Corona virus: Ibi àyẹ̀wò mẹ́ta ló wà fún Coronavirus ní Naijiria

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹgbẹrun eniyan lo ti papoda lẹyin aisan coronavirus bẹ silẹ lorilẹede China to si ti tan kalẹ de awọn orilẹede miran.

Igbakeji minisita fun ọrọ ilera lorilẹede Iran, Iraj Harirchi ti lugbadi aarun Coronavirus to ti pa eniyan mẹẹdọgbọn ni orilẹede naa.

Ninu fidio ti minisita naa fi lede loju opo Twitter rẹ lo ti sọ wi pe ayẹwo ti fihan pe oun ni aarun naa lara.

O ni oun ti fi ara oun si atimọle , ti iwosan si ti bẹrẹ fun oun lẹsẹkẹsẹ.

Saaju ki iroyin to gbe e pe oṣiṣẹ eleto ilẹra maa n fi sun omi lara pupọ pupọ lasiko to n ba awọn eniyan sọrọ ninu ẹrọ tẹlifisan ni ọjọ aje.

Ọjọ keji lo gbe jade wi pe oun ti ni aisan naa, to si ni ki awọn eniyan fi ọkan balẹ.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Igbakeji Minisita naa ni oun gbagbọ pe oun yoo bori aarun naa, ti ago ara oun yoo si pada si po.

O fikun pe ara oun dun oun, amọ orilẹede naa yoo bori aarun naa gbogbo.

Ibi àyẹ̀wò mẹ́ta ló wà fún Coronavirus ní Naijiria

Ijọba orilẹede Naijiria ti sọ wi po ile iwosan to n ṣe ayẹwo coronavirus mẹta lo wa ni lorilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò,

Corona virus:Agbeegbe Wuhan ni China da bi ilu awọn oku

Arun coronavirus to bẹrẹ ni ilu Wuhan, lorilẹede China ti pa ọpọlọpọ eniyan ni ilu naa, ti o si ti tyan kale ka oko.

Awọn ile iwosan ti wọn ti n ṣe ayẹwo naa wa ni Ile iwosan ni Abuja, ile ẹkọ iwosan ni Edo ati ile ẹkọ iwosan ni ilu Eko.

Bakan naa ni eto ilera lagbaye, WHO ti kesi awọn ijọba kaakiri agbaye lati gbaradi fun pajawiri arun naa kaakiri agbaye.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Wọn ni o seese ki aisan naa tan kalẹ lati ara enikan si ẹlomiran lai si idiwọ kankan lati agbeegbe kan si omiran.