PDP: Bí ẹ bá dúnkókó lórí ìdájọ ta ti pegede,àwa náà yóò ṣé àyẹwò ìdájọ tó gbé Buhari wọlé

Aworan Buhatr ati Atiku

Oríṣun àwòrán, OfficialPDPNig

Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party,PDP ti ni awọn ṣetan lati ṣe ayẹwo idajo to gbe aarẹ Buhari wọlẹ gẹgẹ bi aarẹ Naijiria.

Ọrọ yi ko ṣẹyin bi ẹgbẹ alatako ni Naijiria ọhun ti ṣe ni ẹgbẹ APC n dunkoko mọ awọn adajọ ile ẹjọ to gajulọla lati gbe idajọ to tẹwọn lọrun jade ni gbogbo igba.

Akọwe ipolongo ẹgbẹ PDP Kola Ologbọndiyan lo fi ọrọ yi sita ninu atẹjade kan loju opo ẹgbẹ naa ni Twitter

Ologbọndiyan ni ifarajin awọn fun idagbasoke oṣelu awarawa ni Naijiria lo mu ki awọn fi tọkantọkan gba idajọ idibo aarẹ ati tawọn ipinlẹ bi Osun,Kano ,Katsina,ati Kaduna lai fa wahala.

O ni o jẹ iyalẹnu fawọn pe ẹgbẹ APC n sare lati lọ dunkoko mọ awọn adajọ ile ẹjọ giga lẹyin ti wọn gbe idajọ kalẹ lori idibo Bayelsa.

''Lẹyin ta joko jiroro, a ṣetan lati pe fun ayẹwo idajọ to gbe aarẹ Buhari wọlẹ toun ti pe ẹri wa pe o lo iwe ẹri ayederu.

'' O ni bẹẹ naa ni ọrọ kan idibo ipinlẹ Katsina ti ẹri aridaju wa pe wọn lo iwe ayederu''

Yatọ si idibo ti Aarẹ Buhari, PDP sọ pe awọn yoo kesi ile ẹjọ to gajulọ lati ṣe ayẹwo idajọ ipinlẹ Kano, Kaduna ati Katsina ti ẹri ti wa pe wọn ṣe jagidijagan lasiko idibo.

Ipinlẹ Osun naa ko gbẹyin ninu awọn ipinlẹ ti wọn na ika aleebu si idibo to gbe Gomina wọle.