Coronavirus: Ọmọ Nàìjíríà tó darí láti France wá labẹ àyẹwò lórí Coronavirus

Aworan Kọmisana ilera nipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Twitter/LSMOH

Kọmisana feto ilera nipinlẹ Eko ti ni tawọn ko ba ri awọn eeyan meji to ku lara awọn mẹẹdogun to ba ọmọ ilẹ Italy to gbe Coronavirus wọ Naijiria titi ọjọ Ẹti, awọn yoo kede orukọ wọn lori afẹfẹ.

Ọjọgbọn Akin Abayomi fidi ọrọ yi mulẹ nigba ti o n sọ fawọn oniroyin ibi ti wọn ba iṣẹ de lori kikoju itankalẹ aisan Coronavirus.

O tun ṣalaye pe ọmọ Naijiria kan ti o dari lati ilẹ Faranse tawọn ri apẹrẹ pe o le ni aisan naa ti wa labẹ ayẹwo.

Ninu alaye rẹ, o ni awọn ti gba ẹjẹ arakunrin naa to lo ọjọ meje ni ilẹ Faranse ti o si pada si Eko ni nkan bi ọjọ mẹta sẹyin.

O ni ẹni naa ṣe afihan awọn apẹrẹ bi ori fifọ ati ofikin ti awọn ko si fẹ jafira boya o le ni Coronavirus nitori ilẹ tawọn eeyan ti n ko aisna naa ran ara wọn lo ti dari de.

Àjọ elétò ìlera lágbáyé ń lọgun pé èèyàn lée kó àrùn coronavirus nípasẹ̀ níná owó bébà

Aarun Coronavirus ti di ẹrujẹjẹ to n dẹru bonile ati alejo kaakiri agbaye bayii, bẹẹni ajọ eleto ilera lagbaye ti jẹ ko di mimọ bayii pe, beba owo naa lee ṣe agbodegba fun itakalẹ arun yii.

Ajọ WHO wa ke gbe amọran kalẹ pe yoo dara o ki gbogbo eeyan maa ṣe eto inawo ori ayelujara ti a mọ si Cashless policy bi wọn ba fẹ ra ohunkohun.

Amọṣa ṣe a kii mọọ gun, mọs tẹ ki iyan ewura o maa ni koko. Ajọ WHO ni bi a ba wa ri awọn asiko ti awọn eeyan na owo beba, ki wọn rii daju pe wọn n fọ ọwọ wọn ni kiakia.

Ajọ eleto ilera lagbaye ṣalaye pe kokoro arun lee lugọ si ara beba owo fun ọpọlọpọ ọjọ eleyi ti wọn ni o mu ki o ṣe pataki fun awọn eeyan lati yẹra fun lilo owo beba fun karakata wọn bi o ti wulẹ o mọ.

Coronavirus: Èèyàn 49 tó bá ọmọ orílẹ̀èdè Italy tó kó coronavirus Nàìjíríà wọ bàlùú làjọ WHO ti rí, wọ́n ń wá èèyàn 35 míràn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijo wa ajọ jo, awẹ wa ajọ gba ni ọrọ gbigbogun ti arun Coronavirus bayii.

Nibayii, ajọ eto ilera lagbaye, WHO ko fẹ da ijọba orilẹede Naijiria da eto gbigbogun ti arun Coronavirus pẹlu bi ajọ naa ti ṣe n funrarẹ wa awọn eeyan to ba arinrinajo ọmọ orilẹede Italy to ko arun Coronavirus wọ Naijiria ni ọsẹ to kọja.

Kọmiṣọna feto ilera ni ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayọmi lo ṣi aṣọ loju igbesẹ ajọ WHO. Ọjọgbọn Abayọmi ni gbogbo awọn ero ọkọ to ba ọmọ orilẹede Italy naa to wọle sorilẹede Naijiria lati ilu Milan lorilẹede Italy ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu keji ọdun yii ni wọn n wa bayii.

Arakunrin ọmọ orilẹede Italy naa ṣi n gba itọju ni ileewosan fun awọn awọn ajakalẹ arun to wa ni Yaba nilu Eko.

Ninu awọn eeyan mẹrinlelọgọrin lara awọn to baa wọ baluu pọ ni wọn wa ni ilu Eko. Mọkandinlaadọta ninu wọn ni wọn ti ri kan si bayii, gẹgẹ bi kọmiṣọna feto ilera nipinlẹ Eko ṣe sọ. Marundinlogoji ni wọn ṣi n wa kaakiri bayii.

Bakan naa lo fi kun un pe Eeyan marundinlaadọrin ninu wọn ti wọn ti rinrinajo kuro nilu Eko lọ sawọn ilu miran pẹlu wa labẹ itanna ajọ WHO lati mọ ibi ti ọkọọkan wọn wa.

Àkọlé fídíò,

Aremu: Eré ìtàn nípa ìbí, àti jéèyàn pẹ̀lú ìpèníjà Olusegun Aremu Obasanjo

O ni o ṣeeṣe ko jẹ wi pe awọn iroyin ti wọn fi silẹ lasiko ti wọn n mura ati rinrinajo naa lo fa segesege aile ri wọn lọwọlọwọ bayii.

Bakan naa ni o ṣalaye pe awọn marundinlogoji ti wọn ni ajọṣepọ pẹlu arakunrin naa lasiko to fi lọ si ipinlẹ Ogun ṣi wa labẹ ayẹwo ọẹọ mẹrinla bayii lati mọ boya ara wọn mọ tabi awọn naa ti ko arun ọhun.