Bukunmi Oluwasina: Ìmọ̀ràn ọkọ mi nínú eré tí mo bá kọ lo ń jẹ́ kí eré mi dáńtọ́

Bunkunmi Oluwasina

Oríṣun àwòrán, Bunkunmi Oluwasina

Gbajugbaja oṣerebinrin to ṣẹṣẹ ṣe igbeyawo, Bukunmi Oluwashina ti sọ pe o daju pe ẹbẹ ati aforiji ni oun yoo fi iyooku ọdun yii tọrọ lọwọ ọpọ eeyan, fun bi ko ṣe dajọ ayẹyẹ igbayawo rẹ fun wọn.

Lati owurọ Ọjọbọ ti ti fidio igbeyawo rẹ ti jade si ori ayelujara, ni awọn ololufẹ rẹ ati awọn akẹẹgbẹ rẹ kan ti n sọ boṣe ya wọn lẹnu pe o ṣe igbeyawo bi ikọkọ.

Lalẹ ọjọru ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹsan ni oṣerebinrin yii rọraa fidio kan soju opo ayelujara rẹ to fihan pe o ti gba oruka igbeyawo.

Ninu fidio naa lo ti wọ aṣọ funfun igbeyawo ti ọkọ rẹ naa wọ kootu to si jẹ wipe awọn mejeeji nikan sọ́ọ́ lo wa ninu fidio naa.

"Awa mejeji jọ kere ti a ko si mọ ohunkohun nipa ifẹ nigba ti mo kọkọ pade rẹ, odo ifẹ kun a si luwẹ lai bẹruu ko gbe ni lọ..."

"Iwọ lo kọ mi bi wọn ṣe n luwẹ ninu odo ifẹ, wo ibi ti a de bayii latẹyin wa".

Bi orin yii ṣe n lọ labẹlẹ fidio ti Bunkunmi fi sita n wu ni lori jọjọ eyito ṣalaye itan ifẹ to mbẹ laarin wọn.

Bunkunmi kọ bi wọn ṣe rin irinajo ifẹ wọn soju opo rẹ afi bii episteli ni tori bi wọn ba gun ẹṣin ninu rẹ , wọn o le kọsẹ rara.

"... kii ṣe ti ka kan maa ra gbogbo agbaye fun obinrin bikoṣe mimu inu obinrin dun ati fifun un ni ifọkanbalẹ ju ẹni to ni gbogbo nkan laye lọ".

Oríṣun àwòrán, IbrahimChatta/Instagram

Bunkunmi ni oun ranti ọdun 2010 ti oun beere pe ki ọkọ afẹsọna rẹ to di ọkọ lonii fun ohun ni nkankan gẹgẹ bi ami ifẹ lati maa ranti rẹ, "o fun mi ni ẹgba ọwọ alawọ pupa didi rẹ, Mo si ṣeleri pe maa tọju rẹ titi ayeraye ati pe boya mo maa wọ gan lọjọ igbeyawo wa, o rẹrin musẹ... o ni iyẹn bi tirela ko ba gba aarin wa".

Oríṣun àwòrán, Bunkunmi Oluwasina

Ọrọ pọ ninu iwe kọbọ ti iyawo ọsingin kọ ṣugbọn lẹyin ọdun mọkanla ti wọn ti n fẹrawọn sọna, ọrọ naa di ohun.

Àkọlé fídíò,

Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Akomolede BBC Yorùbá fẹ́ kọ́ wa lònìí

Awọ́n akẹ́gbẹ́ Bunkunmi Oluwasina gan ji ri i lowurọ kutukutu ni bi inu wọn si ṣe dun to ni awọn naa ṣe bẹrẹ si ni fi aworan rẹ sita pẹlu ikini.