NDLEA: Ó sàn kí ẹ pa mí ju kí ẹ ba oko tí mo gbin igbó sí jẹ́ lọ- Afurasi Clement Akor ní Kogi

Clement Akor ati NDLEA

Oríṣun àwòrán, Others

O san ki ẹ pa mi ju ki a ẹ ba oko ti mo gbin igbo si jẹ lọ- Afunrasi kan lo rọ NDLEA bẹẹ.

Afurasi kan to ni oko igbo, Clement Akor ti rọ ajọ to n gbogun ti ilokulo egboogi oloro ni Naijiria (NDLEA) pe ki wọn pa oun san ju ki wọn ba oko eeka mẹwaa ti oun fi gbin igbo jẹ lọ.

Akor, ẹni ọdun mejilelogoji lati ilu Enabo nijoba ibilẹ Ankpa, ipinlẹ Kogi ati alajumọkẹgbẹpọ rẹ David Ameh lọ n bẹbẹ bẹẹ lẹyin ti awọn ajọ NDLEA ipinlẹ Kogi mu wọn.

Akor to ni oun ti na obitibiti owo si idi oko-owo naa ni oun ko si le gba lati padanu gbogbo rẹ,

Àkọlé fídíò,

Baby abandoned on dunmpsite: Mo ti bímọ mẹ́rin tẹ́lẹ̀ fún bàbá méjì nínú òṣí- Dupe Ogbomos

Akor ni ilu Owo nipinlẹ Ondo ni oun ti kọ iṣẹ igbo gbingbin Afunrasi oun n wa ẹkun mu bi omi ni, to si n gbiyanju lati dena awọn NDLEA lati ma ba oko naa jẹ.

Ọga agba ajọ NDLEA, Alfred Adewumi lo saaju bi won se fi katakata hu oko na ni ilu Oketepe, Okula, afunrasi naa ni o san ki oun ku ju ki oun ri bi wọn ṣe n ba oko ti oun ti n jiṣẹ jiya le lori lati bi ọdun kan sẹyin jẹ lọ.

O salaye pe oun mọ pe ofin wa pe eniyan ko gbọdọ ta igbo sugbọn ko si iṣẹ ti ko mu ewu dani.

Akor salaye pe "emi ni mo ni oko yii. Ondo ni mo ti kọ iṣẹ.

Nigba ti mo dako yii lọdun to kọja wọn ji gbogbo rẹ lọ, mo tun ra eso miran ni ilẹ Yoruba mo si gbin in ki wọn to tun mu mi bayii".

Àkọlé fídíò,

Bolaji Faleke ni Olùkọ́ tó ń kọ́ wa ní àṣà oge ṣiṣe lórí BBC Yorùbá

Akor ni: "Nigba miran mo le ta apo igbo kan ni egberun lọna ogun Naira, o wa lọwọ ibi ti mo fẹ taa si, mo tun le taa ju bẹẹ lọ. Ẹgbẹrun mejila naira ni mo ti na le oko yii lori, o san ki e pa mi ju ki ẹ baa jẹ lọ.

"Mi o kawe mi o si fẹ gbe ibọn ki n maa jale kiri, ọsẹ meji pere lo ku ki n fi kere oko yii, ẹ jọwọ ẹ saanu mi, mi o lọna miran".

Bo tilẹ jẹ pe ọga NDLEA pẹtu si ninu, sibẹ o sọ fun pe, igbogun ti egboogi oloro jẹ eyi to pataki ni Naijiria.

Adewumi ni, o se ni laanu pe, gbingbin egboogi oloro ati igbo n peleke si ni ipinlẹ Kogi ati ni Naijiria.

O ni iyalẹnu lo jẹ pe ipinlẹ kogi le di bo se da pẹlu gbigbin igbo.

Ati pe oniruuru oko ni awọn ti ri ti wọn si gbin igbo si aaye to to papa isere bọọlu.

Oga ajọ NDLEA ni okinrin naa yoo foju ba ile ẹjọ ni kete ti iwadi ba ti pari