Coronavirus update: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko yóò pín ìrẹsì, ẹ̀wà, àti oúnjẹ míì fún àwọn èèyàn

Babajide Sanwo-Olu Image copyright @jidesanwoolu
Àkọlé àwòrán Lara awọn ounjẹ ti ijọba Eko yoo pin fun awọn eeyan ni irẹsi, ẹwa, garri, ata, ati bẹbẹ lọ.

Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti bẹrẹ igbeṣẹ lati pin ounjẹ fun awọn ọmọ ipinlẹ naa lẹyin igbele to wa lode nitori arun Coronavirus.

Sanwo-Olu sọ pe ijọba oun gbe igbeṣẹ yii lati mu adinku ba iyan ati ebi lasiko ti awọn eeyan ko lọ ibi iṣẹ oojọ wọn.

O ni ipele akọkọ yi wa fun ẹgbẹrun lọna igba idile, pẹlu ireti pe eyan mẹfa lo wa ninu idile kan.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Kò sí ẹni tí coronavirus kò le mú

Lara awọn ounjẹ ti ijọba Eko yoo pin fun awọn eeyan ni irẹsi, ẹwa, garri, ata, ati bẹbẹ lọ.

Sanwo-Olu sọ pe oun fẹ ki ounjẹ ti ijọba oun ba pin fun awọn eeyan le to wọn jẹ fun oṣe meji, ati pe ijọba rẹ yoo ma woye ibi ti ọrọ arun Coronavirus naa yoo yọri si.

Gomina ọhun wa pari ọro rẹ pe ijọba n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe wọn wa ni alaafia ati irọrun, nitori naa, ki awọn eeyan gbiyanju lati joko sile wọn.

Coronavirus: Kò sáyè fún ìwọléwọ̀de ní gbogbo ibodè ìpínlẹ̀ Kano mọ́ - Ìjọba Kano

Image copyright facebook/Salihu Tanko Yakasai

Ijọba ipinlẹ Kano ti sọ pe oun yoo ti gbogbo ibode to wọ ipinlẹ naa lọna ati le dena itankanlẹ arun Coronavirus.

Bo tilẹ jẹ pe ko tii si ẹnikẹni to ni Coronavirus ni Kano, ijọba ipinlẹ naa ko fi ọrọ naa ṣere rara.

Agbẹnuso ijọba ipinlẹ ọhun, Abba Anwar sọ ninu atẹjade kan pe ijọba gbe igbeṣẹ ọhun ki aarun Coronavirus ma ba wọ ipinlẹ naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Fífi nkan bó ìmu nìkan kò le dènà kíkó coronavirus

Anwar sọ pe wọn yoo gbe agadagodo ṣenu ibode ipinlẹ naa lati aago mejila ọsan, ọjọ Ẹti, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2020.

Agbẹnusọ ijọba ọhun ni wọn yoo ṣe adinku si bi awọn eeyan ṣe n rin kiri laarin ilu ati awọn ibi ti eeyan ma n pọsi julọ.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, Gomina ipinlẹ ọhun, Abdullahi Umar Ganduje gbe igbesẹ lati ti ilekun ibode ki ẹnikẹni lati ilu miran ma baa ko aarun ọhun wọle.

Umar ni ijọba yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ ni ikawọ rẹ, lati rii pe oun pese aabo to yẹ fun awọn eeyan ipinlẹ naa.

O tẹsiwaju pe "A rọ gbogbo ara ilu lati fọwọ sowọpọ pẹlu awọn alaṣẹ ati oṣiṣẹ eto ilera lati daabo bo ipinlẹ Kano ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ lọwọ ajakalẹ arun yii."

Image copyright facebook/Salihu Tanko Yakasai

Gomina Ganduje wa rọ awọn ara ilu lati fi ọwọ pataki mu imọtoto era ẹni.

O ni ki wọn jinna si awujọ elero pupọ, ki wọn maa fọ ọwọ pẹlu ọṣẹ ati sanitaisa ni gbogbo igba ki aarun naa le jinna rere si ayika wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCoronavirus: Àwọn ìlana to tọ̀nà lati tọ ti o ba fún pe o ni ààrun

Coronavirus: Àwọn ọ̀nà ti ìjọba fi ran ará ìlú lọ́wọ́ lásìkò coronavirus

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wo awọn nkan ti orilẹ-ede miran fẹ ṣe

Lati ìgbà ti ọrọ oronavirus ti bẹrẹ jakejado agbaye, ni awọn ijọba orilẹ-ede kọọkan ti n wa nkan ti yoo mu aye dẹrun fun awọn ara ilu wọn.

Iroyin loriṣiriṣi lo ti jade lori ọna ti awọn ijọba n gba mu aye rọrun fun awọn ara ilu, paapaa julọ, awon orilẹ-ede ti wọn ti paṣẹ pe ki awọn eniyan o ma jade mọ.

