Lagos vs Ekiti Waste Baskets: Ìjọba Eko kọ́ ló rán àwọn ọ́ọ́físà tó ń ta apẹ̀rẹ̀ ikòlẹ̀sí níṣẹ́

Awọn to fi apẹrẹ idalẹ si gbowo

Oríṣun àwòrán, Instagram/yenukuti

Ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe ohun kọ lo ran awọn ọkunrin kan ti wọn fẹ fi tipa tipa ta apẹrẹ idalẹ sin ipinlẹ Eko fun ọrẹ ọmọ Yeni Kuti to jẹ ọmọ oloogbe Fela Kuti.

Ijọba Eko fọrọ yii lede loju opo Twitter rẹ lọsan Ọjọbọ lẹyin ti fidio naa ti kọkọ lu oju ayelujara pa lowurọ Ọjọbọ kan ni.

Kọmiṣọnna ọrọ ayika ati alumọọni inu omi, Tunji Bello ṣalaye loju opo Twitter ipinlẹ Eko pe onijibi lawọn eeyan to n fipa ta apẹrẹ idalẹ si ọhun ninu fido naa.

Ọgbẹ Bello sọ pe wọn kii ṣe aṣoju ajọ ipinlẹ Eko kankan, ati pe ijọba ipinlẹ Eko kọ lo ran wọ niṣẹ.

O fikun ọrọ rẹ pe ko si ajọ kankan to n jẹ ''Lagos State Vehicle Waste Basket(LAVWAB)'' labẹ ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika ati alumọọni inu omi.

O sọ pe onijibi lawọn ọkunrin to wa ninu fidio naa pẹlu bi wọn ti lọ tẹ orukọ ajọ ti ko si si ara ọkọ lati gbowo lọwọ awọn araalu Eko lọna aitọ.

Kọmiṣọnna ni ijọba ti fi to awọn agbofinro leti lati wa awọn eeyan to wa ninu fido naa ki wọn si fi wọn jofin.

Ọgbẹni Bello rọ awọn to wakọ loju popo lati maa lo apẹrẹ idasilẹ si to ba wu wọn ninu ọkọ wọn.

Kí ni apẹ̀rẹ̀ ikòlẹ̀sí Eko fi yàtọ̀ sí ti Ekiti tí ọ́ọ́físà mú wa mọ́lẹ̀?

Itahunsira bẹ silẹ loju popo ipinlẹ Eko nibi ti awọn oṣiṣẹ ajọ to n bojuto imọtoto ipinlẹ Eko, The Cleaner Lagos ti n sọ fun alabaṣiṣẹpọ Omoyeni Anikulapo-Kuti, ọmọbinrin gbajugbaja oloogbe olorin, Fela Kuti pe apẹrẹ ikodọti si ti ko tọ ni wọn gbe sinu ọkọ.

Lọjọbọ ọsẹ, Yeni fi fidio ọhun si oju opo instagram rẹ nibi ti oṣiṣẹ ajọ The Cleaners Lagos ti mu ọkọ bọọsi ti ẹni ti wọn jọ n ṣiṣẹpọ wa ninu rẹ lọna Badaru tori pe wọn ri apẹrẹ ikodọti ti wọn kọ ipinlk Ekiti si lara ninu ọkọ wọn.

Ọọfisa ba yari pe ko yẹ ki wọn gbe apẹrẹ ikodọti si ti wọn kọ orukọ ipinlẹ Ekiti si lara ninu ọkọ wọn.

Njẹẹ kii gan ni apẹrẹ akodọti si ti Eko fi yatọ si ti Ekiti? Ki lẹṣẹ wa gaan?

Ọọfisa ba ni "yean, mo mọ ohun ti mo n sọ ọ, ẹ n gbe apẹrẹ ipinlẹ ekiti ninu ọkọ yin, eleyii si lo yẹ ki ẹ gbe". Lo ba yọ apẹrẹ ikọdọti si ti wọn lẹ beba ipinlẹ eko mọ lara jade.

Oríṣun àwòrán, yeniakuti

O n jẹ ko di mimọ fun wọn pe ẹṣẹ ni ki wọn lo apẹrẹ ikodi si ti Ekiti ninu ọkọ tii ṣe ti ipinlẹ Eko to si ni wọn o le lọ ibi kankan o, afi ki wọn ṣe oun to tọ.

Oṣiṣẹ yii ṣalaye pe niwọn igba ti o jẹ pe Eko ni wọn n gbe, ti wọn ti n ṣiṣẹ, ti ọkọ wọn si jẹ ti Eko, ko yẹ ki wọn lo apẹrẹ to jẹ ti ipinlẹ Ekiti ninu ọkọ tori o ni o lodi si ofin.

O daa, bi a ba wa lọ ra apẹrẹ lọja taa kan gbe e sinu ọkọ nkọ o?

Ọọfisa ni irọ o, ẹ o le ṣe iyẹn tori apẹrẹ tiwa yii nikan lẹ gbudọ maa lo.

Lo ba ni dandan ki wọn wa ra apẹrẹ lọwọ ikọ ohun ni ẹgbẹrun mẹta abọ naira.

Ṣe ni awọn eeyan tu sẹrin rẹkẹrẹkẹ pe laduru iṣoro to n ba Naijiria finra ni iru eleyi tun n waye ti awọn mii naa si ba wọn gba a si ibinu lootọ pe iru orilẹede wo gaan leyii

Àkọlé fídíò,

Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Akomolede BBC Yorùbá fẹ́ kọ́ wa lònìí