Coronavirus in Nigeria: Ǹjẹ́ ààrùn olówó ni coronavirus bí?

Coronavirus in Nigeria: Ǹjẹ́ ààrùn olówó ni coronavirus bí?

Oriṣiiriṣii nnkan lawọn eeyan m sọ nipa aarun coronavirus to n ṣọṣẹ kaakiri gbagbo agbaye bayii.

Awọn kan gbagbọ tẹlẹ pe awọn oyinbo alawọ funfun nikan ni aarun n mu wi pe kii mu awọn alawọdudu ilẹ Afirika.

Awọn miiran tiẹ sọ pe ohun elo imọ ẹrọ ibaraẹnisọrọ ti wọn n pe ni 5G lo n ṣokunfa aarun covid-19.

Loju awọn mii, aarun olowo ni coronavirus jẹ, kii mu talika.

BBC Yoruba ṣe alaye lẹkunrẹrẹ lori ọrọ yii.