School reopening: Ìmọ̀ràn márùn ùn láti ẹnu olùkọ́ni tó fakọyọ lágbàyé lórí bí a ti se lè kọ́ ọmọ nílé lásìkò ìséde

School

Oríṣun àwòrán, @MalaikaDRC

Lasiko tigbogbo agbaye n gbiyanju lati koju arun Covid-19 yi, ibeere nla kan to jọba lọkan ọpọ awọn obi ni igba tawọn ọmọ wọn yoo pada si ile ẹkọ.

Lọpọ awọn orile-eden ni Afrika, ko ti daju igba tawọn alasẹ yoo si ile ẹkọ pada.

Amọ sa ẹ ma foya, nitori pe ogbontarigi olukọni ọmọ ilẹ Kenya Peter Tabichi to gbẹbun miliọnu dọla kan gẹgẹ bi olukọni to fakọyọ julọ lagbaye ni awọn imọran kan gbogi fawọn obi.

Ẹ la asiko kalẹ f'ẹkọ kikọ:

Ọga Peter Tabichi sọ pe ohun ti a gbọdọ kọkọ se ni pe ki a kọ awọn ọmọ wa bi eeyan ti se n seto ara rẹ nile.

O ni ohun ti eyi tumọ si ni pe ki a la asiko kalẹ lati fi bẹrẹ ati pari isẹ lojoojumọ nile wa ki a si ri pe a fi tọkantọkan tẹle.

Bakan naa o ni ka fi aaye kalẹ fun awọn ọmọ lati sinmi ati sere nigba to ba to.

Oríṣun àwòrán, @Hamza_Africa

Fi isẹ ile kọ awọn ọmọ lẹkọ:

Nigba ti ile rẹ ti di aaye ikẹkọọ, ko si sise ko si aise ju ki o sọ ''eyikeyi aaye to ba ni ninu ile di ile ẹkọ.

Eeyan o si nilo lati kawe gboye ki o to le se eleyi lati fi kọ awọn ọmọ naa lẹkọ pataki''

O salaye pe ki ọrọ naa ba le wọ ọmọ rẹ lara daada, o ni lati jẹ ki isẹ to n kọ dabi akanse isẹ iyẹn tumọ si pe wa ni lati ma jẹ ki awọn ọmọ naa ma kopa ninu ohun to ba fẹ se.

O ni wọn le ba ọ dana, ba o fọsọ tabi ran asọ eleyi to ba ya.Bi wọn ba se eleyi, imọ ẹkọ eto ile,Home Economics, ni wọn n se yẹn.

Koda ẹ le jọ se isẹ ọna papọ, ki ẹ jijọ ma kọrin tabi lulu, eyi naa a ma jẹ ki wọn kẹkọ daada.

Ríi wi pe o fi ere idaraya kun un:

Tabichi sọ pe , "ere idaraya dara pupọ fawọn ọmọde."

Imọran rẹ ni pe o le wa okun ti wọn yoo fi se ere fakinfa laarin ara wọn tabi ki wọn ma fo kọja okun naa

Oríṣun àwòrán, @Nataana254

Tabi ki o si fi akoko yi kọ wọn bi wọn ti se le gun kẹkẹ

O tun sọ pe o le fi asiko yi sere daadaa pẹlu awọn ọmọ rẹ, yatọ si pe o jẹ ọna idaraya fun iwọ ati ọmọ rẹ, yoo tun mu ki irẹpọ wa laarin obi ati ọmọ rẹ.

Fi asiko ajakalẹ arun Covid 19 yi kọ ọmọ rẹ nipa ẹkọ ilera:

Asiko ajakalẹ yi ti mu anfaani nla wa lati salaye fawọn ọmọ rẹ ohun ta n pe ni kokoro aifojuri ati bi wọn ti se n rin kaakiri.

Kọ awọn ọmọ rẹ nipa bi ọwọ fifọ se le ko wọn yọ ninu ewu arun yi.

Tabichi tẹsiwaju pe , "Ranwọn lọwọ bi wọn ko se ni bẹru pupọ,sọ fun wọn pe kokoro yi ko ni wa titi lailai ati pe kii se gbogbo eeyan to ba ko arun naa ni yoo ku."

Nipari mọ wi pe o ti gbiyanju tirẹ gẹgẹ bi obi:

Tabachi ko akotan ọrọ rẹ pelu imọran pe ti ẹ ba pari ẹkọ kikọ tan, ẹ le gba adura, ki o si se agbeyẹwo nkan ti ba ri se loojọ ki ẹ si ni akọsilẹ rẹ.

O ni ''ti ilẹ ba ti su, ẹ jade ista lati lọ wo irawọ loju ọrun, ki ẹ si pada wọle lọ sun pẹlu igbagbọ pe o ti se iwọn to le se gẹgẹ bi obi''

Àkọlé fídíò,

Coronavirus survivor: Àntí Korona ni wọ́n n pè mí l'ádùúgbò láti ìgbà tí mo ti ní Covid-19