Bayelsa Electiions : Ile ẹjọ́ gíga jùlọ kọ ìpẹ̀jọ́ David Lyon àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Oríṣun àwòrán, OTAHER
Ile ẹjọ giga julọ ti ni gbọingbọin lawọn fi ẹsẹ mulẹ lori idajọ to waye lonii lori idibo gomina ipinlẹ Bayelsa.
Ile ẹjọ naa ni ipẹjọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ati oludije wọn ko ni ojun kankan to ṣee di mu lọwọ bẹẹ si ni wọn ko laṣẹ lati ṣagbeyẹwo ofin ara wọn.
Gẹgẹ bi adajọ Amina Augie to ka idajọ naa lọjọru ọsẹ ṣe sọ ọ, o ni ipẹjọ ẹgbẹ APC kuna lati tọka si aṣiṣe kankan o si jẹ ko di mimọ pe idajọ awọn duro titi laelae.
Adajọ fi kun un pe ko si ile ẹjọ kankan laye to lee tu idajọ yii wo mọ.
Kogi vs Bayelsa: Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀
Idajọ to waye lọjọ kẹtala oṣu keji ọdun yii ba ọjọ ifilọl David Lyon jẹ to si gbe ade fun Sẹnetọ Duoye Diri ti gbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Bayelsa.
Agbẹjọro David Lyon, Afe Babalola ro ẹjọ pe ki ile ẹjọ da ẹjọ ti wọn kọkọ da nu eyi to fa idaduroo onibara rẹ Lyon to si fagile anfani rẹ lati di gomina.
Bakan naa o ni ẹjọ ti wọn kọkọ da ko faaye gba gbigbọ ẹjọ lati ẹnu gbogbo awọn tọrọ kan.
Ẹwẹ, Wole Olanipekun to ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC lori ẹjọ yii sọ pe ile ẹjọ lo lagbara lati ṣe agbeyẹwo ẹjọ wọn o si ni ki wọn ma ṣe da ẹjọ ọjọ kẹtala oṣu keji dun 2020 naa nu.
Mi ò kí ń ṣèèyàn burúkú tàbí Babalawo bí ẹ ṣe mọ̀ mí nínú eré - Fadeyi Oloro