Coronavirus: Ìwádìí ń lọ láti fi ẹ̀jẹ̀ àwọn tó ti jajabọ lọ́wọ́ Coronavirus ṣe ìwòsàn fáwọn alárùn míràn

Apo iko ẹjẹ si

Ìjọba ilẹ̀ United Kingdom (UK) tí ń palẹ mọ láti lo ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn ti orí kò yọ lọ́wọ́ àrùn Coronavirus fi ṣe ìwòsàn fún àwọn èèyàn ti àrùn náà ń bá fínra lọ́wọ́ lọ́wọ́.

Èyí sì lo mu kí ajọ eleto ìlera lórílẹ̀-èdè naa maa rọ àwọn èèyàn kan tó ti jajabọ lọ́wọ́ àrùn Coronavirus láti wá fi ẹ̀jẹ̀ wọn silẹ, kí wọn le e dan ẹ̀jẹ̀ náà wò.

Bẹẹ bá sì gbàgbé, irufẹ ìgbésẹ yìí náà tí ń lọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde sì kéde laipẹ yìí pé, òun ti setan láti fi ẹ̀jẹ̀ òun silẹ fún ìwádìí to yẹ.

Irufẹ iwadii yii wa láti fi ṣe itọju àwọn èèyàn tó ń ṣe àìsàn Coronavirus lọ́wọ́ lọ́wọ́.Ìrètí àwọn onímọ̀ ìlera lórí igbesẹ yìí ni pé, àwọn èròjà tó ń gbógun ti àìsàn nínú agọ ara àwọn èèyàn tórí tí kò yọ lọ́wọ́ àrùn Covid-19 yóò seranwọ láti pá kòkòrò àrùn náà rún lára àwọn èèyàn miran.

Àkọlé fídíò,

Coronavirus update: Akọrin tàkasúfé, Tommy Kuti tó ń forin ṣèkìlọ̀ COVID-19 lágbáyé

Kò tán síbẹ̀, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà náà tí ń gbé irufẹ ìgbésẹ yìí, tó sì ti ń ṣe ayẹwo ẹ̀jẹ̀ àwọn alárùn Coronavirus làwọn ilé ìwòsàn to to ẹẹdẹgbẹjọ.

Tí èèyàn bá ní àrùn Covid-19, ajẹsara to wá lára wọn yóò pèsè àwọn èròjà tó ń gbógun ti àrùn, tí yóò sì kọjú oro sì kòkòrò àrùn Coronavirus.

Láti ìgbà degba sì ni àwọn ọlọ́pàá ara yìí máa ń dàgbà, tí wọn yóò sì farahàn nínú èròjà Plasma, tíì ṣe ẹ̀jẹ̀ tó ń ṣàn nínú agọ ara

Àjọ eleto ìlera tí wá ń tọ àwọn èèyàn tó jajabọ lọ́wọ́ àrùn Coronavirus lọ, láti mọ bóyá èròjà Plasma tó wà nínú ẹ̀jẹ̀ wọn ṣe é fún àwọn aláìsàn miran tó lugbadi àrùn Covid-19.

Àkọlé fídíò,

Irọ́ ńlá ni pé ewé dongoyaro le wo ààrùn coronovirus

Atẹjade kan tí àjọ eleto ìlera náà fisita ni "ẹ̀jẹ̀ náà ni àwọn yóò lo ni ìbẹ̀rẹ̀ láti dán-án wo, bóyá yóò lè wo àrùn Covid-19 san".

"Tí wọ́n bá fọwọ́ sì tàn, ìwádìí ẹ̀jẹ̀ náà yóò ṣèwádìí bóyá gbigba ẹ̀jẹ̀ ọhun yóò mú agbega bá ìyára kánkán àwọn aláìsàn náà, láti rí ìwòsàn àti ìwàláàyè wọn".