Black lives matter: Daniel Prude: Ìbòjú tí àwọn ọlọ́pàá New York fi bo ọkunrin ọhun ló ṣe ikú pà á

Daniel Prude ku lẹyin ọsẹ kan ti ọlọpaa mu u

Oríṣun àwòrán, We the people / go fund me

Ọsẹ kan lẹyin ti awọn ọlọpaa mu ọkunrin naa lo pada ku lẹyin ti ọlọpaa fi iboju bo o nimu ati ẹnu to si fun un mọlẹ fun iṣẹju meji, ẹrọ ayaworan ti ọlọpaa naa de mọra lo fihan bẹẹ.

Daniel Prude, ẹni ọdun mọkanlelogoji, ni ipenija aarun ọpọlọ nigba ti awọn ọlọpaa mu ninu osu kẹta ọdun yii, wọn si fi iboju de e lori lati le e di lọwọ lati ma ba tu itọ si awọn ọlọpaa lara.

O pada ku nitori ai le mi daadaa bi wọn ṣe de e lori titi de ẹnu, sugbọn wọn fi asiri naa pamọ fun awọn ara ilu.

Lẹyin oṣu meji to ku ni ọrọ iku George Floyd sẹlẹ, iwọde ifẹhonuhan miran ti bẹrẹ ni ilẹ Amẹrika lẹyin ti oyinbo alawọ funfun kan yin alawọdudu kan nibọn nigba meje.

Àkọlé fídíò,

Black women live matters: Ọdún 2015 ní àwọn ọlọ́pàá pa India Kager láìní ìdí- Gina Best

Jacob Blake, di ẹni ti ko le rin mọ, eyi naa tun ru inu awọn eniyan sita ti wọn si bẹrẹ si ni wọde.

Saaju ni oludije fun ipo aarẹ ilẹ Amẹrika labẹ Asia ẹgbẹ oṣelu Democrat Joe Biden ti pe, pe ọlọpaa to ṣe aṣemaṣe lori ọrọ Jacob Blake ati ti Breonna Tylor gbọdọ foju ba ile ẹjọ.

Obinrin alawọ dudu Tylor ti ọlọpaa yin nibọn ni ẹẹmeẹjọ ninu ile rẹ ni Louisville Kentucky ni ọjọ kẹtala, oṣu kẹta, ọdun yii ko ri idajọ gba.

O ni "ni ero ti temi, o yẹ ki ẹka eto idajọ ṣiṣẹ ọwọ ẹ" o sọ bẹ lasiko ipade awọn oniroyin ni Delaware.

"Mo lero pe, o kere tan, o yẹ ki wōn pe awọn ọlọpaa naa lẹjọ"

Saaju ni agbẹjọro agba ile Amerika William Barr ti ni ahesọ lasan ni pe awọn ọlọpaa alawọ funfun n pa alawọ dudu, ati pe iha ti ijọba kọ si ẹya mejeeji yatọ si ara wọn.

Bawo ni Daniel Prude se ku? Nínú Ipadà awọn oniroyin ni aburo rẹ Joe ti salaye pe lọjọ kẹtalelogun osu kẹta ni Rochester New York ni oun pe ọlọpaa pe ki wọn wa wọ ẹbi oun to ni aarun ọpọlọ.

"Mo pe wọn fun iranwọ ni kii se pe ki wọn wa paa" Prude jẹ osiṣẹ ile ikẹru si kan ni Chicago o si ni ọmọ marun, sugbọn o wa ki aburo rẹ ni lasiko to padà iku rẹ.

Ẹrọ ayaworan to wa lara ọlọpaa ṣe afihan bi Daniel ṣe n sakiri adugbo naa ni ihonho nigba ti awọn ọlọpaa de, lẹyin naa o wa ni ilẹ nibi ti ọlọpaa ti doju rẹ bolẹ

Àkọlé fídíò,

Dambe fight: ìdíje ìjà láàrin àwọn akóni tó n ja ẹ̀ṣẹ̀

Ni kete ti ọlọpaa de ni ọgbẹni Prude ṣe nkan ti wọn ni ki o ṣ lai janpata rara Ṣugbọn nigba ti wọn bẹrẹ si ni janpata nigba ti wọn fẹ da nkan boo loju, sugbon ko ni agbara lati ṣe ohunkohun gěgẹ bi fonran naa ṣe fi han.

O safihan ọlọpaa kan to rin ori Prude mọlẹ to si n sọ pe "ma titọ mọ"

Àkọlé fídíò,

George Floyd: Àwọn ọlọ́pàá darapọ̀ mọ́ àwọn olùwọ́de lórílẹ̀èdè Amẹ́ríkà

Awọn onimọ iṣegun gbiyanju lati doola rẹ ki wọn to gbe sinu ọkọ pajawiri lati gbe lọ fun itọju.

Lẹyin ọṣẹ kan ni wọn yọ ẹrọ aṣeranwọ eemi ti wọn gbe e si kuro.

Esi ayẹwọ ti wọn ṣe lẹyin to ku tan fi han pe ai ni eemi to nigba ti wọn fi ibomu bẹnu boo lasiko ti ọlọpaa fun mọlẹ lo ṣeku paa

Àkọlé fídíò,

Super Tuesday: ìdìbò láti yan ẹni tí yóò díje tako Trump bẹ̀rẹ̀