Notorious Armed Robbers in Nigeria: Lára àwọn ọ̀daràn méje ni Mufu Oloosa Oko àti Godogodo

Awon afurasi adigunjale ti ọlọpaa se afihan wọn

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force/ Facebook

Ẹya Yoruba jẹ ẹya to maa n wa alaafia, to si korira iwa idaluru abi ọdaran ni gbogbo ọna.

Ọwọ yẹpẹrẹ si kọ ni Yoruba fi n mu agbega aṣa ati ise wa to da lori iwa ọmọluabi ati iwa rere ni awujọ.

Ṣugbọn awọn ẹda kan wa, ti wọn jẹ kanda ninu irẹsi fun iran Yoruba, nitori awọn iwa to tako ti ọmọluabi ti wọn n hu.

Ọpọ awọn eniyan naa si lo jẹ ogboju adigunjale ati adaluru, ti wọn ti da ẹmi ọpọlọpọ eeyan legbodo.

BBC Yoruba wa ṣe akojọpọ itan igbe aye awọn adigunjale ati ọdaran naa pẹlu iwa aidaa ti wọn hu ati ijiya ti ijọba fun wọn, eyi ti yoo kọ ọpọ ọdọ lọgbọn.

Awọn adigunjale ati ọdaran meje nilẹ Yoruba:

Abiodun Egunjobi - Godogodo:

Oríṣun àwòrán, others

Ogboju adigunjale ni Abiodun Egunjobi, ti ọpọ eeyan mọ si Godogodo nigba aye rẹ, to si gbajumọ fun isẹ to yan laayo naa.

Oju kan pere ni Godogodo ni, amọ o buru ju àpáàrà lọ, ti awọn kan si ni oun lo buru julọ laarin awọn ilumọọka adigunjale nilẹ Naijiria.

Ọmọ gọta ati atapata dìde ni Godogodo, to si pada di olori ikọ adigunjale ti kii gbọ ẹbẹ nilu Eko, afi ko mu ẹjẹ.

Odidi ọdun mẹrinla lo fi da Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko riba ribo, ki ọwọ palaba rẹ to segi ni ọjọ kinni osu kẹjọ ọdun 2013, ti wọn mu.

Dr Isola Oyenusi:

Laarin saa ọdun 1970s ni Ishola Oyenusi da omi alaafia ilẹ Yoruba ru, ti ọpọ ẹmi si ti ọwọ rẹ bọ.

Oyenusi ni adigunjale akọkọ nilẹ Naijiria, eyi to gbajumọ ni kete ta pari ogun abẹle tan.

Oríṣun àwòrán, Others

Ogboju adigunjale naa ni oogun abẹnu gọngọ pupọ, to si maa n rẹrin pade awọn ọlọpaa ati Sọja lasiko to ba n ṣíṣẹ ibi naa lọwọ.

Ọta ìbọn kii ran Oyenusi, bẹẹ lo maa n poora lasiko tawọn agbofinro ba fẹ mu, kii si lọ si ode idigunjale lai gba ẹmi eeyan, koda, ọdaju adigunjale pọnbele ni.

Gẹgẹ bi Oyenusi ti salaye obinrin afẹsọna oun to nilo owo nigba naa lo sun oun de idi ole jija.

Oríṣun àwòrán, @Daily times

Lẹyin o rẹyìn, ọwọ ofin tẹ ẹ, ti wọn si fi ẹyin rẹ ti agba ni Ọjọru, ọjọ kẹjọ oṣù Kẹsan-an ọdun 1971 ni eti okun nilu Eko.

Kayode Williams:

Ọmọ ileewe ni Kayode Williams wa nigba to dara pọ mọ ikọ Adigunjale Isola Oyenusi.

Oun nikan si lo sẹku lẹyin ti wọn pa Oyenusi tan, to si buru pupọ nitori ọwọ oun naa yara lati pa eeyan, ti ko si loju aanu.

Oríṣun àwòrán, others

Koda, ogbontagi adigunjale yii naa maa n gun ọmọ tuntun ninu odo lati fi ṣe oogun isọra, to si daamu agbofinro, ki ọwọ to tẹ ẹ.

Kayode Williams lọ ṣe ẹwọn ọdun mẹwa nigba ti ọwọ ijọba tẹ ẹ, ibẹ si lo ti ba Ọlọrun pade, to si di ọmọlẹyin Kristi.

