Police brutality: DPO ọlọ́pàá fi ọmọ odó lu èèyàn méjì pa, ó ṣe ẹnìkan lééṣe lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá

Ọmọdekunrin naa

Eeyan meji ti ku lẹyin ti ọlọpaa kan fi ọmọ odó lu ọdọ mẹta fun pe wọn ji adiyẹ.

Ẹnikẹta, Abdulwahab Bello, nikan ni o ye. Ṣugbọn, o fi ara gba ọgbẹ, ti egungun rẹ si kan lẹyin ti ọlọpaa naa lu wọn ni agọ ọlọpaa kan ni ipinlẹ Bauchi.

Abdulwahab sọ pe iṣẹ abanikọle ni oun n ṣe, ati pe awọn ọrẹ rẹ lo ko adiyẹ meje wa ba oun, ki oun to o tẹle wọn lọ si ọja lati ta a.

Lẹyin naa ni awọn ọlọpaa wa a ko wọn, pe awọn ji adiyẹ.

Abdulwahab tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe niṣe ni ọga ọlọpaa naa 'DPO' fi okun so oun, to si bẹrẹ si ni fi ọmọ odó lu oun ni ẹsẹ titi to fi kan.

Abdulwahab ni : "Lẹyin naa lo bọ si ẹsẹ keji, to si tun kan an, ko to o bọ si itan."

"Niṣe ni mo sin awọn ọrẹ mi lọ ta adiyẹ l'ọja, koda emi ni mo ya wọn ni owo ti wọn fi wọ ọkọ lọ."

Iyooku nkan ti Abduwahab sọ niyii: Lẹyin ti wọn ta adiyẹ tan ni wọn to o da owo mi pada. Ni kete ti wọn ko wa de agọ ọlọpaa, ni ọga wọn sọ pe ki gbogbo wa o dojubolẹ.

Ko pẹ ẹ lo ni ki awọn ọlọpaa o de wa ni ikọọkan, to si lọ ọ gbe ọmọ odó lati ma a fi lu wa.

Abdulwahab sọ fun BBC Hausa pe ọrẹ oun Ibrahim lo kọkọ lu aya, ati ẹyin titi to fi dakẹ.

"Mo kọkọ ro pe o daku ni, ṣugbọn nkan ti DPO naa n sọ ni pe "o sàn ko o ku nitori pe o ko wulo fun nkankan."

Lẹyin naa lo bọ sori ọrẹ mi keji, to si lu oun naa to fi ku."

O ni bo tilẹ jẹ pe ori ìso ni oun wa lasiko naa, gbogbo nkan to n sẹlẹ ni oun ri.

Lẹyin to lu gbogbo wa tan, o ni ij wọn o gbe ọkọ ayọkẹlẹ wa, oun lo si lọ ọ fi gbe oku Ibrahim lọ si ile wọn, to si sọ fun wọn pe adigunjale ni.

Ṣugbọn, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Bauchi sọ pe awọn ti n ṣe iwadii iṣẹlẹ naa.