Tope Alabi: Mo ti tọrọ aṣọ àti yẹtí etí rí, kí n tó leè ṣe àwo orin

Tope alabi

Oríṣun àwòrán, Tope alabi

Ilumọọka olórin ẹ̀mí lóbìnrin nnì, Tope Alabi tí ṣàlàyé pé, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹpẹ tí òun ti ń kọrin ẹ̀mí ni òun ti ń lo yẹtí eti, tí òun sì ń wọ ṣòkòtò pẹ̀lú, èyí tó lòdì sí èrò àwọn èèyàn kan tó ní òun kii lo yẹtí tẹ́lẹ̀.

Tope, ẹni tó sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń kopa lórí eto BBC Yoruba tún fikùn pé, òun kii ṣe adekodere, òun máa ń lọ ẹsọ etí, àmọ́ nígbà miran ó leè jẹ pe wọn ya òun ni.

Tope ni "Mo ti tọrọ aṣọ àti yẹtí rí nígbà kan láti fi yà fídíò orin mi, àwọn èèyàn kan sì wà tó jẹ́ pé, isẹ wọn ní lati maa tàbùkù mi nítorí ìbẹ̀rẹ̀ mi, àmọ́ mo fi ìdájọ́ wọn si ọwọ Ọlọ́run."

Àkọlé fídíò,

Bí mo ṣe rí ọ̀pọ̀ Mílíọ̀nù Nàírà tí mo sì dáà padà fún Ọlọ́pàá lọ́dún 1971 àmọ́ ǹkan t'íjọba sọ rèé - Baba Shonubi

Nígbà tó ń ṣe afiwe orin ẹ̀mí lásìkò yìí sí ìgbà tó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ, Tope Alabi ni àwọn tó ń kọrin ẹ̀mí kò pọ nígbà tí òun bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ yàtọ̀ sí bí àwọn olórin ẹ̀mí ṣe pọ ni asiko yii.

"Ìbáwí wá lásìkò tí àwa bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ, tí a sì ń gbà ìbáwí àmọ́ ni asiko yii, ọ̀pọ̀ olórin lo ń kọ ẹyin sì ìbáwí."

Bákan náà lo fikùn pé, òun ni ile kan ti òun fẹ́ fi ṣe ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn tó bá nifẹ láti kọ orin àti bí wọn ṣe leè dàgbà nínú ẹ̀mí.

Oríṣun àwòrán, Tope alabi

Lórí igbele àrùn Coronavirus, Tope ni ori ayélujára ni òun ti ń ṣe ipagọ ìyìn, tí òun sì tún rí ààyè fi ara balẹ gba àdúrà sì Ọlọ́run, ti oun si tún ráyè sinmi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé asiko yii ko mú owó wá.

"Mo tún ń ṣe ère idaraya lásìkò yìí, a to èèyàn méjìdínlógún nínú ilé mi, a jọ n yín Ọlọ́run, gba àdúrà, tá sì tún jọ ń ṣiṣẹ nínú ilé, àmọ́ kò mọ mi lára láti máa sun oorun ọ̀sán, mo kan ń tiraka láti ṣeé ni"

O wa rọ àwọn olólùfẹ́ rẹ láti jókòó sile nítorí àrùn . Coronavirus, pẹlu àfikún pé, ki wọn maa lo ọ̀sẹ̀ ifọwọ àti aṣọ ibomu, tí wọn ba jáde nínú ilé.

Àkọlé fídíò,

Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó

Oríṣun àwòrán, Tope alabi

O tún wa gba àwọn ọdọ tó nifẹ láti máa kọrin ẹ̀mí nímọ̀ràn pé, isẹ orin kíkọ yóò

rọrùn fún wọn tó bá wù Ọlọ́run fún onitohun láti kọrin, àmọ́ ó fikùn pé, orin ẹ̀mí kíkọ kii se isẹ ti èèyàn leè ṣe ayojuran si.

Ó ní onítọ̀hún gbọdọ sún mọ́ Ọlọ́run dáadáa, kí àjọṣepọ̀ rẹ pẹlu Ọlọ́run sì dán mọran.

Ilumooka akọrin ẹ̀mí náà tún ni ọdọ olóògbé Alade Aromire ni òun ti bẹ̀rẹ̀ si ni kópa nínú eré tíátà, kii sì ṣe Yemi Ayedun lọ jẹ oga òun, gẹgẹ bí èrò àwọn ènìyàn kan.

Tope fikùn pé òun kò ṣe ère tíátà tí gbogbo-gbòò mọ lásìkò yìí, àmọ́ òun ń ṣe ère tíátà ti ẹ̀mí, tó sì tun fikún pé, òun ń kọ orin fún àwọn Òṣeré tíátà to bá bẹ òun.

