Nike Suliyat: Ọ̀dọ́mọdébìnrin akéwì tó n fi ẹ̀ṣà kìlọ̀ ìwá lásìkò yìí

Ọmọ tó bá sọ ile nu...- Nike Suliat.

Suliat Ogundele, to jẹ ọdọmọde akewi, to n fi ẹṣa egungun ki awọn eniyan lo ba BBC Yoruba lalejo.

O ménuba ajọṣepọ oun ati Baba Ajobiewe Arẹmu Ayilara, ogbontarigi akewi ti ọpọ n wari fun.

Okoto Akewi ọdọmọdebinrin yii sọrọ nipa ipa ti aṣa ati ori ẹni n ko ninu aye ẹni.

O gba awọn ọdọ bii tirẹ ni imọran lati tọju iwa wọn daadaa nitori iwalẹwa ọmọ eniyan.

Ẹṣa egungun jẹ ewi abalaye to jẹ atẹnudẹnu ti wọn maa n fi ki egungun ko ma baa rẹ wọn ninu ẹ̀kú.

Bakan naa ni wọn maa n lo nibi awọn ayẹyẹ loriṣriṣi gẹgẹ bii oriki koriya.

Okan lara ẹya litireṣọ Yoruba ni Ewi alohun ninu eyi ti ẹṣa ti awọn baba wa n kọ awọn ọmọ wọn lati iran de iran nilẹ Yoruba wa.