Oshodi Tapa: ìgbésí ayé Oshodi, ọmọ Tápà léǹpe tó di akọni ní ìlú Eko rèé

Osodi

Oríṣun àwòrán, others

Ilu Eko ni iwọ oorun guusu Naijiria jẹ ilu nla, ilu olowo ati ọlọla, ilu to gbajumọ, ti ọpọ eeyan si n gbe inu rẹ ṣe oriire.

Lara awọn adugbo to gbajumọ nilu Eko si ni Oshodi, bii eeyan ba si de Eko, lai mọ adugbo Oshodi, onitọhun ko mọ Eko rara.

Oshodi yii kii si ṣe orukọ arosọ lasan, tí wọn kan fi sọ adugbo kan; amọ, o jẹ orukọ akinkanju ẹda kan to ṣe gudu-gudu meje ati ya ya mẹfa si idagbasoke ilu Eko,

Idi si ree to fi yẹ ka mọ nipa akinkanju ọkunrin naa.

Gẹgẹ ba a ṣe ka a lori awọn oju opo itakun agbaye, orukọ akọni ọkunrin naa ni Balogun Landuji Oshodi Tapa, bi itan igbe aye rẹ si ṣe lọ ree.

Àkọlé fídíò,

'Èmi gan máa ń béèrè lọ́wọ́ ara mi pé ta ni Wole Soyinka gangan'

Itan igbe aye Oshodi Tapa:Balogun Landuji Oshodi Tapa jẹ ọmọ ọba nilu Bida to wa nipinlẹ Niger bayii, eyi to fidi rẹ mulẹ pe ẹya Tapa ni, lọdun 1800 si lo dele aye.

Ọmọ ọdun mẹfa ni Oshodi wa, tí ogun abẹle fi ja nilu rẹ, eyi to mu ẹmi awọn obi rẹ lọ.

Ọna lati bọ lọwọ awọn to le mu u lẹru, lo mu ko sa kuro nilu Bida, wa silu Eko lai naani pe ọjọ ori rẹ kere jọjọ.

Ibẹru pe ki wọn ma mu oun lẹru pada ni Eko, si lo gbee Oshodi lọ si aafin Ọba Eko, pe ọdọ ọba ni oun fẹ maa gbe.

Ọba Eshinlokun, tii ṣe baba Kosoko, lo wa lori itẹ lasiko ti Oshodi de silu Eko, ti oloye Fagbemi si muu lọ si aafin ọba lati fi ọrọ rẹ to ọba leti.

Ọba Eshinlokun ni ki wọn bi ifa leere lati mọ bi asiko alejo naa yoo tu ilu lara si abi bẹẹkọ, tí ifa si fọ ire nipa Oshodi.

Idi ree ti ọba Eshinlokun fi gba Oshodi Tapa sọdọ rẹ, to si fi ṣe alakoso eto aabo ni awọn abala kan ninu aafin rẹ, ti ọba si fi si abẹ amojuto Fagbemi. Oshodi Tapa ń dagba, ọkunrin de, to si di akikanju ati akọni pataki laarin ilu, bẹẹ lo sun mọ ọba Eshinlokun bii isan ọrun.

Nigba to ya, ọkan lara awọn oyinbo pọtugi to jẹ gbajugbaja onisowo nilu Eko, tii tun ṣe ọrẹ ọba Eshinlokun beere lọwọ ọba pe ko fun oun ni ọmọkunrin rẹ meji lati tẹle oun lọ si orilẹ-ede oun tii ṣe Portugal.

Oyinbo naa jẹjẹ pe oun yoo mu awọn ọmọ ọba naa pada, ti oun ba n bọ pada wa silu Eko sugbọn ọrọ naa ko mu ọkan ọba balẹ.

