Amotekun : Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Akeredolu buwọ́lu àbádòfin nípa Àmọ̀tẹ́kùn

Amotekun

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti buwọlu abadofin to ṣe ifilọlẹ ikọ amọtẹkun ni ipinlẹ Ondo.

Oju opo ikansiraẹni Twitter gomina naa ni o ti fi lede wi pe oun ti sọ Amọtẹkun di ofin ni ipinlẹ naa.

Gomina naa fi da awọn eniyan loju wi pe eto aabo fun awọn eniyan ipinlẹ naa lo jẹ oun logun.

Atiwipe awọn ti ṣetan lati ri daju pe awọn ṣe oun gbogbo ti awọn nilo lati ri wi pe eto aabo to gbooro wa ni ipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Awọn eniyan eniyan to fesi si oun ti gomina naa sọ gboriyin fun Akeredolu fun ipa ribiribi to ko nipa ifilọlẹ ikọ amọtẹkun fun eto aabo ipinlẹ naa ati ilẹ Yoruba lapaapọ.

Bẹẹ naa ni awọn eniyan lori ẹrọ Twitter naa ki awọn eniyan ipinlẹ Ondo ku oriire fun aṣeyori ofin to rọ mọ ikọ Amọtẹkun.

Bakan naa, gbogbo awọn ile igbimọ aṣofin to wa ni ilẹ Yoruba ni wọn ti buwọlu abadofin naa, ti wọn si ti fi ṣọwọ si gomina ipinlẹ naa lati buwọ lu u.