Oríṣun àwòrán, TOPE ALABI

O ṣàlàyé pé ó ti pé ọdún mẹrindinlọgbọn tí òun ti ń kọ orin ẹ̀mí, tí òun sì ti gbé àwo orin bíi mẹ́rìnlá jáde.

Nígbà tó ń ṣàlàyé ọ̀pọ̀ ipenija tó ti dojú kọ, Tope Alabi ni onírúurú irọ tí kò ní ẹsẹ nílẹ, ni àwọn èèyàn máa ń ṣàdédé pá mọ òun bíi kí wọn ní òun wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n torí gbígbé oogun oloro tàbí pé, òun àti ọkọ̀

òun ti pínyà, tó fi dé orí pé àwọn ènìyàn kii fẹ́ san owó láti gbọ orin ìyìn nínú gbọ̀ngàn.

Tope tún sọ síwájú pé "bí àwọn èèyàn ṣe sọ̀rọ̀ mi ni aidaa lórí ijo tí mo jo lásìkò ìsìnkú bàbá mi, dùn mi gidigidi àmọ́ ó dà mí lójú pé, ijo náà jẹ ìtẹ́wọ́gbà lọdọ Ọlọ́run ló ṣe mú awuyewuye lọ́wọ́."

"Kí ni ijo ayé nínú ijo tí mo jo táwọn èèyàn fi ń pariwo, bẹ́ẹ̀ ni n kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wọ ṣòkòtò, kí wa lo jẹ́ nkan tuntun nínú ohun tí mo ṣe, ṣùgbọ́n mo bẹ gbogbo wọn, kí wọn má bínú si mi"

Nínú ìròyìn míràn bíi rẹ̀: Orúkọ Abiku ni Okunnu tí mo ń jẹ nínú eré, inú orin Barrister ni mo sì ti ri - Wale Akorede

Oríṣun àwòrán, Wale Akorede

Àkọlé àwòrán,

Orúkọ Abiku ni Okunnu tí mo ń jẹ nínú eré, inú orin Barrister ni mo sì ti ri - Wale Akorede

Gbajugbaja osere tíátà, Adewale Akorede, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ si Okunnu, tí sàlàyé pé lásìkò igbele Covid-19 yìí, àwọn amuludun tí ń gba onírúurú ọna lórí ayélujára láti mú inú àwọn olólùfẹ́ wọn dùn.Lásìkò to ń kopa lórí eto kan ni ìkànnì BBC Yoruba, to ń jẹ 'Sọ tiẹ̀', Akorede ni oun ti gbé eto kan kalẹ lórí YouTube láti dá àwọn èèyàn laraya, kọ wọn ní ẹ̀kọ́ àti gba wọn nímọ̀ràn, èyí tí to pé àkòrí rẹ ni 'Ààbọ̀ ọ̀rọ̀'.Okunnu, nígbà tó ń ṣàlàyé bo se n ló àkókò igbele yìí ni, òun ni àǹfààní láti kọ àwọn ere tuntun, tí òun sì ṣe àtúnṣe sì àwọn ere tí òun ti kọ tẹ́lẹ̀.

Oríṣun àwòrán, okunu

Àkọlé àwòrán,

Orúkọ Abiku ni Okunnu tí mo ń jẹ nínú eré, inú orin Barrister ni mo sì ti ri - Wale Akorede

Àkọlé fídíò,

Àrìnfẹsẹ̀sí - Ìbéèrè ni a bèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn, ika òṣì ni wọ́n ń ta dànù

Akorede ni O yẹ káwọn osere lo àkókò yìí dáadáa, nítorí ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò ṣe oriire lásìkò yìí, kò sì yẹ ká fi ṣòfò. Ó ní o yẹ ká ṣe àtúnṣe sì àwọn ohun tó jẹ́ kúdíẹ̀-kúdíẹ̀ láti ẹyin wá."Mo rọ àwọn olólùfẹ́ mi láti ṣe sùúrù lasiko yìí, ẹ jẹ ká bá ara wa sọ̀rọ̀ nínú ìdílé, ká sì ṣe àtúnṣe sì àwọn ohun tó jẹ́ kudiẹ-kudiẹ láàrin wá lákòókò igbele yìí" Nígbà tó ń ṣàlàyé bo ṣe bẹ̀rẹ̀ ère tíátà, Okunnu ni Ọlọ́run ló kọọ pé òun yóò ṣe ere tíátà. Ó ní òun kò sì leè sọ ọpọ ohun tí ojú òun ti rí, kí òun tó já ojú ọ̀nà

Okunnu ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti kọkọ sina, kò tó jánà, tí yóò sì ti koko rìn àwọn irin kan, kí Ọlọ́run tó wà fi ọna hán-an. "Ilé ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ ni mo ti kọkọ bẹ̀rẹ̀ ere ṣíṣe, kò tó wà di pé mo bẹ̀rẹ̀ si ni rí owó ni ìdí rẹ lọ́dún 1984. Nígbà tó yá, kò sì owó fún mi láti jẹun, mo wa lọ gbé ní orílẹ̀ èdè Saudi Arabia fún ọdún mẹ́tàlá.

