Emir of Kano: Oríṣiríṣi ẹ̀sùn ni ìjọba ìpínlẹ̀ Kano kà sí Sanusi l'ẹ́sẹ̀

Sanusi Lamido Sanusi

Oríṣun àwòrán, Majeeda Studio

Ọsan ọjọ Aje ni ijeba ipinlẹ Kano kede lati ẹnu akọwe ijọba, Alhaji Usman Alhaji pe awọn ti rọ Emir ilu Kano, Sanusi Lamido Sanusi loye.

Akọwe ijọba sọ awọn idi to mu ki ijọba o gbe igbesẹ naa. O sọ ninu atẹjade to fi sita pe gbogbo awọn ọmọ igbimọ alaṣẹ ipinlẹ Kano lo fẹnuko pe ki wọn o yọ Emir Sanusi l'oye.

BBC ṣe atupalẹ awọn idi ti ijọba fi sita, o si ba awọn oloṣelu sọrọ lori awọn idi naa:

  • Emir ilu Kano, kii gbọran si aṣẹ to ba wa lati ọọfisi gomina ati awọn ileeṣẹ ijọba.
  • Bakan naa ni kii lọ si ipade kankan ti ijọba ba pe lai si arigbamu idi ti ko fi lọ si ipade. Ijọba sọ pe iwa aigbọran ni.
  • O fojuhan pe Sanusi Lamido ti kọ lati tẹle abala ofin kẹtala ninu iwe ofin ipinlẹ Kano ti ọdun 2019. Ti wọn ba si fi silẹ ko tẹsiwaju, yoo dojuti ilu Kano.

Didaabo bo iyi ati ẹyẹ ilu Kano

Ijọba sọ ninu atẹjade to fi sita pe oun rọ Emir Sanusi l'oye lati le pa aṣa, iṣe ati awomọni ọrọ ẹsin Kano to ti wa lai mọye ọdun mọ kuro lọwọ yẹyẹ.

Awọn ilana ati aṣẹ ijọba

Onimọ nipa eto oṣelu, Kabiru Safi Sufi, to jẹ olukọni fasiti kan nipinlẹ Kano sọ fun BBC pe idi pataki ti ijọba fi rọ Emir Sanusi l'oye ni bi o ṣe maa n bu ẹnu ẹtẹ lu awọn ilana iṣejọba gomina Abdullah Umar Ganduje.

Ọpọ lo ri titako ti Emir tako igbesẹ ijọba lati ya owo lọwọ orilẹ-ede China fi ṣe oju'rin fun reluwe gẹgẹ bi didena idagbasoke ipinlẹ Kano.

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Ọdun 2014 ni Sanusi Lamido Sanusi jẹ oye Emir lẹyin ti wọn gba iṣẹ lọwọ rẹ gẹgẹ bi gomina banki apapọ Naijiria

Gẹgẹ bi onimọ nipa ọrọ aje, Emir sọ pe ko si oore kankan ti ipinlẹ Kano fẹ ri lara owo yiya nitori pe iṣẹ akanṣe naa ko le so eso kankan.

Ọrọ naa bi ijọba ipinlẹ Kano ninu, lati igba naa si ni wahala ti n rugbo laarin wọn.

Awọn eniyan pataki bi igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ati Alhaji Aliko Dangote wa lara awọn to ti gbiyanju lati pari ija laarin gomina ati Emir.

Gomina Ganduje si kọwe mabinu si Emir nigba naa.

Ọrọ Oṣelu

Awọn alatilẹyin gomina ipinlẹ Kano ti ṣaba maa n fi aidunnu wọn han si ipa ti Emir n ko lori eto oṣelu ipinlẹ naa.

Gomina Ganduje ati awọn alatilẹyin rẹ tilẹ fi ẹsun kan Emir Sanusi pe ẹgbẹ oṣelu PDP lo ṣatilẹyin fun ninu eto idibo gomina to kọja.

Wọn sọ pe o fi ikorira ati atako rẹ fun Ganduje han ni gbangba, to si tun fi owo rẹ ran oludije ẹgbẹ PDP lọwọ.

Ṣugbọn Emir sọ pe ọrọ ko ri bẹ ẹ.

Eyi lo mu ki awọn ololufẹ Gomina Ganduje o wọ gbọngan kan ni ọfiisi ijọba ipinlẹ Kano, ti wọn si yọ aworan Emir Sanusi kuro lẹyin ti Ganduje wọle saa keji sipo gomina.

Eyi tun fa ede aiyede laarin awọn adari mejeeji, eyi to mu ki ijọba o tun gbe igbesẹ lati rọ Emir l'oye.

Pipin aṣẹ Emir ilu Kano

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán,

Ijọba ipinlẹ Kano fi awọn Emir mẹẹrin miran jẹ lati din agbara ti Emir Sanusi ni ku.

Bi ijọba ipinlẹ Kano ṣe fi awọn Emir mẹẹrin miran jẹ, jẹ apẹẹrẹ pe agbara ti Emir Sanusi ni ti dinku.

Awọn Emir tuntun mẹẹrin naa wa ni agbagbe Gaya, Karachi, Bichi ati Rano.

Igbesẹ ti ijọba gbe yii tubọ mu ki ina ija laarin gomina ati Emir Sanusi o jo si.