Ojisẹ Ọlọrun naa wa laye lonii, to si n lo iriri rẹ bii adigunjale lati waasu fun awọn ọdaran iwoyi lati yipada kuro ninu isẹ ibi, bẹẹ lo tun n ṣe ayipada igbe aye awọn ẹlẹwọn.

Àkọlé fídíò,

'Oyenusi ló mú mi wọ ẹgbẹ́ adigunjalè kó tó di pé mo b'Ólúwa pàdé'

Shina Rambo:

Ọmọ bibi ilu Abeokuta ni ogbontagi adigunjale ti ọpọ eeyan mọ si Shina Rambo, aarin saa ọdun 1990s si lo da ilu risa risa.

Fun bii ọdun meje, ní Rambo fi n ja ọkọ ayọkẹlẹ gba laarin ilu, bo si ṣe n pa agbofinro, naa lo n pa araalu, ọdaju adigunjale pọnbele si ni.

Rambo gbẹkẹle oogun abẹnu gọngọ pupọ, o fi ọlẹ̀ inu alaboyun mẹtadinlọgbọn gun ọṣẹ fun isọra, to si fi ahọn eeyan ọgọrun mu ẹkọ.

Bo ṣe n gbe inu igi iroko oluwere, lo n sun si itẹ oku fun aabo, koda ẹbọra kan to ṣe bii obinrin, ti wọn n pe ni Alhaja, lo maa n wa ọkọ rẹ, ẹni ti ẹda kankan ko le e pa.

Oríṣun àwòrán, others

Ilu Cotonou nilẹ Benin ni Rambo fi ṣe ile, nibi ti aya ati ọmọ rẹ wa, to si maa n ko ẹrú ole to ba gba ni Naijiria lọ.

Lẹyin o rẹyin, Shina Rambo padanu ohun gbogbo to ṣíṣe fun, to fi mọ aya ati ọmọ mẹta, to si jọwọ ara rẹ silẹ fawọn ọlọpaa.

Ijọba sọ Shina Rambo si ẹwọn níbi toun naa ti ba Ọlọrun pade, to si ji ajihinrere to n waasu ihinrere Jesu kiri fawọn ọdaran lonii.

Isiaka Busari - Mighty Joe:

Isiaka Busari, ti wọn n pe ni Mighty Joe laarin awọn adigunjale, ni igbakeji Ishola Oyenusi ninu ikọ adigunjale wọn.

Oríṣun àwòrán, others

Oun si lo tẹsiwaju ninu iṣẹ ole jija lẹyin ti wọn pa Oyenusi tan.

Iṣẹ yii rọrun fun Mighty Joe pupọ nitori ọpọ awọn abọde Sọja to ṣẹṣẹ ja ogun abẹle tan lo ko mọra, ti wọn si n lo ohun ija oloro lati digun jale.

Ọka bimọ silẹ, o bi oro ni ọrọ Mighty Joe, to si buru ju Oyenusi to jẹ ọga rẹ lọ, igbakugba to ba wu lo n lọ soko ole, ẹmi eeyan ko si jọ loju.

Fun ọpọ ọdun lo fi da ilu Eko laamu laarin ọdun 1971 si 1973, ti agbegbe Mushin to n gbe ko si rọrun fun tonile talejo rara.

Oríṣun àwòrán, Others

Amọ ọwọ palaba oun naa papa segi nigba ti ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lẹyin to digun jale nile Itura kan, to si gba odidi naira mẹwaa lọwọ osisẹ ile itura naa, eyi tii ṣe owo nla nigba naa.

Nigba to wa ni ahamọ to n reti ọjọ ti wọn yoo fi ẹyin rẹ ti agba, Mighty Joe gba ẹṣin Islam to si di musulumi ododo.

Ẹyin agba leti okun nilu Eko ni ogboju apamọlẹkunjaye ẹda naa pari aye rẹ si, nigba táwọn ọmọ ologun rọ ojo ìbọn le lori.

Mufu Oloosa Oko:

Agbegbe Abebi, Idikan, Oloosa oko, Beere titi de Mokola, Oja Ọba nilu Ibadan ni Mufutau gbe dagba, to si ti ṣe ìpátá.

Ni ibẹrẹ aye rẹ, onirẹlẹ ẹda ni Mufutau, ti kii si gbe oju soke wo ẹnikẹni loju, koda, ko le sọrọ ẹnu ẹnu rẹ tan.

