Coronavirus: Orílẹ̀èdè Cameroon ti ní alárùn àkọ́kọ́

Awọn eleto ilera

Orilẹede Cameroon ti fi lede pe awọn ti ni ẹni akọkọ to ni aarun Coronavirus ni orilẹede wọn.

Minisita eto ilẹra lorilẹede naa,Manaouda Malachie sọ wi pe ẹni ọdun mejidinlọgọta lati ilẹ Faranse ni ẹni to gbe arun naa wọ ilẹ Cameroon.

Wọn fikun pe ọjọ kẹrinlelogun, osu keji, ni ẹni naa wọ orilẹede wọn ti awọn si tete ṣe akiyesi nitori awọn eto ayẹwo ti awọn ti fi lele

Nibayii, ọkunrin naa ti wa ni ipamọ ni ile iwosan to wa ni Yaounde lorilẹede naa.

Bakan naa ni wn fikun wi pe awọn n ṣiṣẹ takuntakun lati ri wi pe ayẹwo to peye n waye ni awọn ibudokọ oju omi, ti papakọ ofufuru ati bẹẹ lọ.

Minisita fun eto ilẹra naa ni awọn n ṣe ilanilọyẹ fun awọn eniyan wọn lori ri wi pe wọn koju aarun naa lọkunkundun.

Orilẹede Cameroon ti darapọ awọn orilẹede bii Egypt, Nigeria, Algeria ati South Africa to ti ni arun Coronavirus.

Coronavirus tún ti ṣe ọṣẹ́ lórí iṣẹ́ líla ojú ọ̀nà relùwe láti Eko sí Ibadan - Ìjọba àpapọ̀

Ijọba orilẹede Naijiria ti sọ wi pe, ajakalẹ arun Coronavirus lo mu ki wọn dawọ iṣẹ ti wọn n ṣe, loju ọna reluwe Eko si Ibadan.

Minisita fun ètò irinna, Rotimi Amaechi lọ sọ bẹẹ ni ilu Abuja, lasiko to n sọrọ lori ibi ti wọn ba iṣẹ de.

Amaechi ni awọn oṣiṣẹ ilẹ China to n ṣe oju ọna reluwe naa ṣi wa lorilẹede China, lẹyin ti ijọba ilẹ wọn paṣẹ ki wọn duro si ile.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Minisita naa fikun pe, awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ to n ṣe eto oju ọna irin, CCECC ko i tii pada wa si Naijiria, nitori ati koju arun coronavirus nilẹ wọn ati itankalẹ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Others

O ni ti ko ba si ti arun coronavirus ni, awọn iba ti pari iṣẹ oju ọna reluwe Eko si Ibadan, bi o tilẹ jẹpe o ku diẹ ki iṣẹ akanṣe naa pari.

Lọ́pọ̀ ìgbà ni ìjọba ti kéde pé àwọn yóò ṣi òpópònà ní Osù Kẹ́rin, ọdun 2020 tí yóò bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́.