Ibadan Traditional worshippers: Àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ ń bèèrè ọludé lọ́dọọdún fún àyájọ́ ìṣẹ̀ẹ̀ṣe

Oríṣun àwòrán, others
Awọn ẹlẹsin ibilẹ ẹka ti ipinlẹ Oyo ṣe iwọde niluu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo ni guusu iwọ oorun Naijiria lati kepe ijọba pe ko dẹkun idẹyẹsi awọn ẹlẹsin ibilẹ.
Awọn eeyan naa ti wọn kọwọọ rin lọ sí olu ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo ni Agodi nibi ti wọn ti gbe oriṣiriṣi beba lọwọ p\wlu akọle oniruuru.
Die ninu akọle naa ni eyi ti wọn kọ ọ si pe "Ẹ dẹkun idẹyẹsi awọn ẹlẹsin ibilẹ, gbogbo wa ni ipinlẹ Oyo wa fun."
- Bí nǹkan ọkùnrin bá há sójú ara obìnrin, kìí ṣe Mágùn, ẹ má páyà
- "Ẹ fún ọ̀já kó le, lítà epo kan le tó ₦250 àbí ju ₦300 lọ"
- Ìdí tí mo ṣe se oúnjẹ nínú ilé ẹni tí mo lọ jà lólè rèé- Afurasí adigunjalè
- Owó tí Kiddwaya bá rí ní BB Naija, ìdá kan fún Erica, ìkejì fọ́mọ aláìníyàá - Baba Kiddwaya
- Wọ́n ti dáwọ́ ìdánwò àbẹ́rẹ̀ àjẹsára Oxford dúró lẹ́yìn ti olùkopa kan ṣàìsàn
Bakan naa ni wọn rọ awọn kristẹni ati musulumi lati bawọn bẹ ijọba pe ki o maa fawọn naa lọlude bi awọn ẹlẹsin meji to ku.
Akọwe agba ẹgbẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ l'Oyo, Ọmọwe Fayemi Fakayode ṣalaye pe iha ti ijọba Gomina Seyi Makinde kọ si awọn ẹlẹsin ibilẹ lo jẹ k'awọn ṣewọde lati fi ẹhonu han.
Ninu ọrọ tiẹ, aarẹ Iṣẹṣe Foundation nipinlẹ Oyo, Baale Olukanmi Egbelade sọ pe ohun ti awọn fẹ ni pe ki ijọba fi awọn si ipo to yẹ k'awọn wa lawujọ.
Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí
Aarẹ Egbelade ni "a fẹ ki ijoba kede ọlude logunjo, oṣu kẹjọ lọdọọdun gẹgẹ bi ayajọ ọjọ Iṣẹẹṣe."
Ẹwẹ, oludamọran fun Gomina ipinlẹ Oyo lori ọrọ aabo, Ọgbẹni Odukoya Sunday to bawọn sọrọ ṣeleri lati jiṣẹ wọn fun Makinde.
- Wọ́n ti fa Ààrẹ Amẹrika, Donald Trump kalẹ̀ fún àmì ẹ̀yẹ Nobel Peace Prize
- Auxiliary gbé èèyàn mẹ́fà tó ń jáwèé ayédèrú fáwọn awakọ̀ lọ sí ilèẹjọ́ ní Ibadan
- Ibadan NURTW: Àwọn ti Auxilliary àtàwọn tí Ajanaku gangan ló ń dàgboro rú
- Kí ló le è mú kí agbábọ́ọ̀lù subú, kó sì kú lásìkò ìfẹsẹ̀wọ̀nsẹ̀?
- Owó tí Kiddwaya bá rí ní BB Naija, ìdá kan fún Erica, ìkejì fọ́mọ aláìníyàá - Baba Kiddwaya