Federal Girls College Akure: Akẹ́kọ̀ọ́ Federal Girls College Akure ń lọ ẹ̀rọ ìbánísọ̀rọ̀ láti fi bá ọ̀rẹ́kùnrín sọ̀rọ̀ lafí báàjẹ́

Federal Girls College Akure

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán,

Láìpẹ yii ni fidio jade to ṣe afihan akẹkọbinrin ileewe Federal Girls College Akure to n fọ awọn ẹrọ ibanisọrọ tí àwọn akẹkọ̀ọ́ ń lọ̀.

Ile iwe girama Federal Girls College Akure ni ipinlẹ Ondo ti fesi lori fidio to ja rain lori ayelujara to safihan akẹkọọ ti awọn olukọ rẹ ni ki o ma a fọ ẹrọ ilewọ awọn akẹkọọ ẹgbẹ rẹ.

Alukoro ẹgbẹ awọn obi awọn akẹẹkọ ile iwe girama Federal Girls College Akure, Arakunrin Akintunde Akinṣemọla to ba BBC sọrọ fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn olukọ naa laṣẹ lati ba ẹrọ ibanisọrọ awọn ọmọ ile iwe jẹ.

Akinṣemọla ni iwe ofin ijọba apapọ to de eto ẹkọ ni ile iwe alakọbẹrẹ ati girama fi lọlẹ pe ẹru ofin ni ẹrọ ilewọ ni awọn ile ẹkọ, nitori naa ẹnikẹni to ba mu wa si ile ẹkọ ti rufin to de ile iwe girama.

O fikun wi pe o ti le ni ọdun meji bayii ti awọn ọmọ ileewe naa ti n mu ẹrọ ibanisọrọ wa si ile iwe ti awọn si ti n gba lọwọ wọn, amọ ti wọn kọ lati jawọ ninu iwa bẹẹ.

‘Awọn ọmọ to ṣẹṣẹ wọle si JSS1 ni ileewe naa lo fi ẹjọ sun awọn ọga ileewe naa pe awọn to je bi agba si wọn ninu ile iwe naa ma n lọ ẹrọ ibanisọrọ ninu yara ti wọn gbe lorun, ti wọn kii si jẹ ki awọn sun ninu yara.’

‘Awọn olukọ bẹrẹ iwadii lori ẹsun naa, ti wọn si ri orisirisi ẹrọ ilewo ninu ẹru awọn ọmọ ileewe naa.’

Bakan naa ni awọn olukọ fẹsun kan awọn akẹkọọbinrin naa wi pe ọkunrin ni wọn fi ẹrọ ilewọ naa pe, ti wọn a si ma a sọrọ ibalopọ nigba miran.

Alukoro ẹgbẹ awọn obi awọn akẹẹkọ ile iwe girama Federal Girls College Akure fikun wi pe awọn olukọ naa fun awọn akẹkọọ ti ọrọ naa kan lati lọ rọkun nile fun igba diẹ, lẹyin naa ni awọn wa pàsẹ fun lati ba ẹrọ ilewọ naa jẹ.

Akinṣemola ni awọn akẹkọọ tun n ya ara wọn ninu yara, ti wọn si n gbe si ori ẹrọ ikansiraẹni Facebook, Twitter ati Instagram,eleyii to le fa ijamba abi ijinigbe fun wọn.

O ni eyi yoo kọ awọn ọmọ naa lọgbn lati maṣe wu iru iwa yii mọ nitori ọpọ igba ni wọn ti sọ fun wọn ki wọn yee mu u ma si ileewe, nitori yoo fa ifasẹyin fun ẹkọ wọn.akẹkọọ yii.

Bawo ni awọn akẹkọọ naa ṣe n ba awọn obi wọn sọrọ nigba ti wọn ko laṣẹ lati lo ẹrọ ibaraẹni sọrọ?

Akinsemola ni akẹẹkọbinrin kọọkan lo ni alagbatọ ni ileewe naa, ti wọn lọ ma n ba ti wọn ba ni ohun kan ti wọn ṣe alaini, tabi ti wọn ba n ṣe aisan ti wọn si nilo lati ba awọn obi wọn sọrọ.

Bakan naa ni wọn fikun wi pe awọn satide akọkọ ni osoosu ni wọn ma n fun awọn obi laaye lati wa wo awọn ọmọ wọn.

O fikun wi pe ileewe Federal Girls College Akure wa lara awọn ileewe to n ṣe daradara julọ lorilẹede Naijiria, ti awọn olukọ naa si n gbiyanju lati ri wi pe ina wọn ko jọ ajorẹyin.

Alukoro ẹgbẹ awọn obi awọn akẹẹkọ ile iwe girama Federal Girls College Akure naa wa parọwa si awọn obi naa lati maṣe fun awọn ọmọ wọn ni ẹrọ ibanisọrọ wa si ile iwe, ki wọn ba le foju si ẹkọ wọn, ki wọn si maṣe di awọn akẹkọọ to ku lọwọ.