Ghana Election 2020: Ẹ dín iye ìgbà tẹ n gorí obìnrin kù kẹ́ẹ lè lágbára...

Ghana Election 2020: Ẹ dín iye ìgbà tẹ n gorí obìnrin kù kẹ́ẹ lè lágbára...

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bo ṣe ku nkan bii oṣu mẹta ki idibo orilẹede Ghana waye, awọn adari oṣiṣẹ alaabo nileeṣẹ ọlọpa ti n rọ awọn ọlọpaa lati ṣe adinku iye igba ti wọn n ni ibalopọ ki wọn lee ṣiṣẹ karakara lasiko idibo.

Ọga ọlọpaa patapata to wa ni ẹkun olu ilu orilẹede naa Accra, DCOP Afful Boakye-Yiadom ṣalaye pe eyi ṣe pataki gan ni tori pe iṣọwọ ti eeyan fi n ni ibalopọ maa n ṣakoba fun agbara awọn ọlọpaa tori naa wọn nilọ okun ati agbara fun iṣẹ lasiko idibo.

"Ẹ ko ara yin ni ijanu, gbogbo wa la nilo okun lati ṣiṣẹ lasiko idibo, mo fẹ gba yin nimọran lati maa jẹun daadaa, ati pe ki ẹ din nini ibalopọ ku ki ẹ le lagbara fi ṣiṣẹ daadaa ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo ọdun 2020, DCOP Afful sọ fawọn ọọfisa ọlọpaa.

O sọ ọrọ yii fawọn ọlọpaa lasiko igbaradi yiyan bi ologun ti wọn ṣe lati jẹ ki awọn araalu mọ pe ṣamu-ṣamu lawọn ti gbaradi de ọjọ idibo.

Ọga agba ọlọpaa naa tun gba awọn ọlọpaa nimọran pe ki wọn ma dara pọ mọ oṣelu kankan ki wọn le da yatọ lẹnu iṣẹ wọn.

Lọpọ igba, idibo lorilẹede Ghana maa n gbona janjan ṣugbọn fun ọdun diẹ bayii, apapọ awọn ọlọpaa atawọn ologun ti n ṣiṣẹ lati ṣe aridaju alafia lorilẹede naa lasiko idibo.

Ọjọ keje oṣu kejila ni awọn ara Ghana yoo lọ dibo lati yan adari tuntun fun orilẹede wọn bẹẹ si ni ẹni to wa lori alefa lọwọ lọwọ yii, Nana Akufo-Addo n ni ireti pe labẹ ẹgbẹ oṣelu NPP, oun yoo le ṣe saa keji.

Ẹwẹ, alatako rẹ, John Mahama ti ẹgbẹ oṣelu NDC naa ni ireti pe awọn oludibo yoo tun oun yan lẹyin saa kan ṣoṣo to lo gẹgẹ bi aarẹ Ghana ti ẹlomii fi gbajọba mọ ọ lọwọ.