N10m suit: ‌Agbẹjọ́rọ̀ ọmọ Nàìjíríà, Ogedi Ogu gbé Fásitì Oxford lọ sílé ẹjọ́ lórí ìtumọ̀ ọ̀rọ̀

Iwe atumọ ede Oxford si ọrọ

Oríṣun àwòrán, others

Ile ẹjọ giga kan ni ipinlẹ Eko ti da ẹjọ ti Oxford ti pe tako ipẹjọ oni miliọnu mẹwaa Naira ti agbẹjọro ọmọ Naijiria Ogedi Ogu pe tako wọn nu.

Ogu ninu ějọ to pe niwaju adajọ I.O. Harrison, ti salaye pe itumọ ọrọ ti wọn fun "mortgagee" ati "mortgator ninu iwe atumọ ọrọ Oxford ti ile itẹwe Oxford Press ki se eyi to tẹwọn rara.

O ni o jẹ nkan itiju fun oun nigba ti oun kuna gẹgẹ bi agbẹjọro, o si tabuku ba isẹ nigba ti oun gbara le itumọ ọrọ inu "Oxford Dictionary " lati gba alabaṣiṣẹpọ oun ni imoran ni ilana isẹ wọn ti o si ja si pe awọn itumọ naa ko tọna to.

O ni alabasisẹ pọ oun lo wa naka si i pe itumọ ti "Oxford Dictionary" kọ kii ṣe eyi to mu itumọ pipe jade ati pe lati igba naa, awọn alajumọ ṣiṣẹ pọ oun kii bere ibere tabi imọran to ba jẹ mọ isẹ lọwọ oun mọ

Ogu rọ ile ẹjọ lati sọ fun Fasiti Oxford ati ile itẹwe Oxford lati san miliọnu mẹwaa naira gẹgẹ bi owo itanran ati bibani lorukọ jẹ.

Ṣugbọn agbẹjọro fun Oxford, arabinrin Funke Adekoya (SAN) naa ti kọwe lodi si ipẹjọ naa pe ko ni ẹri to peye ati pe ki ile ẹjọ da ipẹjọ naa nu.

Àkọlé fídíò,

Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá

Adekoya ni Ogu ko tẹle ilana iwe ofin ti "Sheriff and Civil Process Act" ko to kọ iwe ipẹjọ naa.

O sapejuwe ipẹjọ naa gẹgẹ bi eyi ti ko ni itumọ kan kan, ohun a n gbe pati si ẹgbẹ kan ni

Agbẹjọro agba naa fi kun un pe ile itẹwe Fasiti Oxford, ti o fi kun un bi olujẹjọ keji ko ni ejọ ọ ro rara nitori ẹka lasan ni nile ẹkọ fasiti Oxford, ko le da duro fun ijẹjọ.

Ṣugbọn ọgbọn ọjọ, ninu oṣu kẹfa, ọdun 2020, Adajọ Harrison tako arabinrin Adekoya ni apa ibikan to si da iwe ẹbẹ pe ki ile ẹjọ ma sọrọ lori igbẹjọ naa nu.

Yatọ si ọrọ Adekoya pe ipẹjọ naa mẹhẹ Adajọ Harrison ni ẹjọ naa tọna, o si yanranti, o ba ofin mu, kii si ṣe nkan to yatọ rara si awọn ipẹjọ to ti maa n waye tẹlẹ.

Sugbọn Adajọ naa gba pe lootọ ni ẹka ni ile itẹwe Oxford jẹ ko si le duro fun ijẹjọ nitori naa ki wọn yọ kuro ninu igbẹjọ naa.

Àkọlé fídíò,

Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos