Cuppydat: Ọmọdé aláwàdà Ikorodu Bois tún àwòrán Ferrari Portofino àwọn Otedola yà

Aworan awọn ọmọ Otedola lara ọkọ ati Ikorodu Bois

Oríṣun àwòrán, DJ CUPPY/IKORODU BOIS

Oju opo Twitter tun ti n sọ putuputu nitori aworan ọkọ ayọkẹlẹ mẹta ti Femi Otedola ra fun awọn ọmọ obinrin rẹ.

Ohun to yani lẹnu tabi ka si ni ko yani lẹnu nipa rẹ ni pe awọn ọmọ alawada asinijẹ nii, Ikorodu Bois lo n mu awọn eeyan sọrọ nipa rẹ.

Ko pẹ sigba tawọn ọmọ Otedola fi aworan wọn sita tawọn Ikorodu Bois naa ya ẹda aworan tiwọn pẹlu kẹkẹ ''wheel barrow'' mẹta ni iye ọkọ awọn ọmọ Otedola mẹtẹẹta koda to fi mọ kikun awọn "wheel barrow" naa ni awọ awọn ọkọ wọn.

Aworan wọn ti wọn ya yi mu ki awọn eeyan bọ si oju opo wọn lati maa sọ nipa rẹ.

Cuppy ati Otedola ko ti sọ nkankan nipa aworan yi titi di igba ti a fi ṣe akojọpọ iroyin yi.

Eyi kii se igba akọkọ tawọn ọmọ Ikorodu Bois yoo maa ṣe ẹda aworan tabi fidio tawọn oṣere tabi gbajumjọ ba fi sita.

Lara wọn leleyi ti wọn ṣe nipa sinima "Money Heist" to gba orii Netflix kan.

Femi Otedola ra ọkọ̀ Ferrari mẹ́ta lọjọ kan ṣoṣo fáwọn ọmọbìnrin rẹ, ariwo ta

Yoruba ni ẹni nla, lo n ṣe ohun nla, tẹni n tẹni, akisa ni ti aatan.

Bẹẹ lọrọ ri nile gbajumọ olokoowo, to tun jẹ ilumọọka ọlọrọ ni Naijiria, Femi Otedola.

Lọjọru ni ọkan lara ọmọbinrin rẹ mẹtẹẹta, Cuppy Otedola, bọ soju opo twitter rẹ lati bun araye gbọ pe, baba oun ra ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye ti wọn n pe ni Ferrari Portofino ti wọn ṣe sita lọdun 2020 taa wa yii, fun ikọọkan awọn ọmọbinrin rẹ mẹta.

Bakan naa lo fi aworan awọn ọkọ Ferrari mẹtẹẹta ọhun soju opo twitter, ti Cuppy funra rẹ ati Temi si duro ti ọkọ naa.

Amọ ọmọbinrin kẹta, Tolani, tii ṣe agba awọn mẹtẹẹta ko si ninu aworan ọhun, bẹẹ ni ko gbe ọkọ tiẹ̀ sori ayelujara rara. Ikede naa ti mu ki ariwo ta lori ayelujara laarin ọmọ Naijiria, koda wọn ṣe iwadii iye ti ọkọọkan ọkọ naa jẹ, eyi ti wọn pe ni ẹgbẹrun lọna okoolerugba o din marun dọla $215,000.

Ta ba si ni ka si owo ohun ni owo naira ilẹ̀ wa, iye owo ọkọọkan mọto Ferrari Portofino naa le ni mílíọ̀nù lọna mẹrindinlaadọsan naira, N86m.

Apapọ iye owo ọkọ Ferrari mẹtẹẹta ti Otedola ra fáwọn ọmọbìnrin rẹ si le ni milionu lọna ọtalerugba naira o din meji, N258m.

Idi ree ti awọn ọmọ Naijiria ko ṣe sinmi ariwo lori ọrọ naa, bi awọn kan si ṣe n kan saara si Otedola lori bo ṣe n sikẹ awọn ọmọ rẹ, ni awọn miran n yọ suti ete si.

Oríṣun àwòrán, @cuppymusic

Lero tawọn eeyan miran, wọn ni o ya awọn lẹnu pe lasiko ọrọ aje to dagun yii, ni ẹni kan n ra ọkọ mẹta lẹẹkan ṣoṣo fáwọn ọmọ rẹ.

Elomiran ni oun yoo fi aworan ọkọ ayọkẹlẹ naa ransẹ si baba oun, abi Otedola ni ori meji ni.

Oríṣun àwòrán, Tolani Otedola

Koda, awọn miran ni Otedola ni ami ẹyẹ baba to pegede julọ tọ si nitori oun ni baba akọkọ ti yoo wẹ mọto Ferrari mẹta ni ọjọ kanṣoṣo. Loju opo ayelujara naa si ni ọpọ ọmọ Naijiria tí n sọ awọn ohun to ṣe iyebiye julọ, ti baba wọn ra fun wọn.