Mudasiru Obasa: Òṣìṣẹ́ tó tú àṣírí ilé asòfin rugi oyin

Mudasiru Obasa

Oríṣun àwòrán, Facebook/Musasiru Obasa

Laipẹ yii ni iroyin kan jade lori ayelujara, to si n fi ẹsun orisirisi kan olori ile asofin nipinlẹ Eko, Mudasiru Obasa.

Awọn ẹsun naa, to jẹ onikoko mẹrin naa lo ni nkan ṣe pẹlu iwa ajẹbanu ati jẹgudu-jẹra, eyi to n fa awuyewuye lori ayelujara.

Awọn koko ẹsun ti iwe iroyin itakun agbaye naa fi kan Obasa ree:

  • Ẹsun akọkọ ni pe olori ile ni apo asunwọn owo mẹrinlelọgọta ni banki, eyi to ni nọmba BVN kan ṣoṣo.
  • Ẹsun keji ni pe iyawo olori ile asofin nipinlẹ Eko naa n gba miliọnu mẹwa naira ni osoosu lati owo ile asofin naa.
  • Ẹsun kẹta ni pe Obasa lo miliọnu lọna ọtalenigba o din meji naira (N258m) lati fi tẹ iwe ipe sibi ayẹyẹ ifilọlẹ ijoko ile asofin kẹsan-an nipinlẹ Eko, eyi to jẹ olori ile fun.
  • Ẹsun kẹrin lo nii ṣe pẹlu bi olori ile asofin nipinlẹ Eko naa ṣe buwọlu ọgọrin miliọnu naira fun awọn iyawo awọn asofin ogún lati lọ ṣe idanilẹkọọ nilu Dubai.

Awọn ẹsun onikoko mẹrin yii si lo kan ile asofin nipinlẹ Eko lara, eyi to mu ki wọn gbe igbimọ oluwadii ẹlẹni mẹsan kan kalẹ, ti Asofin Victor Akande ko sodi.

Igbimọ oluwadii yii si lo ṣe iwadii olori ile ni ọjọ abamẹta to kọja, ti wọn si ti jabọ iwadii wọn bayii nipa awọn ẹsun mẹrẹẹrin naa.

Oríṣun àwòrán, others

Igbimọ oluwadii naa ni irọ to jinna si ootọ, ti ko si lẹsẹ nilẹ ni awọn ẹsun naa, ti wọn si dibo pe awọn ọmọ ile asofin nipinlẹ Eko si ni igbẹkẹle kikun ninu olori wọn naa.

Abọ iwadii ile asofin Eko lori ẹsun mẹrin ti wọn fi kan olori wọn:

  • Lori ẹsun akọkọ to sọ pe Obasa ni apo asunwọn owo mẹrinlelọgọta ni banki, igbimọ oluwadii naa ni irọ nla ni eyi nitori nọmba BVN ti wọn kọ kii ṣe ti Obasa, awọn Ileesẹ ti wọn si ni oun lo ni, kii ṣe tiẹ.

"Ninu apo asunwọn owo mẹrinla ti iroyin naa sọ pe Obasa lo ni i ni banki Zenith, mẹfa pere lo jẹ tiẹ, meji pere si lo n lo ninu wọn."

  • Lori ẹsun keji to ni iyawo Obasa n gba miliọnu mẹwa naira losoosu ninu owo ile, igbimọ oluwadii naa salaye pe ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun ni ọrọ naa.

Bakan naa si ni igbimọ oluwadii naa tun da awọn ẹsun mejeeji to ku nu, to si tun kede pe ki ile asofn naa ṣe iwadii bi awọn iwe asiri ile ṣe de ọwọ awọn akọroyin, ki wọn si fi iya jẹ osisẹ to ba jẹbi.

₦80m la fi rán ogún ìyàwó asòfin lọ Dubai - Obasa

Olori ile asofin nipinlẹ Eko, Mudasiru Obasa, ti salaye niwaju igbimọ oluwadii lori bi ile asofin naa ṣe na awọn owo kan.

Obasa lo yọju niwaju igbimọ oluwadii naa lọjọ Abamẹta, lati dahun awọn ẹsun ajẹbanu ti wọn fi kan an ninu iroyin ori ayelujara kan.

Ileesẹ akoroyinjọ ilẹ wa, NAN lo kede pe oju opo iroyin kan lori ayelujara lo kede pe wọn ti sawari apo asunwọn owo ni banki mẹrinlelọgọta to so mọ nọmba idamọ BVN Obasa.

Nigba to n fesi lori ẹsun naa, olori ile ni irọ to jinna si ootọ lawọn ẹsun naa, nitori ile asofin fi ọwọ si awọn ọkọ ti wọn ra fawọn asofin ati inawo miran.

"Irọ pọnbele ni pe iyawo mi n gba miliọnu mẹwa ni osoosu lati inu owo ile asofin, ẹni to ba si ni ẹri to daju, ko mu wa."

Nigba to n salaye bi wọn ṣe na miliọnu lọna ọgọrin naira, Obasa ni ogun iyawo awọn asofin lo na owo ọhun lọ si ilu Dubai fun idanilekọọ kan.

Oríṣun àwòrán, others

" A fun ọkọọkan iyawo asofin to kopa ninu idanilekọọ naa ni miliọnu mẹrin naira, eyi to wa fun owo baalu, gbigba ile ìtura, ounjẹ ati irinajo laarin ilu Dubai"

Bakan naa tun ni Obasa sẹ lori ẹsun kan to ni o na miliọnu mẹtalelaadọta lori irinajo kan to ṣe lọ silẹ Amẹrika pẹlu ale rẹ kan.

Àkọlé fídíò,

Báyìí ni ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọmọnìyàn ṣe pè fún ìdájọ́ ikú fún àwọn afipábánilòpọ̀