Ko si pẹ si igba naa ni ijọba bẹrẹ si wadii rẹ fun iwa nina owo ilu fun igba keji.

Emir lọ sile ẹjọ, o si gba aṣẹ to fofin de igbimọ top n wadii rẹ.

Bi ọmọ o jọ ṣokoto, yoo jọ kijipa

Emir Sanusi Lamido Sanusi kọ ni Emir akọkọ ti wọn yoo rọ l'oye.

Wọn ti rọ baba-baba rẹ, Muhammad Sanusi Kini l'oye lasiko ti awọn alaṣẹ ijọba sọ l'ọdun 1963 pe ko bọwọ fun awọn.

Baba-baba rẹ ko kọja ọdun mẹsan lori oye ti wọn rọ ọ l'oye.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe wọn ti le Emir Kano tẹlẹ, Lamido Sanusi lọ si ipinlẹ Nasarawa lẹyin ti ijọba Gomina Ganduje rọ ọ loye tan.

Kọmiṣọnna fun eto iroyin nipinlẹ Kano, Muhammad Garbaṣalaye fun BBC pe ko si ewu kankan fun Sanusi nibi to wa bayii.

O ni ijọba ti ṣeto to mọyan lori lati gbe Sanusi lọ si ibugbe rẹ tuntun lai si ifoya.

Iroyin ti a kọ gbọ ni pe niṣe lawọn ẹṣọ eleto aabo n yin taju taju ni aafin Emir kano lẹyin ti ijọba rọ Sanusi loye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

BBC ri awọn obinrin laafin Emir kano ti wọn n ju oko lati fi ẹhonu han

Aminu Ado Bayero rọ́pọ̀ Lamido Sanusi gẹ́gẹ́ bí Emir ìlú kano

Ọba mẹwaa igba mẹwaa, Aminu Ado Bayero rọ́pọ̀ Lamido Sanusi gẹ́gẹ́ bí Emir tuntun ìlú kano.

Akọwe ijọba ipinlẹ Kano, Alhaji Usman Alhaji lo kede Emir tuntun lẹyin wakati diẹ ti ijọba Abdulahi Ganduje rọ Lamido Sanusi loye.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Kano

Alhaji ṣalaye pe igbesẹ ijọba wa ni ibamu pẹlu ofin ajọ afọbajẹ ilu Kano ti ọdun 2019.

Akọwe ijọba ipinlẹ Kano ni awọn afọbajẹ mẹrin ti kọkọ dabaa Aminu Ado Bayero fun ipo Emir tẹlẹ.

Bayero ni Emir kẹẹdogun ti yoo jẹ lati igba ti ijọba Fulani ti bẹrẹ niluu Kano.

Àwọn ọlọ́pàá ti gbé Emia ìlú Kano, Lamido Sanusi kúrò ní ààfin rẹ̀ lẹ́yìn tí ìjọba rọ̀ ọ́ l'óyè

Ìròyìn láti ìpínlẹ̀ Kano sọ wí pé àwọn agbófinró ti gbé Ẹmia Sanusi jáde láti ààfin rẹ niluu Kano.

Ṣùgbọ́n kò sí àlàyé tó kún lóríi ibi tí wọ́n gbée lọ tàbí irú ipò tó wà lọ́wọ́lọ́wọ́.

Fidio bi nkan ṣe ri ni aafin Emir ilu Kano, Sanusi Lamido Sanusi lẹyin ti ijọba ipinlẹ Kano rọ ọ l'oye.

Igbimọ iṣakoso ijọba ipinlẹ Kano lo rọ Emir Sanusi loye ni ọjọ Aje, ọjọkẹsan oṣu kẹta ọdun 2020.

O ti to ọjọ mẹta kan ti gbun-gbun-gbun ti n waye laarin gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Umar Ganduje ati Ẹmia Lamido Sanusi.

Akọwe ijọba ipinlẹ Kano ninu atẹjade kan ṣalaye pe igbimọ iṣejọba ipinlẹ naa yọọ loye lori ẹsun pe o n tako aṣẹ ti gomina ipinlẹ naa n pa.

Bakannaa lo ni lara awọn iwa titapa sofin ati aṣẹ naa ni bi o ṣe kọ lati farahan lawọn ipade ati eto ti ijọba ipinlẹ naa ba gbe kalẹ laisi awijare to yanranti.

Àkọlé fídíò,

Obasanjo: Àwọn èèyàn ìpínlẹ̀ Ogun ní iṣẹ́ ṣì pọ̀ fún Ọbasanjọ láti ṣe fún mẹ̀kúnù Nàìjírìà

O ni ọpọlọpọ igba ni Mallam Sanusi ti tako awọn agbekalẹ ofin to de oye jijẹ ni ipinlẹ naa eleyi to ni yoo ba iyi ilu Kano jẹ bi wọn ko ba mojuto.

Ijọba ipinlẹ Kano ni awọn gbe igbesẹ lati yọ Sanusi nipo Ẹmia ilu Kano lati daabo bo aṣa, iṣẹṣe ati ẹsin ti o mu iyi ba ilu Kano.

Gomina Ganduje ti ipinlẹ Kano wa ke si awọn eeyan ipinlẹ naa lati fọkanbalẹ ki wọn si maa wa iṣẹ oojọ wọn lọ ati pe laipẹ ni wọn yoo yan Ẹmia tuntun.