Ẹda tẹẹrẹ ti ko ni omi lara ni Mufu amọ tori adugbo to gbe dagba, ko si ẹda ti wọn jọ ja, tí Mufu ko ni fi ẹyin rẹ balẹ.

Olugbeja mẹkunnu ni Mufu, ẹnikẹni ti wọn ba yan jẹ ladugbo, tabi ti wọn gba iyawo rẹ lo maa n gbe wọn nija pẹlu awọn ọmọlẹyin rẹ.

Awakọ ero ni Mufutau, ilu Portharcourt si lo maa n fi ọkọ pijo 504 rẹ na titi wọ ọdun 1976, ti wahala de ba.

Àkọlé fídíò,

Olumo Rock: Òrìṣà Igùn lọba ọ̀pọ̀ òrìṣà tó wà lábẹ́ Olúmọ tó ń dáhùn àdúrà

Lasiko ti Mufu wa laye, ko si ẹni to mọ bii adigunjale, amọ ọmọ líle, tọ́ọ̀gì ati janduku to n da agbo ariya ru ni, ko si si olorin tí yoo fẹ ṣeré nilu Ibadan, ti ko ni kọkọ juba Mufu Oloosa Oko pẹlu owo nla.

Lọdun 1975, oun ati awọn ikọ rẹ na eeyan kan wọ inu mọsalasi, ibẹ ni Lemọmu ti ṣẹ epe fun pe ko ni si laarin awọn ni iwoyi ọdun to n bọ.

Nigba to di ọdun 1976, Mufu n dari bọ lati ilu Portharcourt to n na pẹlu awọn ikọ rẹ, wọn ya sile epo kan nilu Ondo.

Wọn ba owo tuulu lọwọ osisẹ ileepo naa to n ka lọwọ, ti wọn si fi ìbon gba owo naa lọwọ rẹ.

Ọwọ ọlọpaa papa tẹ Mufu, ti adajọ si ni ki wọn lọ yẹgi fun nilu Akure lọdun 1976.

Baddo ti Ikorodu:

Agbegbe Ikorodu nipinlẹ Eko ni ọkunrin kan tí ọpọ eeyan mọ si Baddo, ti sọṣẹ.

Badoo yii jẹ ọmọ líle, ọdaran ati adigunjale to doju kọ awọn obinrin ati ọmọde nikan.

Oríṣun àwòrán, Others

Fun ọdun pipẹ ni Badoo fi pa ọmọ lẹkun jaye, to si ni awọn omilẹgbẹ ọmọ lẹyin rẹ, ti wọn n da ẹmi eeyan legbodo.

Bi Badoo ati awọn ọmọlẹyin rẹ ba pa eeyan tan, wọn yoo fi aṣọ nu ẹjẹ rẹ, ti ọpọ eeyan si ni oogun owo ni wọn n fi ẹjẹ naa ṣe tabi ki wọn ta aṣọ ẹlẹjẹ naa fun Babalawo ti yoo lo o.

Lootọ ni awọn ọlọpaa maa n mu Badoo si atimọle lori awọn iwa ọdaran to n hu, amọ kii pẹ ki wọn to ju silẹ, ti yoo si tun tẹsiwaju pẹlu iwa ipaniyan ati idigunjale rẹ.

Nigba to ya, ti ara awọn eeyan Ikorodu ko gba iwa ọdaran yii mọ, wọn mu Badoo, ti wọn si dana sun titi to fi jade laye.

Ẹkọ ti itan awọn gbajumọ ọdaran meje yii kọ wa:

  • Ẹkọ akọkọ ni pe asegbe kankan ko si, asepamọ lo wa, ko si ba ṣe pẹ ninu iṣẹ ibi to, asiri yoo papa tu naa ni
  • Ẹkọ kejì ni pe iku ẹsin ni ọdaran maa n ku nitori naa, ko dara ka tẹsiwaju ninu iwa ọdaran, Yoruba ni to ba laya ko sika amọ to ba ri iku Gaa, ko sọ otitọ
  • Ẹkọ kẹta ni pe o dara ka tete fi igbe aye wa sin Ọlọrun ko to pẹ ju, ko si yẹ ka ti balẹ jẹ tan, ka to ma sin Ọlọrun.