Coronavirus in Nigeria: Àwọn ìlànà tó tọ̀nà láti tọ̀ tí o bá fura pé o ní àrùn Coronavirus

Arun Coronavirus ti tan de, o kere tan, ọgọrin orilẹ-ede, ilẹ Gẹẹsi ati Naijira si jẹ ọkan lara rẹ.

Arun Coronavirus maa n tan kan nigba ti ẹni to ba ti lugbadi arun naa ba hukọ, ti afẹfẹ si gbe.

Ẹlomiran le mi iru afẹfẹ bẹ simu, tabi to ba fọwọ kan ibi (ori aga ijoko tabi ori tabili) ti arun naa ti bale, ti iru ẹni bẹ si fi ọwọ naa si oju, imu tabi ẹnu rẹ.

Bi o ba wa kẹẹfin pe o ni arun yii, awọn igbesẹ ti o lee gbe wa ninu fọnran fidio yii.