Bauchi Police: Ẹ wá wó arákùnrin tó pa ọmọ-ọmọ rẹ̀ tuntun jòjòló nítorí nípa ibálòpọ̀ ni wọ́n fi lóyún rẹ̀!

Omo tuntun

Oríṣun àwòrán, Google

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Bauchi ti fi panpẹ ọlọpaa mu arakunrin ẹni aadọta ọdun, Bawada Audu fun ẹsun pe o sin ọmọ-ọmọ rẹ laaye.

Ileeṣẹ ọlọpaa ninu atẹjade ti wọn fi sita gba ọwọ agbẹnusọ wọn, DSP Ahmed Wakil sọ wi pe arakunrin naa wu iwa buruku yii nitori nipa ifipabanilopọ ni ọmọ rẹ obinrin fi loyun ọmọ tuntun jojolo naa.

Wakil ni Ọmọ ọdun mẹtadinlogun ni ọmọbinrin rẹ ki wọn to fi ipabalopọ ni Oṣu Kini, ọdun 2020, to si loyun.

Wakil ni ileeṣẹ ọlọpaa ati ajọ ajafẹtọ ọmọniyan kan lo lọ wu oku ọmọ naa jade nibi ti o sin si, ti ayẹwo nile iwosan si fihan pe ọmọ naa ti ku.

Ajọ ajafẹtọ kan lo mu ọmọbinrin ọdun mẹtadinlogun wa si ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni agbegbe Toro, ni ijọba ipinlẹ Bauchi, lẹyin ti wọn fi lede pe o bi ọmọkunrin kan ni ọjọ Kẹrinla, Osu Kẹsan an, ọdun 2020.

Wọn ni Baba arabinrin naa ki ọmọkunrin jojolo naa mọlẹ to si lọ ri i mọlẹ si ẹyinkunle ile rẹ.

''Awọn sare yọ ọmọ naa kuro ninu ilẹ, amọ ẹpa ko boro mọ nigba ti wọn de ileewosan.''

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa naa ni Danjuma Uba kan lo fi ipa ba oun lopọ ni Oṣu Kini, ọdun yii to si ti salọ.

O ni wọn ti gbe oku ọmọ tuntun naa pada fun awọn araalu lati lọ sin ọmọ naa.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Bauchi fikun wi pe baba arabinrin to wu iwa buruku naa ti jẹwọ wi pe lootọ ni oun pa ọmọ-ọmọ oun.

Saaju ni oṣu yii ni pasitọ kan ti kọkọ pa iyawo rẹ ni America

Àlàyé rèé láti ẹ́nu mọ̀lẹ́bí ìyàwó Pásítọ̀ Sylvester Ofori ọmọ Ghana tó yìnbọn pá aya rẹ̀ l'Amẹrika

Mọlẹbi Barbara Tommey, iyawo Pasitọ ilẹ Ghana ti wọn fura si pe ọkọ rẹ Sylvester Ofori lo yinbọn lu laimọye igba ti mẹnu ba idi ti o fi ṣeku pa.

Awọn mọlẹbi naa lasiko ti wọn kede isinku rẹ sọ pe nitori pe o fẹ kọ ọkọ rẹ silẹ ni Pasitọ Sylvester fi yinbọn lu lẹẹmeeje ti eyi si ṣokunfa iku rẹ.

Oríṣun àwòrán, Sylvester Ofori/Facebook

Lọsu to kọja ni iroyin gbode pe Pasitọ yi yinbọn lu iyawo rẹ niwaju ọfisi arabinrin naa ni ilu Orlando Florida gẹgẹ bi awọn ọlọpaa Amẹrika ti ṣe wi pe

Sophia Tommey, to jẹ ọmọ iya oloogbe naa ṣalaye pe Sylvester binu pa iyawo rẹ nitori pe o bẹrẹ eto lati kọ silẹ.

Sophia sọrọ yi lede Twii lori ileeṣẹ redio Hitz FM to wa nilu Accra.

O ṣalaye pe ọmọ iya oun ti ko kuro nile ọkọ rẹ ni nkan bi oṣu mẹ ta sẹyin nitori ede aiyede to ti n waye laarin wọn.

Pasitọ Ofori to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji ni oludasilẹ ile ijọsin Floodgates of Heaven to wa ni adugbo Coburn Avenue, Orlando.

Lọwọlọwọ bayi o wa ni ahamọ ọlọpaa nibi ti wọn ti fẹsun ipaniyan kan an.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ilu Orlando Frank Chisari sọ fawọn akọroyin pe Pasitọ yi a maa jẹ orukọ wolii lori ayelujara tawọn eeyan si mọ ọ daada.

Akọsil ileeṣẹ ọlọpaa Orlando ṣafihan pe wọn ti mu Ofori ri lọdun 2016 nitori pe o ba iyawo rẹ ja.

Gẹgẹ bi Sophia ọmọ iya Barbara Tommey ṣe sọ, Pasitọ Ofori ri wi pe bi iyawo oun ba file kọ silẹ, gbogbo dukia r ni yoo bọ si lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Sylvester Ofori/Facebook

''Ki tiẹ baa fi ma gbofo lọ mu mi ki o pa''

]Fọnran fidio ibi ti Pasitọ ti n leri lati pa iyawo rẹ

Ileeṣẹ BBC foju ri fọnran fidio to gbode kan nibi ti Pasitọ naa ti sọ pe oun yoo pa iyawo rẹ.

Ninu fidio naa, niṣe ni Paitọ n tahun si Kweku Perry ọmọ iya iyawo Pasitọ lọkunrin nitori pe Pasitọ naa n lu iyawo rẹ

Lasiko ti awọn mọlẹbi rẹ tẹle lati wa ko ẹru kuro ninu ile Pasitọ Ofori ni iṣẹlẹ yi waye.

Ninu fidio naa Ofori leri leka pe ''Ti mi o ba pa aburo yin ayederu Pasitọ ni mi''

Lẹyin to leri yi ni kamẹra CCTV ṣafihan bi Pasitọ naa ti ṣe yinbọn lu iyawo rẹ lẹẹmeeje.

Oríṣun àwòrán, Sylvester Ofori/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Pastor Sylvester Ofori

Pásítọ̀ Ofori dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó yìnbọn pa ìyàwó rẹ̀ ní ìta gbangba

Pasitọ kan to jẹ ọmọ bibi orile-ede Ghana, Sylvester Ofori ti yinbọn pa iyawo rẹ, Barbara Tommey.

Iṣẹlẹ ọhun lo ṣẹlẹ lọjọ Iṣẹgun lẹba ile itaja nla kan ni Millenia ni Orlando lorilẹ ede Amẹrika.

Ileeṣẹ ọlọpaa Orlando ṣalaye pe wọn gbe Tommey digba digba lọ si ile iwosan, ṣugbọn ẹlẹmi ti gba a.

Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe Ofori ti wa latimọle awọn ọlọpaa bayii.

Ọga ọlọpaa Orlando ni fọnran ori kamẹra fihan bi Ofori ti yinbọn pa iyawo rẹ nigba ti o fẹ wọ ile itaja nla naa.

Àkọlé fídíò,

Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí

Obìnrin kan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ sọ pe oun si n gbọn di akoko yii.

Amọ Ofori ti wa lẹwọn bayii nibi ti wọn ti fẹsun apayan kan an.