Breast cancer: Mọ̀ nípa kẹ́míkà tó wà nínú oró agbọ́n fún ìwòsàn àìsan jẹjẹrẹ ọmú

Oyin

Oríṣun àwòrán, others

Awọn onimọ Sayẹnsi orilẹede Australia ti fi iwadii wọn sita pe oro inu awọn agbọn oloyin maa n pa kokoro aisan jẹjẹrẹ to buru ninu ọmu.

Wọn lo oro agbọn ati kẹmika kan to wa ninu rẹ to n jẹ "melittin wọn si fi danra wo fun oriṣi aisan jẹjẹrẹ meji kan to buru jai lati wosan: orukọ wọn ni "tripple negative ati HER2-enriched.

Wọn ṣapejuwe iwadii yii gẹgẹ bi eyi ti inu wọn dun si gan ṣugbọn awọn onimọ sayẹnsi mii sọ pe wọn ṣi niloo ayẹwo sii.

Jẹjẹrẹ ọmu ni aisan jẹjẹrẹ eyi to wọpọ ju to maa n da awọn obinrin laamu kakiri agbaye.

Pẹlu bi kẹmika ṣe pọ to ninu laabu to ṣeeṣe ko wo aisan jẹjẹrẹ, awọn onimọ sayẹnsi diẹ lara wọn ni wọn lee gbe sita gẹgẹ bi ogun ti eeyan le lo.

Oríṣun àwòrán, others

Ṣaaju akoko yii, wọn ti rii pe oro agbọn ni awọn eroja to lee doju ija kọ awọn irufẹ aisan jẹjẹrẹ mii bii "melanoma".

Ayẹwo ti wọn ṣe ni fasiti Harry Perkins Institute of Medical Research ni iha Ila Oorun Australia yii ni wọn ṣe agbejade rẹ ninu iwe iroyin igbadegba "Nature Precision Oncology ".

Kini abajade iwadii naa?

Wọn yẹ oriṣi oro agbọn to le ni irinwo wo latara ẹya agbọn meji - "honeybees ati bumblebees".

Àkọlé fídíò,

Blind Oniru: Muinat Abdulfatai ní òun ro ara òun pin àmọ́ irú títà fún òun ní ìrètí ọ̀tun

Wọn wa ri i pe ohun to jade latara agbọn oloyin lagbara gidi gan gẹgẹ bi ọjọgbọn ẹni ọdun mẹẹdọgbọn kan, Ciara Duffy to darii ikọ iwadii naa ṣe sọ.

Iwadii ọhun tun fihan pe ohun to pọ ninu oro naa lee pa aisan jẹjẹrẹ laarin wakati kan lai pa ohun kankan to ku lara.

Oríṣun àwòrán, Harry Perkins Institute

Bakan naa, awọn onimọ naa fihan pe kẹmika to n jẹ "melittin" ọhun ni agbara gan lati pa ohunkohun to n mu aisan jẹjẹrẹ dagba.

Tẹlẹ, iṣẹ abẹ oiṣiriṣi bii sugery, radiotherapy ati chemotherapy ni wọn ma n ṣe lorii aisan jẹjẹrẹ ọmu eyi to buru ju to n jẹ tripple-negative ohun si lo maa n fa ida mẹwaa ninuu mẹẹdogun awọn to ni aisan jẹjẹrẹ ọmu.

Oríṣun àwòrán, others

Ọjọgbọn Peter Klinken ṣalaye ninu iwadi ọhun bi kẹmikaa "melittin" ṣe maa n ṣiṣẹ idiwọ fun irinkerindoo awọn aisan jẹjẹrẹ ọmu lati ma jẹ ki o ran kaakiri.

Ẹwẹ, awọn aṣewadii naa ti kilọ pe wọn ṣi nilo iṣẹ lati rii boya oro naa le ṣiṣẹ to mọnyan lori bi wọn ba gbe e le iwọn gẹgẹ bi ogun aisan jẹjẹrẹ tori awọn onimọ mii sọ pe perete ṣi ni ọjọ ori rẹ gẹgẹ bi ogun to n ṣiṣẹ tori wọn ṣẹṣẹ ṣawari rẹ ni. Wọn sọ eyi fun BBC.

Àkọlé fídíò,

'Obinrin jẹ amuludun'