ Maruwa ati ọkada lọ

O ní botilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló n dúnadura pẹlu ijọba láti ko mọto wọle.

O ni ìjọba ti gbiyanju láti ko àwọn ọkọ ńlanla sita lẹ́yin ti wan ko kẹkẹ kuro nilẹ, bẹẹ náà ni ọkọ oju omi ti pọ yanturu láti mu ki igbé aye rọrun fun àwọn eniyan