Coronavirus: Ìlú méjìlá rèé tó ti fòfin de dìdì mọ́ ara ẹni torí ìtànkálẹ̀ àrùn

Awọn ero to wa ni papakọ ofurufu

Iyipada ti deba ihuwasi awọn ọmọ eniyan kaakiri agbaye lati igba ti Coronavirus ti bẹrẹ si ni tan kalẹ̀.

Se ni awọn eniyan n sọra ṣe ni ibi iṣẹ, ninu ile ati ni ile ijọsin, lọna ati dẹkun arun Coronavirus, to ti pa eniyan to le ni ẹgbẹrun un mẹta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn ikilọ naa ni ki wọn ṣọra fun ibọwọ, ifẹnukonu paapa ni ẹrẹkẹ, ti asa didi mọ ara ẹni naa si di eewọ.

Oríṣun àwòrán, Professor Akin Ayobami

Ẹ wo orilẹede mejila to ti kọ ifarakinra ni asiko yii:

China:

Beijing to jẹ olu ilu orilẹede China ti sọ fun awọn eniyan pe ki wọn ma ṣe bọ ara wọn lọwọ, amọ ki wọn pa ọwọ wọn pọ, gẹgẹ bi ami ikini.

Wọn tilẹ tun lo ẹrọ igbohunsafẹfẹ fi sọ fawọn araalu pe ki wọn lo asa ibilẹ wọn, ti wọn yoo di osusu ọwọ ọtun, fi lu ọwọ osi (gong shou) lati fi ki eniyan.

Faranse:

Awọn onimọ ti ni ki awọn eniyan yẹra fun asa fifi ẹnu ko ẹrẹkẹ ẹnikeji wọn gẹgẹ bi ikini.

Bakan naa ni iwe iroyin ilẹ naa kọ sita pe ko gbọdọ si asa bibọ ara ẹni lọwọ to wọpọ ni ileeṣẹ lorilẹede naa.

Wọn wa rọ awọn eniyan ilẹ Faranse wi pe ti wọn ba ti tẹju mọ ẹnikeji wọn, wọn ti ki ẹni naa niyẹn.

Oríṣun àwòrán, Others

Brazil:

Ẹka to n risi eto ilera lorilẹede Brazil ti gba awọn eniyan nimọran lati dawọ lilo ohun eelo ti wọn fi n mu tii, ti wọn n pe ni Chimarrao duro na.

Ati wi pe ki wọn ṣọra fun ifẹnukonu, bi ko tilẹ jẹ ni ẹnu.

Germany:

Minisita fun ọrọ abẹle ni Germany, Horst Seehofer fihan gbangba si adari ilẹ naa, Angela Merkel pe, oun ko fọwọ si asa ibọra ẹni lọwọ lasiko yii.

N se ni Horst Seehofer kọ lati gba ọwọ Merkel, ki wọn to bẹrẹ ipade, eleyii to pa adari orilẹede naa lẹrin, to si juwọ soke ki o to joko.

SPAIN:

Awọn adari lorilẹede Spain ti sọ wi pe, o ṣeese ki awọn wogile lilọ si idi awọn ere awọn ẹni mimọ ninu ẹsin Kristẹni ti wọn ma n ṣe ni ọdọọdun, lati fi ẹnu ko wọn lara fun adura.

Wọn ni o ṣeese ki o ma waye ni ọdun yii lọna ati dẹkun itankalẹ aarun Coronavirus.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Romania:

Ijọba ti rọ awọn eniyan lati maṣe fi ẹnu ko ara wọn lẹnu lasiko ọdun Martisor ti wọn ma n ṣe ni ọdọọdun lati fi ifẹ han si ara wọn.

Ijọba ni wọn le fun ara wọn ni ododo amọ ki wọn ṣọra fun fifi ẹnu ko ara wọn lẹnu.

Poland:

Lorilẹede Poland, awọn ẹlẹsin ijọ Aguda ti paṣẹ fun awọn eniyan lati maṣe la ẹnu wọn lati maa gba ounjẹ alẹ Oluwa, amọ ki wọn ma a gba si ọwọ wọn.

Bakan naa ni wọn sọ fun wọn lati maṣe ki ọwọ bọ omi ni ẹnu ọna abawọle ile ijọsin amọ ki wọn ṣe ami agbelebu si ara wọn.

Iran:

Fifi ẹsẹ ki ara wọn ni ohun ti o wọpọ bayii lorilẹede Iran, nibiti eniyan mẹtalelọgọta ti papoda nitori arun Coronavirus. Fidio kan se afihan ibi ti awọn ọrẹ ti wọn lo asọ ibo ẹnu, ti wọn si n fi ẹsẹ ki ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

New Zealand:

Awọn ile iwe kan lorilẹede New Zealand ti paṣẹ pe ki awọn eniyan ye e ki ara wọn nipa fifi imu kan ara wọn, ti wọn n pe ni hongi. Wọn ni orin ikinni nikan ni awọn yoo kọ.

Australia:

Minisita fun eto ilera ni agbeegbe New South Wales, Brad Hazzard ti kilọ fun awọn eniyan ilẹ naa lati maṣe fi ọwọ mejeeji bọ ọwọ ara wọn lọwọ, amọ ki wọn ma a fi ọwọ gba ara wọn lẹyin.

Bẹẹ lo rọ wọn lati ṣe pẹlẹpẹlẹ nipa kiki ara wọn pẹlu ifẹnukonu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

United Arab Emirate (UAE):

Awọn orilẹede to wa labẹ UAE ti rọ awọn eniyan wọn lati maṣe ki ara wọn nipa fifi imu ko imu ara wọn ati bibọwọ ara wọn mọ, amọ ki wọn ma a ju ọwọ si ara wọn ni.

Ilẹ Amerika:

Ẹgbẹ awọn agbabọọlu alapẹrẹ lorilẹede Amerika, NBA ti sọ fun awọn eniyan pe, awọn ko ni le e ma gba ohun ikọwe lọwọ wọn lati le kọ orukọ wọn, titi arun coronavirus yoo fi kuro nilẹ.

Bẹẹ ni wọn ni osuba ni awọn yoo ma a fi ki ara wọn bayii, ki awọn ba le dena itankalẹ arun coronavirus to le ran nipa bibọwọ ara wọn.