Má wá sí Nàìjíríà láti ṣe ère orí itage lákòókò naa, má tún kó ọjà wá láti tá nile, orí kò si ní òun yoo bá ọrùn dúró nígbà náà. Àmọ́ ìfẹ́ tí mo ní sì iṣẹ́ tíátà lo mú kí n padà sì ìdí ise naa."Lórí ìdí tó fi ń jẹ Okunnu, ó ṣàlàyé pé orí bíbá àwọn èèyàn kọ ìtàn ni òun ti bẹ̀rẹ̀ isẹ tíátà, kí oun tó máa kopa ninu ere, 'Isẹ Imọlẹ ' sì ni ère tòun kọ́kọ́ ṣe síta.O fikùn pé, Alhaji Kazeem Afolayan, tíì ṣe olùdarí ileesẹ asesinima kan lo gba òun níyànjú, láti máa ṣe awada nínú eré tíátà, èyí to wá di ohun tí ayé mọ òun mọ báyìí.

"Inú sinima 'Iwọkuwọ' ni mo ti ń jẹ Okunnu, àmọ́ inu sinima 'Afúnrúgbìn' si ní Okunnu tí wá jáde dáadáa. Inú àwo orin Fuji Barrister sì ni mo ti mú orúkọ náà síta, ìtumọ̀ rẹ sì ni Okùn sọnù, tíì ṣe orúkọ abiku.Okunnu ṣàlàyé pé, ara ìyá òun ni òun ti mú ẹ̀bùn awada sise. Ó ní Ọlọ́run fi ẹ̀bùn awada sise pamọ sì ara ìyá òun, àmọ́ kò fi ṣe iṣẹ́ ṣe, kí Ọlọ́run tó wà gbé ẹ̀bùn náà jáde lára òun. "Mo máa ń ronú jinlẹ lati se òun tuntun tí ẹnikan kankan kò ṣe rí, ìdí sì nìyí tí mo fi ṣe sinima tó jẹ́ èmi nìkan ni lo jẹ ọkùnrin ní odidi ìlú kan.

Oríṣun àwòrán, Wale

Àkọlé àwòrán,

Orúkọ Abiku ni Okunnu tí mo ń jẹ nínú eré, inú orin Barrister ni mo sì ti ri - Wale Akorede

O ni Ọlọ́run nìkan ló máa ń fún oun ní iwuri àti ìtọ́ni láti kọ ìtàn fún èrè ṣíṣe, bẹ́ẹ̀ sì ni òun nìkan lo máa ń fún ní ní ọgbọ́n àti làákàyè, ìdí sì rèé tí òun ṣe máa ń ṣe àdúrà pé kí Ọlọ́run dárí oun, àti pé, oun ni lọ́kàn pé oun fẹ́ kọ ìtàn, ó kàn máa ń wà ní. "O dara ká máa jíròrò, ká sì dá ọpọlọ láàmú, ká tó ṣe eré. Ó gbọ́dọ̀ gba wa ni akoko nítorí ìtàn kíkọ dá bí ipilẹ ilé ni. Tí ó bá yíwọ, ère náà kò leè dára, àwọn tí yóò sì kopa ninu rẹ, ara wọn kò leè dá saka láti ṣeé." Okunnu ni ọmọ bibi ìlú Ogbomoso ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni oun, tó sì ni gbogbo olórin ni òun féràn àmọ́ orin Fuji olóògbé Sikiru Ayinde Barrister ni òun máa ń gbọ́ julọ. O wa sísọ lójú rẹ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ pé, òun ń pò ère kan pọ lọ́wọ́, tí àkọlé rẹ ń jé 'Alẹ́ lagba', èyí tí yóò kọ wọn ní ẹ̀kọ́ láti múra fún ọjọ́ alẹ wọn lati ìgbà òwúrọ̀, ó ní kí wọ́n má sì lo òwúrọ̀ wọn jatijati, èyí tó leè kò bá ọjọ́ alẹ wọn.Okunnu wa tún gba àwọn aráàlú nímọ̀ràn láti máa tẹle asẹ ìjọba, pàápàá gẹ́gẹ́ bo se kan amojuto itankalẹ àrùn Coronavirus àti igbele, nítorí àlàáfíà wà àti ti gbogbo ìlú lọ ja ju.