Childhood Games: Ewo nínú àwọn eré ìdárayá ilẹ̀ Yorùbá tẹ ṣe ní kékeré wo lẹ fẹ́ràn jù?

Boju Boju

Oríṣun àwòrán, Others

Ki agbado to daye, nkankan ni adiẹ n jẹ, ki itakun agbaye si to de, eyi tawọn ọdọ fi n se ere idaraya lode oni, ni ọpọ ere idaraya ti wa nilẹ Yoruba, tawọn ọmọde n se.

Ti ọmọde kan ba si dagba si ilẹ Yoruba, yoo ṣe ọkan lara awọn ere idaraya ti awọn ọmọde ma n ṣe, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ wọn lo ti n wọọkun lọ lode oni.

Awọn ere idaraya yii ma n jẹ ki ifẹ gbooro si laarin awọn ewe ati ọdọ ni agboole si agboole, ati wi pe, o ma n wu awọn ọmọde naa lati tete dagba ni kiakia, nitori naa ni wọn ṣe n ṣe awọn ere ohun.

Oríṣun àwòrán, Others

Erebọọlu lo pọ ju laarin awọn ọmọkunrin gẹgẹ bi ere ṣiṣe, amọ awọn ere ọmọde wọnyiii wa ti wọn tun kundun lati ma a ṣe, paapaa ti wọn ba de lati ile iwe ati labẹ osupa lalẹ ti wọn ba de ile.

Awọn ere ọmọde to wọpọ laye igba kan:

Oríṣun àwòrán, Others

Ere Tẹ́ntẹ́:

Ti wọn ba fẹ ṣe ere yii, awọn ọmọdebinrin a kọju si ara wọn, wọn a si ma a patẹwọ, ti wọn a si maa gbe ẹsẹ wọn bakan naa si orin Tẹ́ntẹ́ ti wọn ba n kọ.

Ohun ti awọn ọmọdebinrin naa n lepa ni lati ri daju pe, awọn gbe ẹsẹ bakan naa, amọ ti ẹsẹ wọn ko ba dọgba, ẹni to ṣi ẹsẹ gbe lo kuna ninu ere naa.

Oríṣun àwòrán, Others

Ere Ayo:

Ati ọmọde ati agba ni o ma n ṣe ere ayo. Ninu iho ribiti to ni oju mejila, ti mẹfa si koju ara wọn ni wọn ma n lo pẹlu okuta wẹwẹ abi ọmọ ayo mejidinlaadọta.

Ọmọ ayo mẹrin mẹrin yoo si wa ninu koto kọọkan. Ẹni to ba gbiyanju lati tete jẹ ki awo koto tirẹ kun fun ayo ni yoo gbegba oroke ninu idije naa.

Ere yii maa n jẹ ki ọpọlọ ọmọde ati agba to n ta ji pepe, o n dani laraya, mu ki ifẹ wa, ti yoo si tun fikun imọ isiro awọn to ba n taa.

Ere Boss ati Actor:

Ọpọlọpọ awọn ọmọde ti wọn ba ti wo ere onija a bẹrẹ si ni ṣe awokọse fiimu ti wọn wo ,nipa yiyan ‘Boss’ to jẹ ole ati ‘Actor’ to jẹ bii ọlọpaa ti yoo si bori Boss ninu idije naa.

Boss ma n jẹ alagbara eniyan, amọ Actor lo ma n bori lẹyin idije naa nitori oninu ire ni.

Ere idaraya yii lo kọ wa pe asegbe kankan ko si, asepamọ lo wa, ọjọ gbogbo si ni ti ole amọ ọjọ kan soso pere ni ti olohun.

Oríṣun àwòrán, Others

Ere Talo wa Ninu Ọgba naa:

Lasiko ti awọn ọmọde ba n ṣe ere idaraya yii, wọn yoo pa agbo ribiti kan, wọn a si ma n kọrin, ẹyi po ka.

Lẹyin naa ẹnikan ninu wọn yoo ma a bere pe ‘talo wa ninu ọgba naa’, awọn iyoku yoo ma dahun pe, ‘ọmọ kekere kan ni, ṣe ki n wa wo o’ ?Awọn yoku yoo pariwo pe ‘rara ma waa wo’, a wa ni ko tẹle oun ka lọ.

Bi yoo ṣe mu wọn ni ẹyọ kọọkan niyẹn ti wọn yoo si lọ sa pamọ titi yoo fi ku ẹnikan ti yoo wa lọ wa awọn to ku.

Ere yii saba maa n waye lalẹ labẹ osupa, ki awọn ọmọde to lọ sun, o n mu ki ifẹ gbilẹ laarin wọn, ifarakinra maa n wa, to si tun n da wọn laraya.

Oríṣun àwòrán, Others

Ere Tinko Tinko:

Awọn obinrin lo fẹran ere yii julọ nitori pe awọn meji ni yoo koju ara wọn, ti wọn yoo si ma a kọrin bii ere naa ṣe n lọ.

Awọn mejeeji yoo maa patẹwọ ọwọ mejeeji, ẹni to ba ti kọkọ rẹ ni yoo kuna ninu idije naa.

Oríṣun àwòrán, Others

Ere ẹni to lagbara julọ(Thug of War):

Bi o tilẹ jẹ pe awọn ọmọde ko mọ orukọ ti wọn n pe ere yii nigba naa, wọn ma n pin ara wọn si meji, ti ẹni to si lagbara julọ ni ikọ mejeeji yoo lewaju, ti wọn a si ma a fa okun ni ọna mejeeji.

Ikọ to ba lagbara julọ ni yoo fa ekeji subu kuro ni ila ti wọn fa silẹ, eleyii ti yoo mu wọn bori ninu idije naa.

Ere yii maa n se afikun okun ati agbara fun awọn to n see nitori wọn yoo laagun, to si tun n mu ki ifẹ wa pẹlu.

Oríṣun àwòrán, Others

Ere olokun:

Awọn obinrin lo fẹran lati ma a ṣe ere yii. Awọn akẹgbẹ rẹ yoo ma ka iye igba to n fo soke lori okun. Kete ti okun to fi n fo ba ti kọọ lẹsẹ, to ba ti kuna, ni ẹlomiran yoo bẹrẹ ti rẹ.

Oríṣun àwòrán, Others

Boju Boju:

Ere boju boju jẹ ere ti awọn ọmọde ma n ṣe lati wa ara wọn ni ibi ti wọn ba ti lọ sa pamọ si. Ẹni to n wa awọn ekeji rẹ yoo ma kọrin wi pe,‘ boju boju o, oloro nbọ, ẹ para mọ, ṣe ki n ṣi...’.

Bẹẹ ni yoo ma kọrin titi yoo fi ri awọn ẹni keji rẹ. Ẹni to ba ri ni yoo tun bẹrẹ si ni wa awọn ekeji rẹ kiri.

Ere kẹkẹ:

Awọn ọmọde fẹran lati ma a yii kẹkẹ, wọn si ma n se lati ẹnikan si ekeji ni, titi yoo fi kari awọn toku.