Ooni Adeyeye Ogunwusi: Fani-Kayode ní ìwà àbùkù Tinubu yìí ta bá gbogbo ọmọ Oodua

Femi Fani Kayode ati Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Others

Awuyewuye to n waye lori ikinni laarin Ọọni tilu Ile Ifẹ, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ati asaaju ẹgbẹ oselu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, si n tẹsiwaju lori ayelujara.

Nibayii, minisita tẹlẹ feto irinna, Femi Fani-Kayode naa ti da si isẹlẹ yii loju opo Twitter rẹ l'Ọjọru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọrọ lori bi Tinubu se joko, nigba ti Ọọni n ki lori iduro, Fani-Kayode ni ọrọ sunnukun ni ọrọ naa, o si yẹ ka fi oju sunnukun wo o.

Fani-Kayode ni "Isẹlẹ naa safihan iwa abuku ati ọyaju si ni nikan fawọn ọmọ bibi ilu Ile Ife, amọ iwa naa tabuku gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba lọkunrin ati lobinrin."

Minisita tẹlẹ naa fikun pe, ojuti nla gbaa ni ihuwasi ọhun, eyii to yẹ ko pa ni lẹkun.

Oríṣun àwòrán, Others

Fani-Kayode wa n beere pe se asaaju oloselu lẹkun ariwa Naijiria lee kọ lati dide ki ọba alaye nibẹ?

Afenifere fara ya lórí bí Tinubu ṣe jókòó kí Ooni

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ ọmọ Yoruba lorilẹede Naijiria, Afẹnifẹre ti bu ẹnu atẹ lu ihuwasi adari ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu pẹlu bi ko ṣe dide lati ki Ooni ti Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, lasiko ti wọn n fi Ọba oniru ti Iru, Oba Omogbolahan Lawal jẹ ni Eko.

Odumakin sọrọ yii lẹyin ti aworan bi Tinubu ṣe joko, nigba ti Ooni dide lati ki i, gba oju ẹrọ ayelujara kan.

O ni bi o tilẹ jẹ pe awọn ọba ilẹ Yoruba ko ni agbara bi oloṣelu mọ, ohun to yẹ ni lati bọwọ fun awọn ori ade nipa titẹriba lati ki ọba.

Àkọlé fídíò,

Mayowa Omoniyi: Kò sí orin Obey, Sunny Ade abí tàkasúfèé tí ń kò le ta gìtá sí

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ Afẹnifẹre naa sapejuwe bi Aarẹ orilẹede Naijiria nigbakan ri, Oluṣegun Ọbasanjọ ṣe dọbalẹ lati ki Ọọni lọdun 2016 bii bibu ọwọ nla fun ori ade naa.

'' Ọmọ Yoruba ni wa, a si gbọdọ bu ọla fun ẹni ti ọla yẹ, paapaa awọn ọba alade nilẹ Yoruba, a kọ gbọdọ sọ wi pe nitori ọlaju, ki Tinubu wa joko, nigba ti Ọọni dide lati ki i.

Ohun to mu aarẹ nigba kan ri dọbalẹ gbalaja lati ki Ọọni ti Ifẹ, a gbọdọ bọwọ fun asa ati iṣe ilẹ Yoruba,"