Coronavirus Updates in Nigeria: Baba Obasanjọ kò ní àrùn Coronavirus

Baba Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Kehinde Akinyemi

Aarẹ orilẹ-ede Naijiria tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Obasanjo ko ni arun Coronavirus.

Agbẹnusọ fun Baba Obasanjọ, Kehinde Akinyemi lo fi lede bẹẹ ninu atẹjade ni Ọjọ Isinmi pe ayẹwo fihan pe ko ni arun Coronavirus.

Akinyemi ni Ọjọ Keje, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2020 ni baba ṣe ayẹwo fun arun Coronavirus ni ile rẹ to wa ni Olusegun Obasanjo Presidential Library (OOPL) Pent House residence, Okemosan, Abeokuta, ni ipinlẹ Ogun.

Wọn fikun wi pe dokita kan ti orukọ rẹ n jẹ Olukunle Oluwasemowo ti ileewosan Molecular Genetics Laboratory 54gene, nipinlẹ Eko lo ṣe ayẹwo naa.

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @Akinyemi

Abajade ayẹwo naa ni Ọjọ Isinmi, Ọjọ Kẹsan an, Oṣu Kẹjọ lo fi lede pe saka ni ara Baba da lọwọ arun Coronavirus.

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, @Akinyemi

Ileewosan to ṣe ayẹwo naa wa lara awọn ileeṣe ayẹwo fun arun Coronavirus to gba ontẹ ijọba ati ajọ to n risi ọrọ ajakalẹ arun ni Naijiria, NCDC.

Àkọlé fídíò,

Teach your children Yoruba: Wo àwọn òyìnbó tó ń kẹ́kọ̀ọ́ èdè Yorùbá ní Michigan, America