Death Sentence: Maryam Sanda pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lóri ìdàjọ́ ikú

Maryam
Àkọlé àwòrán,

Maryam Sanda pẹjọ kotẹmilọ́run lóri ìdàjọ́ ikú

Lẹ́yìn ti ilé ẹjọ gíga kan niílu Abuja ti da ẹjọ ikú fún Maryam Sanda lori nítori pe o pa ọkọ rẹ Bilyaminu Bello, Maryam Sanda ti pe ẹjọ kòtẹ́mílọrun nílú Abuja pe ki wọ́n da òhún láre.

Sanda ni adajọ Yusuf Halilu dájọ ikú fun ni ọjọ kẹtadinlógbọ̀n osù kini ọdun yìí ni súgbọ́n o gbabọ pe adájọ náà n sègbè nínú ìdájọ rẹ.

O ti fi iwé ranṣẹ si ile ẹjọ nipasẹ àwọn agbẹ́jọrò rẹ, Rickey Tarfa, Olusegun Jolaawo, Rigina Okotie-Eboh àti Beatrice Tarfa, pẹlu ariyanjiyan pe adajọ ṣe idájọ náà lọ́na aitọ.

Ninú iwé náà, o sàlàyé pé adajọ tasẹ agẹrẹ to si si ara rẹ lọ́na to si di iṣẹ́ ọlọpàá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọ́n.

Sanda rọ ilé ẹjọ láti jẹ ki ilé ẹjọ kòtẹmilọrun gba ẹjọ oun rò ki wọ́n si gbé idájọ ikú ti adajọ Halilu da sẹgbẹ́ kan ki wọ́n le tu oun silẹ ni alafia

Ko ti si ọjọ kankan ti wọ́n da fun igbẹ́jọ lori ẹjọ miran.