Emir of Kano: Èyí ni àwọn ohun márùn ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa Sanusi tí wọ́n yọ nípò Emir

Sanusi

Oríṣun àwòrán, @ayemojubar

Ọjọ Aje, ọjọ kẹsan an oṣu Kẹta ọdun 2020 ni ijọba ipinlẹ Kano yọ Sanusi Lamido Sanusi nipo gẹgẹ bi Emir ilu Kano, lẹyin ede ayede to waye laarin rẹ atiu ijọba ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade kan ni ijọba Kano ti fẹsun kan Sanusi pe, ko bọwọ fun ofin ati awọn ilana kan, lo jẹ ki wọn fi ọwọ osi juwe ile fun un.

Eyii ni awọn ohun meje to yẹ ki ẹ mọ nipa Emir ana ọhun.

1. O man n sọ eroungba rẹ lai woju ẹnikẹni

Muhammadu Sanusi jẹ ẹni kan ti kii bẹru ati sọ ohun to ba wa ninu ọkan rẹ fun ijọba lai bikita ohun to le tẹyin rẹ jade.

Ko to gori oye Emir, Sanusi ma n sọrọ pẹlu igboya lori ọrọ iṣejọba ati ọrọ aje orilẹ-ede Naijiria.

Sanusi ko gbe ọrọ oṣelu ti sẹgbẹ kan nitori ọpọ igba lo ti bu ẹnu atẹ lu awọn adari ni iha Ariwa Naijira fun aibikita wọn lori awọn eeyan ti wọn n ṣejọba le lori.

Àkọlé fídíò,

Facebook love: Ọla àti Folashade ṣègbéyàwó lẹ́yìn ọjọ́ mọ́kànlá tí wọ́n ríra ni Facebook

2. Bo ṣe ṣẹlẹ si baba naa lo ṣelẹ si ọmọ

Lamido Sanusi gori oye lọdun lọdun 2012 lẹyin ẹgbọn baba rẹ, Ado Bayero.

Baba to bi baba rẹ, Muhammadu Sanusi kinni ni Emir kọkanla ilu Kano lati ọdun 1953 titi di ọdun 1963.

Gẹgẹ bi wọn ṣe yọ Sanusi nipọ lọdun yii naa ni wọn yọ baba to bi baba Sanusi ọhun naa nipo, ẹsun ti wọn fi kan baba bab a rẹ naa ni pe, o n tẹ oju ofin mọlẹ.

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig

3. Ọlọpọlọ pipe ni Sanusi

Sanusi ṣeṣẹ lawọn ile ifowopamọ kaakiri ko ti de ipo ọga agba ile ifowpamọ apapọ ni Naijiria.

Lẹyin to kawe jade ni ile iwe Kings college to wa ni ilu Eko, o tẹ siwaju ninu ẹkọ rẹ si fasiti Ahmadu Bello ni Zaria, nibi to ti kẹkọ gboye.

Nitori ọpọlọ pipe to ni lo jẹ ki aarẹ Umaru Musa Yar'Adua faa kalẹ lọdun naa lọhun gẹgẹ bi ọga agbaile ifowopamọ apapọ Naijira.

4. Boṣe gori alefa Emir

Awọn kan gbagbọ pe bi Sanusi ṣe gori alefa Emir lọwọ oṣelu ninu.

Wọn ni bi Sanusi ṣe gba lati joye Emir jẹ ọna abayọ fun un ko ma baa jẹjọ lori ẹsun iṣowo baṣubaṣu ti wọn fi kan an gẹgẹ bi gomina banki apapọ Naijiria.

Awọn miran tun n sọ pe ibatan rẹ ni oye naa tọ si lati joye Emir, wọn ibatan rẹ ọhun ni ni ojulowo ẹni to yẹ ko gori alefa Emir ọhun.

Àkọlé fídíò,

International Womens day: Àwọn obìrintọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn

5. Ẹni to tako ilana

Nigba iṣejọba rẹ gẹgẹ bi Emir ilu Kano, ọpọ awọn awọn eeyan oke Ọya lo n wo Sanusi bi ẹni to n tako ilana aṣa awọn eeyan rẹ.

Eyii ko ṣeyin bo ṣe ma n sọrọ tako awọn to n ṣẹlẹ lagbegbe ọhun bii; igbeyawo ọmọbinrin ti ko tii balaga, bo ṣe yẹ ki ijọba kọ awọn ile iwe dipo Mọsalaṣi, eti awọn nkan mii.

Yatọ si eyi, Sanusi ma n sọrọ tako bi awọn eeyan Oke Ọya ṣe n bimọ bẹrẹ, leyi to ni o n fa iṣẹ ati iya lagbegbe ọhun, ti ko si dun mọ awọn eeyan naa ninu.

Ọpọ igba ni Sanusi ma n sọrọ tako ijọba Kano pe o fi ẹtẹ silẹ lati mojuto lapalapa leyi to bi iwaadi iwa ibajẹ kan ninu ijọba naa.

Lẹyin iwaaadi naa ni ijọba ipinlẹ Kano, labẹ iṣakoso Abdullahi Umar Ganduje yọ nipo gẹgẹ bi Emir lu ọhun.

Àkọlé fídíò,

Fadeyi Oloro: Ọfọ̀, àyájọ́ kò ràn án lọ́jọ́ tí 'ṣó o láyà' bá a lálejò