Presidency 2023: Gbogbo ǹkan tí ènìyàn nílò láti dári ni Tinubu ní-APC

Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Gbogbo ǹkan ti ènìyàn nílò láti dári ni Tinubu ní-APC

Àwọn ọmọ égbẹ́ òṣèlú APC ni ipinlẹ̀ Eko ti kede , pe bi Bola Ahmed Tinubu to jẹ Asiwaju ẹgbẹ́ ni gbogbo ǹkan to yẹ láti di ààrẹ Naijiria lọdun 2023 ati lati dari rẹ de ebute ogo.

Gẹ́gẹ́ bi wọ́n wọ́n o ṣe sọ ọ̀, Lanre Ogunyemi ní gbogbo àwọn ǹkan ti Tinubu ti gbe se nínú oṣelu jẹ́ ẹ̀ri maa jẹ ẹ niso, eyi to si mu u pegede fun ọdun 2023.

Àwọ́n akọroyin to ba akọwé ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti ipinlẹ̀ Eko sọ̀rọ̀ sàlàye pe Tinubu ni ẹto gẹ́gẹ́ bi ọmọ Naijiria láti si ààrẹ Naijiria

" Tinubu ni gbogbo ǹkan to yẹ lati dari orilẹ̀-èdè yìí nítori pe ọmọ Najiriria ni, o wá kù si ọwọ́ àwọn ọmọ Naijiria láti gbà tabi ki wọ́n maa gbàá, o kù si ọwọ ẹgbẹ́ boya wọ́n yóò fàá kalẹ̀ láti soju fun ẹgbẹ́ APC lọdun 2023

" Yala, o ti sọ fun wá o, tabi o fi ami han wá, boya àwọn ènìyàn lòdi si o, ǹkan ti o dá wa lóju ni pe gbogbo ǹkan lo ni láti dari"

Àkọlé fídíò,

Ìlú Eko ló jẹ gbèsè jù ní Nàìjíríà lẹ́yìn ìjọba àpapọ̀

O fi kun alaye rẹ pe Asiwaju ẹgbẹ APC ti lọ́wa si idagbasoke Naijiria tuntun ti a n ri lọ́wọ́lọ́wọ́, ti o si jẹ Mose iran ti a wa yìí.

" Gbogbo apa ibi ti ab a kọri si, , o yẹ ki a pamọpọ pe ti ààrẹ yoo ba lọ iha Guusu, ki a mọ boya Guusu-Iwooru ni tabi Guusu-ila-orun, sugbọ́n ǹkan ti o ṣe pataki jùlọ ni pe, ẹni ti Ade ba to di lo n de ki Naijiria le de ebute ogo"

Ọ̀rọ̀ yìí wáye, ní 2019 ti Tinubu fura rẹ sọ pe oun kọ mọ àwọn to n polongo Tinubu 2023 kiriMi ò m'àwọn ẹgbẹ́ tó ń gbé ''Tinubu 2023'' kiri- Bola Tinubu ati pe oun fẹ gba ijọba ti Buhari ba ti kuro nipo.

Àkọlé fídíò,

Kò sí ǹkan tó ń jẹ́ ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ tàbí ìmọ̀le nínú àgbékalẹ̀ Amotekun - Alake ti Egba