Awon ọmọ Naijiria naa ti wa n beere pe, kini ijọba Naijiria fẹ ẹ se fun ara ilu lati mu aye dẹrun fun wọn, nitori bi ọrọ se n lọ, o dabi ẹni pe ọrọ aje ko ni pẹ dẹnukọlẹ ni Naijiria naa.

Ọjọ Iṣẹgun ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu kede pe ki wọn o gbe gbogbo ọja ti, ki o si ku awọn to n ta nkan ti ẹnu n jẹ nikan ati awọn to n ta ogun.

Igbesẹ ti awọn kan gbe ree:

China

Ni kete ti ọrọ Coronavirus bẹ silẹ ni China, iroyin fi yeni pe ijọba orilẹ-ede naa bẹẹrẹ si ni kọ ile iwosan Leishenshan lati moju to aarun naa, ti wọn si kọ ọ tan laarin ọjọ mẹwaa.

Bakan naa ni wọn se akojọpọ awọn dokita jadejado China lati lọ ṣe iranlọwọ fun awon to ni aarun naa ni China.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ko sẹni ti ko le kọlu lasiko yii

America

Ni ilẹ America, bi aisan naa se n tan kalẹ l'ojoojumọ, ni ohun elo ti wọn nilo ko to fun ayẹwo ti o yẹ ki wọn se.

Bakan naa ni ile asofin pe alabojuto eto ilera wọn pe ki o paṣẹ ki gbogbo eniyan to ba fi ami aarun naa han ma a lọ si ile iwosan ti wọn ti ya sọtọ ni ọfẹ lati fun ayẹwo.

Ipinlẹ Texas tilẹ gbe ijọba apapọ lọ si ile ẹjọ nitori ede aiyede rẹ lori bi awọn eniyan yoo ṣe maa ṣe igbele ti ijoba pa laṣẹ, paapaa julọ ko si awọn elo idaabo bo ara ẹni mọ lawọn ile itaja.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini Yoruba n pe ni "pen"?

Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Doanld Trump fọwọ si iwe pe ki wọn o gbe ọgọrun un Dọla jade fun rira awọn ohun eelo ayẹwo Coronavirus;

O tun gba lati san owo igbele fun awọn eniyan ati owo osu isinmi sile.

Bakan naa ni owo yii yoo wulo fun ọpọlọpọ awọn ọmọ ilẹ America ti ko niṣẹ lọwọ, ọpọ awọn eniyan ni wọn wọn sọ pe awọn ko tii ri ko wa si imuṣẹ.

Canada

Ni orilẹ-ede Canada, ijọba kede lati igba ti Covid-19 ti bẹrẹ pe awọn yoo ma fi ọọdunrun dọla kun owo ọmọ kọọkan yatọ si iye ti wọn n san fun obi tẹlẹ.

Apapọ owo ti wọn yoo maa gba nisinyi yoo maa to ẹẹdẹgbẹta dọla ati aabọ lori ọrọ Coronavirus.

Bakan naa wọn sọ pe ti o ba di oṣu kejila, wọn yoo maa ṣe idapada lori owo ori, eyi yoo si maa jẹyọ ninu ọja rira wọn ati awọn eto ijọba ti wọn gba.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Ni Canada bakan naa, ijọba sọ pe awọn yoo maa moju to ẹnikẹni ti o ba ko Coronavirus ni kiakia, awọn yoo si ṣe iranlọwọ lati ba wọn wa ọna to rọrun ti wọn yoo gba san owo ile wọn.

Awon ti ko niṣẹ lọwọ, awọn to ni aarun Coronavirus tabi obi to duro silẹ lati tọju ọmọ to ni aarun naa yoo jẹ anfaani owo to to ẹgbẹẹrun meji Dọla fun Osu mẹrin titi ti nkan yoo fi pada sipo fun wọn.

Nigeria

Ọpọ ọmọ Naijiria naa lo n woye pe awọn nkan to n waye ni awọn orilẹ-ede to ti goke agba yii yẹ ki o ṣẹlẹ ni Naijiria naa.

Laipẹ yii, awọn kan tilẹ n gbe ayederu iroyin kan ka pe, ijọba fẹ ẹ san ẹgbẹrun mẹjọ aabọ fun ọmọ Naijiria kọọkan nitori coronavirus, eyi ti ko si ri bẹ ẹ.

Awọn miran tilẹ sọ pe, Naijiria naa ti se tirẹ, bi o se yọ ogun Naira kuro ninu owo epo betiro.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn fíìmì òde òní ń kọ́mọ lólè àti ọ̀pọ̀ ìwà burúkú

Ibeere to wa gba igboro kan bayi ni pe, "kini ijọba yoo se fun awọn ọmọ Naijiria lasiko itankalẹ aarun coronavirus yii?"

Bakan naa ni iwadii wa fihan pe irọ ni iroyin lẹta kan to gbode pe aarẹ Uganda paṣẹ pe ki awon onile ma beere owo ile lọwọ awọn ayalegbe fun oṣu mẹta.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNikesuliat: Ọ̀dọ́mọdébìnrin akéwì tó n fi ẹ̀ṣà kìlọ̀ ìwá lásìkò yìí