Kwara; Ìpínlẹ̀ Kwara yọ orukọ Saraki kúrò lára fasitì wọn

Abubakar Olusola Saraki

Oríṣun àwòrán, Others

Ile igbimọ Asofin ni Kwara ti buwolu aba ofin lati ṣe ayipada orukọ fasiti ipinlẹ Kwara kuro ni Abubakar Olusola Saraki University si Kwara State University.

Abadofin yii, pẹlu aba ofin mẹrin miran nile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa gbe kalẹ ni ọjọ Isẹgun lasiko ti ile joko.

Wọn ni ofin naa yoo mu idagbasoke ba eto ẹkọ ni ipinlẹ naa ati igbelarugẹ isakoso ijọba ibilẹ ni ipinlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade ile asofin naa, wọn ni awọn ti buwọlu aba ofin ọdun 2020 to sọ wi pe, ki wọn yii orukọ fasiti ipinlẹ Kwara kuro ni Abubakar Olusola Saraki University si Kwara State University.

Ile igbimọ aṣofin naa fikun pe, awọn ti fi aba ofin naa ṣọwọ si gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq lati buwọlu, ki o le di ofin.

Oríṣun àwòrán, Others

Abubakar Olusola Saraki, ti wọn fi orukọ rẹ pe fasiti ipinlẹ Kwara tẹlẹri naa, ni aarẹ ile asofin agba ni ọdun 1979 si 1983.

Bakan naa lo jẹ oye Waziri ti ilu Ilorin, ki o to di wi pe o ku ni ọjọ Kẹrinla, ọdun 2012 ni ẹni ọdun mọkandinlọgọrin.

Ìdílé Saraki láti ìran dé ìran, ló ti di ipò ńlá mú ní ìpínlẹ̀ Kwara láti ìgbà dé ìgba.

Bakan naa ni ọmọ rẹ Bukọla Saraki jẹ gomina ipinlẹ Kwara, ki o to di wi pe o lọ si Ile Igbimọ Asofin Agba, ti o si di ipo aarẹ ile igbimọ asofin mu, titi di ọdun 2019 ti idibo gbogboogbo yọ ni ipo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìdílé Saraki láti ìran dé ìran ló ti di ipò ńlá mú ní ìpínlẹ̀ Kwara láti ìgbà dé ìgba.

Ni ọpọ igba ni etò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti salábàpàdé àwọn oríṣiríṣi ìdíle, tí wọn sábà ń dipò ńlá mú nínú ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, látí ìran wọn kan sí ìran wọn míràn tó ń bọ̀.