Baba Obasanjo: Àwọn ọ̀rẹ̀ sàpèjúwe Baba Obasanjọ ní ọjọ́ ìbí 83 wọn

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹgbẹ awọn agbaagba nilẹ Yoruba ti sapejuwa aarẹ tẹlẹri lorilẹede Naijiria gẹgẹ bi ẹbùn rere ni Baba Obasanjọ jẹ fun Naijiria.

Akowe ẹgbẹ Yoruba Council of Elders (YCE), Kunle Olajide lo ṣe apejuwe Baba Obasanjọ bẹẹ lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi pe wọn pe ẹni ọdun mẹtalelọgọrin.

Àkọlé fídíò,

Aremu: Eré ìtàn nípa ìbí, àti jéèyàn pẹ̀lú ìpèníjà Olusegun Aremu Obasanjo

Olajide ni oun ko i tii ri ẹni to fẹran orilẹede Naijiria gẹgẹ bi ọkan soso to Baba Obasanjọ nitori wọn ja fitafita lati ri wi pe orilẹede Naijiria wa papọ lai si ipinya.

O fikun pe ọkunrin takuntakun ni Baba Obasanjọ, ti o laya ti kosi bẹru lati sọ otitọ fun ẹnikẹni.

Ninu ọrọ rẹ ẹgbẹ agba ni ilẹ Yoruba ni Obasanjọ kii se ẹlẹyamẹya, bẹẹ ni kii fun eniyan ni iṣẹ tabi fi ẹni si ipo nitori wọn jẹ ẹya kan naa, eleyii to tako iwa wobiliti wọbia to wọpọ bayii ni awujọ wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kunle Olajide ni Baba Obasanjọ ni ọgbọn to bẹẹ gẹ ti ko jẹ ijọba ologun tun gba ijọba lẹyin ti o ṣẹ ijọba alagbada fun ọdun mẹjọ lati ọdun 1999 si 2007.

Amọ, o gba baba niyanju lati mu ki ọrọ ilẹ Yoruba jẹ ẹ logun, ki o si ba wọn gbe ọrọ atuntọ orilẹede Naijiria lọ si awọn ibi giga ti wọn ti n fọhun, ki orilẹede Naijria le di atunto.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ẹwẹ, Arakunrin Babablola Ogunbuyide to jẹ gẹgẹ bi ọrẹ ati ọmọ si Baba ọbasanjọ naa ṣẹ apejuwe rẹ ẹni rẹrẹ ti Olorun ṣẹda rẹ.

Ogunbuyide wa tẹsiwaju lati sọ ohun ti awọn eniyan ko mọ nipa Baba Obasanjo:

  • Oni inu ire to si ni ifẹ awọn eniyan
  • Baba Obasanjọ ni ọgbọn lati tun nkan to nibikibi ti o ba wa.
  • Oun wuwa si ni gẹgẹ bi ọmọ lai fasẹyin fun ẹnikẹni to ba tọ ọ wa.
  • Baba Obasanjo kii fi ọwọ rọ ẹnikẹni sẹyin tabi da ọrọ wọn nu.
  • Baba kii binu nitori eniyan ṣe aṣiṣe, amọ o fẹran ki eniyan mọ ẹbi rẹ ni ẹbi,ki o si ṣe atunsẹ.

Eyi ni akojọpọ aworan ere itage itan Baba Oluṣegun Obasanjọ:

Àkọlé àwòrán,

Ọbasanjọ jẹ adari Naijiria labẹ ijọba ologun ni ọdun 1976 si 1979 ati ijọba tiwantiwa ni ọdun 1999 si ọdun 20007

Àkọlé àwòrán,

Ìdílé Owu ni agbeegbe Ibogun-Olaogun ni ipinlẹ Ogun ni wọn ti bi Baba Obasanjo,ti o si lọ ile iwe ni Abẹokuta.

Àkọlé àwòrán,

Baba Obasanjọ darapọ mọ ikọ ọmọogun Naijiria ni ẹka imọ ẹrọ ti o si jagun ni Congo, Britain, ati India titi to fi de ipo ọgaagun.

Àkọlé àwòrán,

Ni igba ọgun Biafra, Baba Obasanjọ ko ipa ribiribi lati ri wi pe wọn rẹyin iyapa ẹya Igbo kuro lara Naijiria.

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin iku Ọgaagun Murtala Muhammed ni ikọ ọmọgun Naijiria yan Obasanjọ gẹgẹ bi adari orilẹede Naijiria.

Àkọlé àwòrán,

Baba Obasanjọ gbe ijọba alagbada fun Shehu Shagari ko to di wi pe ọgagun Sani Abacha wa gba ijọba ni ọdun 1993.

Àkọlé àwòrán,

Lẹyin ti Baba Obasanjọ pada de latin ọgba ẹwọn ni o jẹ adari orilẹede Naijiria labẹ ijọba tiwantiwa lọdun 1999 lati ẹgbẹ oṣelu PDP.

Awọn aworan yii wa lati ileeṣẹ BBC News Yoruba