Ọba Eshinlokun wa pinnu pe, oun ko ni ko awọn ọmọkunrin oun meji silẹ, to si mu awọn ọmọkunrin meji to wa ni aafin rẹ, eyi-un Oshodi Tapa ati Dada Antonio silẹ fun oyinbo,

Oríṣun àwòrán, others

O ṣe eyi nitori ọmọ ọlọmọ la n ran nisẹ de toru-toru.

Ọba Eko ro pe oun n daabo bo awọn ọmọkunrin oun ni lọwọ iparun lai mọ pe anfaani nla ni oun fi n dun wọn, tori a kii ri Ẹfọn ta ni ẹẹmeji.

Oshodi ati Dada ba eebo lọ soke okun lootọ amọ ilẹ Amẹrika ni wọn lọ, tí wọn si pada de lẹyin ọpọlọpọ ọdun,

Lẹyin eyi ni awọn oyinbo si gba Oshodi Tapa si idi okoowo wọn nitori o ti mọ apade alude oko-owo naa loke okun.

Awọn oyinbo pọtugi n pin Oshodi ninu ere ti wọn ba jẹ ninu okowo wọn, eyi to sọ di olowo ati ọlọrọ nigboro Eko.

Oríṣun àwòrán, others

Bi Oshodi ṣe wa ni owo to yii, ko gbagbe ibẹrẹ rẹ, to si tun sun mọ ọba Eshinlokun tipẹ-tipẹ bii ti tẹlẹ, eyi to mu ki ọba fi ṣe akoso káà awọn olori.

Oun nikan si lo ni aṣẹ lati wọ kaa awọn ayaba ninu aafin bo ṣe wu u, to si ma n ṣe atunse to ba yẹ sibẹ loore koore.

Wọn ni ko si ẹni ti ko ni ku, ọba Eshinlokun waja, ti ọmọ rẹ, Idewu Ojulari si rọpo rẹ, amọ oun naa ko pẹ lori itẹ, to fi darapọ mọ awọn baba nla rẹ.

Àkọlé fídíò,

What causes coronavirus: Akeugbagold sọ àṣírí ohun ti àrùn coronavirus ń dá lárá f

Kosoko lo kan lati gun ori itẹ sugbọn ogun ati ọtẹ dìde sii, ti Oluwole si jọba lẹyin rẹ lọdun 1836 sugbọn digbi ni Oshodi wa lẹyin Kosoko, ko le de ori itẹ, ti ko si gbagbe ajọsepọ rẹ pẹlu baba Kosoko.

Kosoko ati Oshodi Tapa gbogun ti Ọba Oluwole, ti wọn si gba akoso isalẹ Eko, ogun naa gbona giri-giri; amọ, ọba Oluwole lo bori, tawọn mejeeji si sa kuro nilu Eko.

Ọba Oluwole waja nigba to ya amọ dipo ki wọn fi Kosoko ti oye naa tọ si jọba, Akitoye, tii ṣe aburo baba rẹ lo gori itẹ nitori aisi nilu Kosoko, eyi to mu ki wahala miran bẹ silẹ nilu Eko nigba ti Kosoko pada wọ ilu.

Akitoye ati Kosoko tun doju ija kọ ara wọn, ti Oshodi si wa lẹyin Kosoko digbi nitori ọmọ alaanu rẹ, iyẹn Ọba Eshinlokun, nii ṣe, ti aja rẹ ko si gbagbe oloore ẹkọ.

Lẹyin o rẹyin, Kosoko bori Akitoye, to si lee kuro lori oye lọdun 1845, to si jọba ilu Eko nigba ti Oshodi jẹ Balogun rẹ.

Amọ Akitoye ko sinmi, o bẹ awọn oyinbo lọwẹ lati gbogun ti Kosoko, ti wọn si le e kuro lori oye lọ silu Epe pẹlu Oshodi, ni ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun 1853.

