Your Poo and You: Ṣé o mọ̀ pé ìgbẹ́ rẹ leè sọ nípa ìlera rẹ?

Aworan igbẹ

Ohun ti awọn akọṣẹmọṣẹ sọ nipa boo ṣe le mọ ipo ilera rẹ latara awọ ati bi igbẹ rẹ ṣe le tabi rọ si.

Awọn kan kii fẹ ki eeyan mọ pe awọn maa n yagbẹ; sibẹ, pataki ni igbẹ yiya nigbesi aye wa tori o pọ ohun ti ko dara kuro lara.

Ẹwẹ, Dokita Chinedu ti fasiti Nsukka ni lilọ ile igbọnsẹ ṣe koko lati fun lẹẹkan tabi ẹẹmeji loojọ. O ni ẹẹkan lọsẹ lee fa aisan ọlọjọ pipẹ.

Ki ni igbẹ tabi imí tumọ si?

Orukọ mii fun igbẹ ni imi, eyi to tumọ si awọn nkan ti ko daa lara to fi mọ ounjẹ, kokoro atawọn nkan mii ti ko sẹrẹ lara ti ko si wulo fun ara eyi ti o n gba idi igbẹ jade sita.

Iwe iroyin atigbadegba kan, Healthline ni oorun ati bi igbẹ onikaluku ṣe ri yatọ sira wọn ni eyi to si lee sọ ọpọlọpọ nkan nipa onikaluku.

Ẹẹmelo lo yẹ ki n ṣe igbọnsẹ loojọ?

Chinedum Aranato sọ pe ẹnikẹni to ba n jẹun lojoojumọ gbudọ ya idọti jade lojoojumọ.

Oríṣun àwòrán, Chinedu Aranotu

Ko ni akoko kan ni pato ṣugbọn iwe iroyin Healthline sọ pe ẹẹmẹta loojọ ko póju.

Bakan naa, awọn akọṣẹmọ ni igbẹ aarọ dara lai tii wẹ tabi jẹun.

Iwadii ti Ileeṣẹ iwe iroyin atigba-de-igba lori ayelujara sọ pe ida aadọta lo n ṣe igbọnsẹ loojọ, nigba ti ida mejidinlọgbọn eeyan ninu ogorun un n lọ lẹẹmeji ati ida marun abọ ni ẹẹkan lọsẹ.

Ẹwẹ, ida o le ni ida mẹtalelọgọta to n lọ ile igbọnsẹ laarọ, ida mejielogun lọsan ati o fẹrẹẹ to ida mẹta lalaalẹ.

Awọn onimọ ilera ni bi Élẹda ṣe da ara ni lati tun ṣe igbọnsẹ lalẹ lasiko ti awọn eeyan ba n sun.

Tori naa lo ṣe jẹ wi pe aṣe eeyan bi ka gbọnsẹ bi a ba ti mu omi kọọbu kan tabi tii gbigbona.

Awọn ohun to n ṣokufa igbẹ rẹ ree:

Ounjẹ

Ounjẹ bii ẹwa tabi ewebẹ ati eso yoo jẹ ki igbẹ rẹ wa wọọrọwọ.

Mimu omi tabi ẹlẹrindodo naa maa n jẹ ki igbẹ rọ.

Ọjọ ori

Bi eeyan ṣe n dagba si irinkerindo inu maa n dinku, ifun lee fun pọ eyi to le maa fa idiwọ fun igbẹ lati kọja wọọrọwọ.

Ogun mii ti awọn agba n lo maa n ṣakoba fu igbẹ tabi itọ

Ere Idaraya

Gbigbe ara pekepeke fun idaraya maa n ran irinkerindo inu lọwọ.

Aisan

Aisan mii kii jẹ ki ounjẹ walẹ bii awọn aisan to ma n koba inu kikun.

Bayii ni bi igbẹ rẹ ṣe ri ṣe le sọ nipa ilera rẹ.Oriṣi mẹfa lo wa:

  • Igbẹ to ri bi okuta marble tumọ si pe inu kun. O maa n lefo lori omi. O tumọ si pe ẹni bẹẹ kii mu omi daadaa.
  • Igbẹ lile to pẹ ki eeyan to ya a tan maa n ṣe kọndọrọ bi kokoro tata n ṣafihan inu kikun diẹ.

O maa n lefo lori omi ninu awo igbọnsẹ o si le jẹ ki idi maa dun eeyan bi eeyan ba n ya iru rẹ ni gbogbo igba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

  • Igbẹ to gun to tun ni ila tẹẹrẹ tẹẹrẹ lo maa n nira lati ya, a lefo ori omi, bẹẹ domi sii ko tun ni lọ bọrọ.

Iru igbẹ yi n ṣafihan pe eeyan ko mu omi to inu iru ẹni bẹẹ si kun diẹ. Iru igbẹ yii ni eeyan maa n kan inu lati ya.

  • Eyi ni iru igbẹ to dara ju gẹgẹ bi awọn dokita ṣe sọ ọ.

O rọrun gan an lati ya, ko le ko si rọ ju, o gun o si ri wọọrọwọ lati ya.

Awọn dokita ni iru igbẹ yii lo dara ju.

O n ṣafihan ilera. Bẹẹ ba ya iru igbẹ yii tan, inu a si dun pẹsẹẹ, ọkan a tutu wẹẹ.

  • Igbẹ ti ko ni ẹya kankan ree, a kọkọ fọn ka a tun di pọ.

Igba mii a dapọ mọ omi, awọn ounjẹ ti ko sẹrẹ ninu lee jade pẹlu ẹ.

Eyi tumọ si pe ẹni bẹẹ ti ko nkan ninu ọna ti igbẹ n gba jade. Iru igbẹ yii lo maa n fọn jade tẹ o maa gbọ prẹẹẹrẹrẹ.

  • Iru igbẹ yii saaba maa n di pọ ku ku ku pẹlu ifarahan awọn ounjẹ ti ko sẹrẹ lara.

Oorun rẹ buru jai o si n ṣafihan pe ẹni bẹẹ ni aisan igbẹ gbuuru.

O maa n ri lọ si isalẹ inu awo igbọnsẹ ni.

Ẹwẹ, oriṣi aawọ igbẹ lo wa:

Eyi da lori irufẹ ounjẹ ti eeyan n jẹ o si n sọ nipa ipo ilera ẹni:

Aawọ ewe - Ko dara

Aawọ ewe to mọ lara - O dara

Aawọ erupẹ - O dara

Aawọ dudu - Tumọ si pe eeyan ti lo awọn oogun kan, tabi ẹjẹ dida nisalẹ ikun

Igbẹ funfun - Nilo amojuto dokita kia kia

Igbẹ pupa - Tumọ si pe o jẹ nkan ti awọ rẹ pupa, ẹjẹ dida ninu

Igbẹ to ni ọra.