Oríṣun àwòrán, oshodi

Akitoye naa waja lọjọ Keji oṣu kẹsan-an ọdun 1853, ti ọmọ rẹ, Dosumu si jẹ ọba lẹyin rẹ, amọ sibẹ-sibẹ, ilu Eko ko fararọ laisi nile Kosoko.

Ọpọ ipade alaafia lorisirisi lo waye lati jẹ ki ọba Kosoko pada silu Eko, sugbọn awọn oyinbo ko gba, wọn ni ki Oshodi nikan maa pada bọ wale, sugbọn o fi aake kọri lati ṣe bẹẹ, nitori ẹyẹle kii ba onile jẹ, ko di ọjọ ipọnju ko yẹri.

Àkọlé fídíò,

Coronavirus tips: Kìí ṣe gbogbo ìbòmù ló ń dá coronavirus dúró

Nigba to di ọdun 1862, wọn gba Kosoko laaye lati pada wale lẹyin to fọwọ si iwe adehun alaafia pẹlu gomina Eko, John Hawley Glover.

Gomina Glover ni inu rẹ dun si ipa ribiribi ti Oshodi ko si ilọsiwaju alaafia nilu Eko ati iriri rẹ ninu oselu, tó si maa n beere imọran lọwọ rẹ ko to ṣe ohunkohun.

Glover beere agbegbe Epetedo lọwọ idile Aromire fun Oshodi ati idile rẹ lati tẹdo si ni kete to de lati ilu Epe, to si di asoju gomina.

Aarin gbungbun Epetedo ni aafin Oshodi wa, ti wọn si pin agbegbe naa si agboole mọkanlelogun, lara wọn ni agboole Oshodi, Akinyemi, Ewumi ati Alagbede.

Gomina Glover tun fun Oshodi Tapa ni ami ẹyẹ lorisirisi fun aimọye ipa takuntakun to tun n ko si idagbasoke ilu Eko.

Nigba to jẹ pe ko si ẹni ti ko ni ku, Balogun Landuji Oshodi Tapa dagbere faye ni ọjọ Keji, oṣu Keje ọdun 1868 lẹyin ọdun mẹfa to pada de silu Eko lati Epe.

Oshodi Tapa fi ọpọ aya ati awọn ọmọ to to mẹrindinlaadọta sile aye lọ, ti wọn si sin oku rẹ si aarin gbungbun opopona Oshodi ni Epetedo nilu Eko, bẹẹ ni wọn ri ọwọn iranti soju saare rẹ titi di oni.

kọ ti itan igbe aye Oshodi Tapa kọ wa:

Ẹkọ akọkọ ni pe ki ọmọde tete mọ ohun to fẹ fi ile aye rẹ ṣe lai naani ọjọ ori rẹ abi ipo to wa.

A tun ri i kọ pe iku obi ọmọ ko ni ki ọmọ ma de ibi to fẹ de, eyi ko si yẹ ko jẹ awawi lati di ẹni pataki nile aye.

Ẹkọ miran ni pe ko yẹ ka maa fi ibi san oore fun alaanu wa ati ọmọ rẹ, boya loju aye rẹ ni abi lẹyin to ku.

O tun kọ wa pe ka maṣe pada lẹyin oloore wa ati iran rẹ nigba isoro.

Oríṣun àwòrán, Eko

Itan aye Oshodi Tapa tun kọ wa lati maṣe raga bo ọmọ tiwa, ka si ran ọmọ ọlọmọ níbi tó le.

A tun rii kọ pe, ka maa ri ibi ti a ba tẹdo si gẹgẹ bii ilu wa, ka si maa wa alaafia rẹ.

Lakotan, a kẹkọọ pe ka maa ṣe aanu fun awọn ajeji ni ayika wa, lai naani, ẹya, ẹṣin ati ede ti wọn n sọ nitori oore wa lara awọn naa.

Àkọlé fídíò,

Coronavirus symptoms in Nigeria: Pẹ̀lú èròjà olùgbèjà ara 'Antibodies'